Lebanon: Peace Busari àti àwọn 28 míràn ló padà sí Naijiria

Oríṣun àwòrán, Twitter
Arabinrin Peace Busari ti olowo rẹ lorilẹede Lebanon fẹ ta loju opo Facebook ti pada wale si Naijiria.
Alaga Ajọ Nigerians in Diaspora Commission, Abike Dabiri-Erewa, lo fi lede bẹẹ ni oju opo Twitter rẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Dabiri-Erewa
Abike Dabiri-Erewa ni arabinrin Peace Busari pada sile pẹlu awọn mọkandinlọgbọn miran ti wọn wa ni oko ẹru ni Lebanon naa.
- 'Báyìí la ṣe rìn ín láti pápákọ̀ òfurufú Abuja sí Eko bí ìrìnà òfurufú abẹ́lé ṣe bẹ̀rẹ̀'
- Ìṣòro mi ni pé mo tètè ṣe tàn, ṣùgbọ́n ó wù mí kí n ní ìbálòpọ̀ síi
- Ààrùn Coronavirus tún ti ran ènìyàn 664 l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà
- Ayé le! Sheffield faṣọ iyì ya mọ́ Chelsea lára lọ́nà ìrìnàjò sí Champions League
- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ lákọ̀tun
O saleye pe ki wọn to pada si Naijiria, Busari wa pẹlu ikọ to n bojuto awọn ọmọ Naijiria to wa ni Beirut, Lebanon, lẹyin ti wọn gba pada lọwọ olowo rẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ọgbẹni Wael Jerro polowo Busari Peace pẹlu iwe irina rẹ ọmọ ipinlẹ Oyo loju opo Facebook rẹ ni oṣu diẹ ṣẹyin.

Oríṣun àwòrán, Other
Eleyii lo bi awọn ọmọ Niajiria ninu ti wọn si pe fun itusilẹ Busari ati ki wọn fi panpẹ ọba mu Jerro to polowo rẹ lori ayelujara.
Lẹyin naa ni Dabiri-Erewa kede pe panpẹ ọba ti mu arakunrin naa ti awọn si ti bẹrẹ eto lati mu arabinrin Busari pada sile.
Ọkùnrin Lebanese tó lu ọmọ Nàìjíríà ní gbàǹjo lórí Facebook ti kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá
Ọmọ orilẹede Lebanon, Wael Jerro to lu ọmọ Naijiria ni gbanjo loju opo Facebook rẹ ti wa ni gbaga ọlọpaa.
Alaga ajọ to n ri si awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa nilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa lo fidi ọrọ yii mulẹ loju opo Twitter rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Abike ṣalaye pe, ọkunrin naa yoo jẹjọ lẹyin tawọn ọlọpaa ti fi panpẹ ofin mu un.
- Iléèwé Chrisland yóò wọlé padà lọ́jọ́ Ajé, wọ́n ní òfin ìgbélé coronavirus kò mú ìgbẹ̀kọ́ orí ayélujára
- Ewu ń bẹ! Coronavirus lè tara òkú Abba Kyari ran àwọn tó péjú síbi ìsìnkú rẹ̀- Ààrẹ ẹgbẹ́ dókítà ní Nàìjíríà
- Lórí ọ̀rọ̀ Ogun Majek, mi ò lọ́rọ́ láti sọ, ẹ lọ pe ẹni tára rẹ̀ kò yá- Mr. Latin lórí àìsàn Ogun Majek
- Wo bí ìgbé ayé Richard Akinjide ṣe lọ gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò àti olóṣèlú tó mòye
- Ìyàn ń bọ̀ ní Nàìjíríà lẹ́yìn coronavirus àyàfi... - Ẹgbẹ́ àgbẹ̀ kìlọ̀
- Ikú Dagrin pé ọdún mẹ́wàá, wo àwọn nǹkan mánigbàgbé nípa rẹ̀
O ni ijọba ilẹ naa yoo gbe e lọ si ileẹjọ nitori ijọba tako fifi ọmọ eeyan ṣe kata-kara.
Ọgbẹni Jerro polowo Busari Peace pẹlu iwe irina rẹ loju opo Facebook rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ẹgbẹrun kan owo dọla($1,000) lo gbe le e lori.
Ọmọ ọgbọn ọdun ni ọmọ Naijiria naa, ipinlẹ Oyo ni o ti wa.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo faraya lori ayelujara ti wọn si sọ pe ki ijọba ilẹ Lebanon fi ọwọ ofin mu un.
























