Foreign Secretary: Gboingboin ni a wà lẹ́yìn Nàìjíríà lórí ìgbógun ti Boko Haram

Ilẹ Gẹẹsi ti fi atilẹyin wọn han fun ikọ ọmọogun Naijiria to n gbogun ti Boko Haram ni agbeegbe Ariwa orilẹede Naijiria.
Akọwe Agba Ilẹ Gẹẹsi, Jeremy Hunt lo sọ eyi lasiko to n se abẹwo si ikọ omoogun to wa ni Maiduguri lati fi atilẹyin wọn han. Eyi wa lara abẹwọ rẹ si ilẹ Afirika ati si Ajọ World Food Programme to wa ni Maiduguri.
Hunt to ba ajọ to n pese ounjẹ ati ile gbigbe fun awọn ogunlende to n gbe lagbeegbe Maiduguri lẹyin ti ikọ Boko Haram se ikọlu si agbeegbe wọn.
O fi kun wi pe Ilẹ Gẹẹsi ti se atilẹyin imọ oye fun ọmọogun to to ẹgbẹrun lọna ọgbọn lati fi atilẹyin wọn han fun orilẹede Naijiria.
Bakan naa lo ni awọn ti setan lati fun ikọ ọmọogun Naijiria ni awọn ohun ija ti wọn nilo lati koju Boko Haram, ati wi pe Ilẹ Gẹẹsi n pe fun itusilẹ gbogbo awọn ti ikọ Boko Haram ti jigbe lagbeegbe Ariwa orilẹede Naijiria.
Akowe Ilẹ Gẹẹsi wa parọwa si ijọba orilẹede Naijria lati ri wi pe wọn pese awọn ohun igbaye-gbadun si awọn agbeegbe ti awọn ọmọogun ilẹ Naijiria ti le awọn Ikọ Boko Haram kuro ki wọn ma ba a raye pada si agbeegbe naa mọ.








