Fẹ́mi Kútì: Ó ku ogún ìsẹ́jú táa fẹ́ seré, ni atagìtá mi pòórá

Oríṣun àwòrán, @ Femi Anikulapo-Kuti
Ilu mọọka akọrin Afro beat, Fẹmi Anikulapo-Kuti, ti n kerora pe atagita oun, Aghedo Andrew, ku diẹ ko ba isẹ oojọ oun jẹ ni orilẹ-ede Amẹrika, nibiti awọn ti lọ kọrin.
Fẹmi Kuti, tii se ọmọkunrin Fẹla Anikulapo Kuti, lo n tara poro ni ilu New York pe, o ku ogun isẹju ki ere orin ti oun gba bẹrẹ, ni oun ri pe atagita oun naa ti di awati, eyi ti oun kọ̀kọ bẹru pe yoo se ipalara fun orin ti oun fẹ kọ.
Sugbọn, Fẹmi, ẹni to n dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin rẹ yoku, fun bi wọn se duro ti oun, ti wọn si ti oun lẹyin bii igba ẹkẹ ti n fi ọwọ ti ile, tun fi kun pe, awọn ko fi bẹẹ mọ ipa atagita to poora ni Amẹrika naa lara, nitori pe orin ti awọn kọ dun, to si tun ni arinrin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Fẹmi, ẹni to kede isẹlẹ yii loju opo Twitter rẹ @Femi Anikulapo-Kuti, fi kun pe, obinrin ni atagita oun ba lọ nitori oun ti se awọn iwadi to yẹ, ti oun si ri pe Andrew ko si ninu ewu rara.
O salaye pe, awọn pe ni ori aago pe ko gbe ọkọ lati wa tete dara pọ mọ awọn, amọ to kọ lati se bẹẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Amọ o wa n fọwọ sọya pe, ẹru ko bodo fun oun rara, nitori oun si ni awọn ọmọ ẹgbẹ ti muse-muse wọn da muse-muse, lati se ere to wu ni lori, ti wọn si tun setan lati gbe orukọ rere ẹgbẹ akọrin oun soke lala.
Fẹmi ko sai yan pe "A ko ri iru eyi ri, a fi n dẹru ba ọlọrọ ni, iru awọn isẹlẹ bayi maa n waye lati jẹ ki eeyan ni agbara ati ọgbọn si ni."

Oríṣun àwòrán, @ Femi Anikulapo-Kuti
Fẹmi, ẹni to n kọminu lori idi ti atagita ti oun fọkan tan se lee hu iru iwa bayii fun oun, wa n salaye pe, kii kuku se pe oun n fi iya owo jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ oun.
"O ni isẹ gidi lọwọ, mo si n san owo ribi-ribi fun wọn. Koda o ni owo to jọju lọwọ lati kọwe fi isẹ silẹ lọna to tọ,, bẹẹ ni awọn iwe asẹ iwọlu lorisi-risi nilẹ okeere (VISA), lo wa lori paali iwe asẹ irinna rẹ, eyi to lee fi wọ ibikibi lagbaye. Nitori naa, ko lee wi awijare pe oun ko ri itọju, loun se wu iru iwa bayii."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Nigba ti ọpọ eeyan n beere pe, kin lo de ti oun naa ko se ti gba iwe asẹ irinna rẹ, Passport, ni kete ti wọn wọ̀ ilẹ Amẹrika, Fẹmi dahun pe, eyi lodi pata-pata si ihuwasi oun, nitori iwa ifiyajẹni ni oun ka igbesẹ naa si, bẹẹ ni oun ni igbagbọ ninu gbogbo awọn to n ba oun sisẹ, ọna ti oun si maa n gba sisẹ niyi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3