Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọwọ́ ko ti tẹ àwọn afurasí to jí olórí ìlú Buhari gbé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Katsina State Policeti ke gabjare pe irọ balawu ni ọrọ to n ja rain-rain pe awọn ti mu awọn afurasi to ji ana ẹsọ aarẹ Buhari gbe.
Alukoro ọlọpaa Gambo Isah tofi ọrọ yi sita ni ohun ko mọ ibi ti awọn akọroyin kan ti ri iroyin pe ohun sọ pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi naa.
O ni ohun ti atẹjade ti oun fi sita sọ ni pe awọn kọlu awọn ajinigbe naa ni.
"Mi o fi igba kankan sọ fun ẹnikẹni pe a ti mu awọn ajinigbe naa .O jọ pe ọrọ ti a fi sita ni ko ye wọn nitori a ni a da wọn lna nii kii ṣe wi pe a tiu ri wọn mu.''
Dida lọna ti Isah loun n sọ ni eleyi to ni ṣe pẹlu ikọlu to waye laarin awọn ọlọpaa ati awọn to ji olori ilu Daura naa gbe.O ni awọn ajinigbe naa papa bọ mọ awọn lọwọ.
Ni irọlẹ Ọjọru ni awọn afurasi ajinigbe naa gbe Umar Isah ni ile rẹ to wa ni Daura ni ipinlẹ Katsina ni nnkan bi ago meje aṣalẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oga Isah salaye pe kete ti awọn ọlọpaa gburo ijinigbe naa ni wọn tọ awọn ajinigbe naa lọ titi ti wọn fi de ikorita Kwosanda nibi ti wọn ti doju ija ko wọn.
Lori boya awọn ajinigbe naa ti bere owo lati fi tu olori naa silẹ, Isah ni ohun ko le fesi si ibeere naa .
Amọ ṣa ileeṣẹ ọlọpaa ni Katsina sọ fun BBC pe owo ti awọnklede lati fun ẹni to ba le tawn lolobo nipa ibi ti wọn ti le ri olori naa le ju miliọnu marun un naira lọ.












