Daura Kidnap: Àna ààrẹ Buhari, Musa dàwátì ní ìlú Daura

Oríṣun àwòrán, AFP
Alhaji Musa Umar to jẹ adari ilu Daura ni ipinlẹ Katsina ti di awati ni ilu rẹ.
Iroyin to tẹ wa lọ́wọ́ ni wi pe alẹ ọjọru lawọn ajinigbe ọhun ya wọ ilu Daura ti wọ́n si bẹrẹ si ni yinbọn sinu atẹgun, awọn araalu sa asala fun ẹmi wọn.
Ni ti Umar, o ṣẹṣẹ pada de lati mọsalasi to ti lọ kirun irọlẹ ni iṣẹlẹ naa waye. Iwaju ile rẹ lo wa pẹlu awọn eniyan nigba ti awọn agbebọn yii de.
Awọn aralu to ṣoju wọn koro sọ fun awọn oniroyin pe ọkọ Peugeot 406 Saloon ati Toyota Kilux ni awọn ajinigbe naa wa.
"Wọn ba a niwaju ile rẹ ni Kwanar Agam wọn si ji i gbe ni nkan bi agogo meje alẹ lẹyin irun Mọgrib.










