N30,000 minimum wage: Ṣé N30,000 mú ìyàtọ̀ gorí N18,000 owó oṣù òṣìṣẹ́?

Osise

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, A se àgbéyẹ̀wò ipa tí N30,000 gbèǹdeke owó osù tí ìjọba sẹ̀sẹ̀ fọwọ́ sí gẹ́gẹ́ bí òní se jẹ́ Àyájọ́ Ọjọ́ àwọn òsìsẹ́ ní Naijiria.

Onimọ nipa eto isuna ti sọ wi pe igbe aye awọn osisẹ yoo dara diẹ ju tẹlẹ lọ lasiko ti ijọba Naijiria buwọlu gbedeke owo osu osisẹ to jẹ ẹgbẹẹrun lọna ọgbọn naira(N30,000).

Atiku Samuel lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni eto ọrọ aje Naijiria naa yoo gbooro sii, amọ awọn ipenija kọọkan yoo wa ni ọdun akọkọ ti wọn ba bẹrẹ si ni san owo osu osisẹ tuntun naa.

Ninu ọrọ rẹ, Samuel ni awọn ipenija ti Naijiria yoo koju ni ati maa san owo osu ọhun, nitori ijọba Naijiria n ya owo oṣu lati san tẹlẹ fun awọn osisẹ, eleyii ti yoo tun mọ si wi pe wọn yoo tun maa ya owo sii ni.

O fi kun un wi pe bi o tilẹ jẹ pe ounjẹ, owo ile gbigbe ati owo irinna ọkọ ni yoo gba gbogbo owo naa lọ, amọ yoo kari awọn eniyan naa ti ko sisẹ ijọba nitori awon naa yoo ri ọja ta, eleyii ti yoo mu owo naa wọle fun wọn.

Àkọlé fídíò, 'Oyin sínsìn lérè lórí ṣùgbọ́n ó tún gbé ikú karí'

Onimọ nipa eto isuna naa fi kun un wi pe aisi isẹ lorilẹede Naijiria si jẹ oun to n fa ifasẹyin fun awọn eniyan lorilẹede Naijiria, amọ ireti wa wi pe igbe aye awọn eniyan yoo gbe pẹẹli soke sii.