Ìjámbá ọkọ̀: Ìwà àìbikítà nídí ọkọ̀ wíwà ló ń fa ìjàmbá

Ijamba ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ní ọdọọdún ni ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ń sọnú ní inú ìjàmbá ọkọ̀, eléyìí tí a lè kojú tí awakọ̀ bá gbájú mọ́ ọkọ́ wọn lójú pópó.
    • Author, Funmi Jokotade
    • Role, Broadcast Journalist

Ni owurọ Ọjọ Aje, Osu Keje, ọdun 2018 ni arabinrin to n wa ọkọ lori afara Third Mainland n kun atike loju popo lasiko to n wa ọkọ lọwọ.

Obinrin awakọ to n kun atike yii. da ọpọlọpọ sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ lori afara naa, ti ọpọ eniyan n gba lọ si ibi isẹ laarọ Ọjọ Aje ọhun. Eyi mu ọpọlọpọ eniyan bẹrẹ si ni bu arabinrin naa.

Ni ọpọlọpọ igba,, ihuwasi bi eleyii ati awọn ise miran ti awọn eniyan ma n se ni oju popo, lo maa n fa ijamba ọkọ, ti o ma n mu ọpọlọpọ ẹmi lọ.

Ni ọdọọdun ni ọpọ ẹmi n sọnu ninu ijamba ọkọ, eleyii ti a le dẹkun rẹ, ti awọn awakọ ba le gbajumọ ọkọ wiwa ni oju popo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Shomolu gbajúmọ̀ fún ìwé títẹ̀

Iwa aibikita ti awọn eniyan ma n wu ni oju popo

Wiwa ọkọ ni oju popo jẹ ohun to gba ọpọlọpọ ọgbọn ati akiyesi si awọn ohun ti eniyan ko gbọdo se ni oju popo.

  • Awakọ ko gbọdọ mu oti to ba n wa ọkọ
  • Ohun ti ko dara ni lati gbe ọmọ ti ọjọ ori rẹ wa laarin ọjọ kan si ọdun mẹjila si iwaju ọkọ ni ẹgbẹ awakọ
  • A ko gbọdọ ma a tẹ atẹjisẹ ti a ba n wa ọkọ, o le fa ki oju eniyan kuro lara ọkọ to n wa
  • Ohun ti ko dara ni lati ma a ba ọmọ wi ti eniyan ba n wa ọkọ. Ohun ti o yẹ ki obi naa se ni lati wa ọkọ rẹ gunlẹ sẹgbẹ kan, ki o si ba awọn ọmọ naa wi, ki o to pada si ni wa ọkọ naa.
  • Ohun ti o buru jai ni lati ma a kun atike tabi ki o ma a wọ asọ to ba n wa ọkọ.
  • Awọn ẹlomiran tun ma a n sun ni idi ọkọ. Ohun to yẹ ki eniyan se ni lati sun daradara, ki wọn ko wa oko.
  • Awọn onimo nipa eto wiwa ọkọ gba awọn eniyan niyanju lati mase maa gba ipe ti wọn ba n wa ọkọ, ati wipe ti ọrọ ti wọn ba n sọ ba nii se pẹlu idunnu tabi ibanujẹ.