Coronavirus pandemic: Ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀ ní Nàìjíríà ní ìyàn ń bọ̀ lẹ́yìn coronavirus àyàfi...

Awọn ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ministry of Humanitarian Affairs

Ajọ iṣọkan agbaye ti ke gbajare sita pe bi ọrọ ṣe n lọ yii ajakalẹ iyan yoo waye lagbaye nipasẹ ọwọja arun Coronavirus.

David Beasley to jẹ adari eto ounjẹ lagbaye (WFP) labẹ aṣia ajọ iṣọkan agbaye ni igbesẹ kanmọkanmọn yẹ ko waye lori ọrọ yii lati lee dena ajalu to n rọ dẹdẹ naa.

Abọ iwadii kan fihan pe iye awọn eeyan ti ebi n pa lagbaye lee gbera lati miliọnu marundinlogoje lọ si ọtalelugba o din mẹwaa milọnu eeyan.

Awọn orilẹede mẹwaa ni ajakalẹ ebi yii yoo ṣe ọṣẹ fun julọ, gẹgẹ bi ajọ to n ri si eto ounjẹ lagbaye ṣe sọ.

Abajade iwadii lori wahala ounjẹ ẹlẹẹkẹrin iru ẹ, 'Global Report on Food Crises' tọka si orilẹede Yemen, Democratic Republic of Congo, Afghanistan, Venezuela, Ethiopia, South Sudan, Sudan, Syria, Nigeria ati Haiti.

Nigba ti o BBC Yoruba sọrọ, akọwe agba ẹgbẹ awọn agbẹ to jẹ ọdọ(Young Farmers Association of Nigeria - YFAN), Adeleke Opeyemi jẹri sii pe iyan n bọ lorilẹede Naijiria lẹyin ti aarun coronavirus ba kasẹ nlẹ.

Ounjẹ ninu apo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọgbẹni Opeyemi ni adaimọ ki iyan ma bẹ silẹ lẹyin ti covid-19 ba tan nilẹ, ayafi ti ko ba pẹ ju loku.

O ni lọwọlọwọ bayii, ọpọlọpọ awọn agbẹ lo ko le de oko wọn mọ nitori awọn janduku to n dunkoko mọ wọn lọna.

Akọwe agba ẹgbẹ YFAN ni ko si nnkan koriya fun awọn agbẹ mọ lasiko yii, eyi to ti mu ki ọpọ pa iṣẹ naa ti.

Ọgbẹni Opeyemi tun sọ pe iṣoro to n koju ọpọ awọn agbẹ gan an bayii ni ai ri ibi ti wọn ti le ta nnkan oko wọn.

O ni ọpọ ti wọn fẹ ta ẹyin lọpọ yanturu ni ko ri ọjọ ti wọn ti le taa, bakan lawọn ti wọn fẹ ta nnkan oko mii.

O rọ ijọba lati ṣe agbekalẹ ọja tawọn agbẹ ti le maa ta ọja oko wọn lasiko yii, tabi ki ijọba gan an maa ra lọwọ wọn.

Akọwe agba ẹgbẹ YFAN tun fikun ọrọ rẹ pe o yẹ ki ijọba ṣe eto kiko ere oko awọn agbẹ lọ si ibi ti wọn ba ti fẹ ta ọjọ naa.

Apo ireṣi

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ministry of Humanitarian Affairs

Bakan naa lo sọ pe o yẹ ki ijọba ṣeto fawọn agbẹ lati le maa rin lai si ẹni lai ni idiwọ lasiko igbele coronavirus yii.

Lorilẹede South Sudan, ida mọkanlelọgọta awọn olugbe ibẹ lo foju wina ebi ti ko lẹgbẹ lọdun to kọja gẹgẹ bi abajade iwadii naa ṣe fi kalẹ.

Awọn eeyan ni ẹka ijọba to n ri si igbayegbadun eeyan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ministry of Humanitarian Affairs

Koda, ki ajakalẹ arun yii to wọle de, apa kan ẹkun ila oorun Afirika ati gusu Aṣia lo ti n ba ọwọngogo ounjẹ finra eleyii to waye nipasẹ ọda ojo ati ajalu awọn kokoro ajẹkorun fun ọpọlọpọ ọdun.

Nigba to n ba igbimọ eto abo lajọ iṣọkan agbaye sọrọ, Ọgbẹni Beasley ṣalaye pe gbogbo agbaye gbọdọ ṣe giri pẹlu igbesẹ to yẹ lori ọrọ yii.

O ni afaimọ ki orilẹede agbaye o maa fi oju wina iyan to lagbara bii ti inu Bibeli nigba ti a o ba fi ri oṣu diẹ sasiko yii.