Èyí ni bí àwọn agbébọn ṣe gbé òṣìṣẹ́ Shell méjì, wọ́n tún pa àwọ̀n aláàbò wọ̀n ní Rivers

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọga gba meji nileeṣẹ elepo rọbi Shell ko ti i di riri lẹyin ti awọn ajinigbe gbe wọn, ti wọn si tun pa awọn ọlọpaa to n daabo bo wọn.
Iṣẹlẹ naa waye lasiko ti awọn oṣiṣẹ naa n pada si ilu Port Harcourt lati irinajo ẹni iṣẹ ti wọn rin lọ si ipinlẹ Bayelsa.
Awọn agbebọn naa pa awọn oṣiṣẹ alaabo ọhun, ti ọ̀kan lara wọn jẹ awakọ ọkọ̀ to gbe wọn, ki wọn to o gbe awọn oṣiṣẹ meji naa.
Agbẹnusọ kan nileeṣẹ ọlọpaa sọ pe igbesẹ ti n waye lati doola wọn.
Wọn ko si ti i fi orukọ awọn to kagbako iṣẹlẹ naa sita.
Agbẹnusọ ileeṣẹ elepo Shell ninu atẹjade kan sọ pe ''Ileeṣẹ Shell kabamọ lati fidirẹmulẹ pe ikọlu waye si awọn oṣiṣẹ rẹ ati awn alaabo ijọba ni Rumuji, loju ọna East/West nipinlẹ Rivers.
Igba akọkọ kọ niyi ti awọn ajinigbe yoo ji awọn ọmọ ilẹ okeere ni Naijiria.
Nibẹrẹ oṣu yii, obinrin kan to jẹ ọmọ orilẹede Britain jẹ ọ̀kan lara eniyan meji ti awọn agbebọn pa lasiko ti wọn kọlu ibudo igbafẹ kan niluu Kaduna.
Eniyan mẹta ni wọn jigbe nibi ikọlu naa.
Bakan naa l'oṣu Kinni ọdun 2018, ọmọ orilẹede America meji, ati Canada meji ni wọ̀n jigbe lasiko ti wọn n rinrinajo lati ilu Kafanchan nipinlẹ Kaduna lọ si ilu Abuja. Meji ninu awọn ọlọpaa to n sọ wọn ni wọn pa.













