Coronavirus prevention tips: Ọ̀nà àbáyọ fún olóyún lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo ibi nílẹ̀ káràòjíire ni oyún tí jẹ nkan, oyún jẹ́ àdúrà pàtàkì tí ìyàwó osìngín má ń lẹ́yìn ayẹyẹ ìgbéyàwó.
Ṣùgbọ́n lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn Coronavirus yìí, ọ̀pọ̀ aboyún ni ẹ̀rù ń bà. Ṣáájú ni ààrẹ àwọn agbẹ̀bí Franka Cardee tí ké sí gbogbo àwọn obìnrin tí ó lè máa bẹ̀rù bí wọn yóò ṣe rùú là lásìkò yii, àti ọ̀nà tí yóò gbà láti dáàbò bo ara wọn.

- Coronavirus: Àwọn ohun tí a kò tíì mọ̀ nípa àrùn Covid-19
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
- Ṣé òògùn Chloroquine lè dènà ààrùn Coronavirus bí?
- Coronavirus tún ti ṣe ọṣẹ́ lórí iṣẹ́ líla ojú ọ̀nà relùwe láti Eko sí Ibadan - Ìjọba àpapọ̀
- Àrùn Coronavirus fa'lẹ̀ya láwọn ìletò aláwọ̀dúdú ní Amẹ́ríkà

Ṣe ó tọ̀nà láti máa lọ fún àyẹ̀wò ìgbàdédéìgbà àwọn aláboyún?
Ọ̀pọ̀ àwọn aboyún ni ẹ̀rù ń bà láti láti lọ sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò ìgbàdédéìgbà tí ó yẹ kí wọn máa lọ fún nítorí wọn fẹ máa tẹ́lẹ̀ àṣà sún - fúnmi - ń - sún fún ọ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ǹkan lọ tí yí padà lágbàáyé lẹ́nu lọ́lọ́lọ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn nọ́ọ̀sì agbẹ̀bí lọ sì ti ń ṣe ìrànwọ́ fún àwọn aboyún lat máa dá wọn lóhùn láti orí aago ìbánisọ̀rọ̀.
Cadée gba àwọn aboyún níyànjú láti wádìí lọ́dọ̀ àwọn olùtọ́jú wọn ọ̀nà tí ó dára jù lásìkò yìí láti ṣe ètò àyẹ̀wò ìgbàdédéìgbà tí alaboyun máa ń ṣe
Bi mo bá láàrùn COVID-19, ṣé mo leè ko ran ọmọ láti inú oyún ?
Wọn ò tí rí kòkòrò Covid-19 ni ojú ara ìyá, tàbí lára ìwọ́ ọmọ tàbí láti inú omi ọyàn abiyamọ" , ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lórí èyí ṣùgbọ́n àwọn onímọ̀ kò tíì salábàpàdé Covid-19 nínú olubi ọmọ nínú ẹ̀jẹ̀ .Nkan ti o se pàtàkì jù lọ ní pe ki aboyún sá gbogbo ipá rẹ̀ láti dènà níní ààrùn Coronavirus, àmọ́ óò, tí ó bá lóyún tàbí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, ó ṣe pàtàkì láti àwọn elétò ìlera kí ó sì tẹ̀lé ìlànà tí wọ́n bá ní kí ó tọ̀
Mo ń ròó láti bímọ sí ilé ìwòsàn, ṣe ìpinnu tó tọ̀nà ni?

Oríṣun àwòrán, AFP
Ó ṣe pàtàkì láti bèrè lọ́wọ́ àwọn agbẹ̀bí tàbí dókítà wọn ibi tí ó dára jù láti bímọ sí.
Cardee ni èyí dálé ipò tí obìnrin náà wà, irú ìdojúkọ rẹ̀ àti bí ilé ìwòsàn ètò ìlera àgbègbè rẹ̀ bá ṣe rí
Ṣe àwọn ẹbí mi le wà pẹ̀lú mi ti mo bá fẹ́ bímọ?
Fún irú nkan báyìí oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè lọ ní àṣà tí wọn. Ṣùgbọ́n Cadée nígbà gbọ́ pé ó ṣe pàtàkì kí aláboyún ni ẹni tí yóò wà ní àyíká rẹ̀ lásìkò ìrọbí níwọ̀n ìgbà tí ẹni náà bá ti dáàbò bo ara rẹ̀, bí àpẹẹrẹ kí ó wọ ìbòjú-bomu ni yàrá
ìgbẹ̀bi kí ó sì máa fọ ọwọ rẹ lóòrè kóòrè pẹ̀lú ọmọ àti ọșẹ
- Ikú Dagrin pé ọdún mẹ́wàá, wo àwọn nǹkan mánigbàgbé nípa rẹ̀
- Ẹnìkan ṣoṣo nínú ìdílé kan ni yóò gbà N20, 000 owó ìdẹ̀rùn igbele Covid-19 - ìjọba àpapọ̀
- Lórí ọ̀rọ̀ Ogun Majek, mi ò lọ́rọ́ láti sọ, ẹ lọ pe ẹni tára rẹ̀ kò yá- Mr. Latin lórí àìsàn Ogun Majek
- Ewu ń bẹ! Coronavirus lè tara òkú Abba Kyari ran àwọn tó péjú síbi ìsìnkú rẹ̀- Ààrẹ ẹgbẹ́ dókítà ní Nàìjíríà
Ẹ̀rù ń bà mí láti bímọ, kíni mo fẹ́ ṣé, ní àsìkò yìí ?
Ṣe eto bí ose fẹ́ kí gbogbo nkan ó rí, èyí yóò mú àdínkù bá ẹ̀rù. Gba nọ́mbà ìbánisọ̀rọ̀ ẹni tí ó fẹ́ láti bá sọ̀rọ̀ nígbà tí ọmọ bá ti ń mú ọ, mọ ẹni tí fẹ́ kí ó ràn ọ lọ́wọ́ lásìkò ìrọbí, máa ṣe àwọn ǹkan bí eré ìdárayá nínú ilé, èyí yóò
máa mú kí ara rẹ balẹ̀ tí yóò sì mú ọkàn rẹ kúrò níbi ẹ̀rù. Máa ṣe eré ìdárayá èémí, pee nọ́ọ̀sì agbẹ̀bí rẹ tí ó bá kojú ìṣòro kankan. Tọju ara rẹ dáadáa, jẹun dáadáa, mumi dáadáa, feyinti kí inú rẹ sì máa dùn pé ó ní oyún. Irú ìbéèrè wo ni mo le bí àwọn elétò ìlera mi?

Tí àsìkò bá ti tó láti bímọ, ó ṣe pàtàkì kí ó bere àwọn ìbéèrè tí ó bá wù ọ
Cadee sọ pé ó lè béèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyìí:
- Ǹjẹ́ ewu àti kó ààrùn Coronavirus ń bẹ fún mi níbi tí mo wà yìí, ṣe ó ní ẹni tí ó ti wà ní ààyè yìí tó ní ààrùn Coronavirus tẹ́lẹ̀?
- Báwo ni ẹ ṣe mọ ìyàtọ̀ nínú àwọn tó ní ààrùn Coronavirus àti àwọn tí kò ní?
- Ǹjẹ́ o ni aṣọ tí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ń lò láti dáàbò bo ara wọn?
- Ṣé ẹ lè gbà kí ẹnikẹ́ni dúró tì mí, tí ẹ kò bá gbà kini ìdí?
- Ṣe lè gbà kí n gbé ọmọ mi sọ́dọ̀, tí ẹ kò bá gbà kíni ìdí?
- Ṣé mo lè fún ọmọ mi lọ́yàn, tí ẹ kò bá gbà kíni ìdí?
- Ṣé ojú ara ní mo fẹ́ fi bímọ ni tàbí iṣẹ́ abẹ, kí ni ìdí.
Kini nkan ti obìnrin tó bá fẹ́ lọ bímọ nílé ìwòsàn yẹ kí o gbé dání? Obìnrin kò nílò láti gbé tí ó pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ìwọ̀nba èyí tí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera bá ní kí ó mú wá náà ni, ó sì gbọdọ sọra gidi.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ní kété tí mo bá ti bímọ kí ló yẹ kí n ṣe láti dáàbò bo ọmọ mi?
Nkan ti o dára jù ni pé ṣókí ni, ìwọ àti ẹbi rẹ lọ ṣe pàtàkì jù kii se àkókò láti máa jẹ ki àwọn àlejò wò
" Tí ó bá ti ní àwọn ọmọ nílé, má ṣe gba wọn láàyè láti bá àwọn míràn ṣeré. Rí dájú pé ebi rẹ ń fọwọ́ wọn pẹ̀lú omi àti ọṣẹ lóòrèkóòrè. Ìmọ̀ràn Cardee
Aláboyún ni mí, báwo ni n o ṣe dáàbò bo ara mi ni àsìkò Covid-19 yìí.
Ìwádìí tí fi hàn pé, àwọn aláboyún kò sì lára àwọn tí àsìkò yìí ni ewu fún jùlọ láti ni ààrùn Coronavirus ṣùgbọ́n nítorí àwọn àyípadà tó dé bá ara ati èròjà tó ń f'ára lókun tí yóò ti gbọ̀jẹ̀gẹ́, ó ṣe pàtàkì lat ṣọ́ra. Ó gba àwọn obìnrin ni ìyànjú láti máa tẹ́lẹ̀ àwọn ìlànà yìí:
- Yàgò fún ẹnikẹni ti bá ń fi àmì Coronavirus hàn
- Yàgò fún wíwọ ọkọ̀ èrò lásìkò yìí tí ó bá ṣeé ṣe fún ọ
- Máa ṣiṣẹ́ láti ilé tí ó bá ṣeé ṣe
- Jìnà sí ìpéjọpọ̀ elérò púpọ̀ tàbí díẹ̀
- Yàgò fún ìpéjọpọ̀ ojúkojú láàrin ebi àti ọ̀rẹ́
- Máa lọ fóònù àti àwọn ètò orí ayélujára láti bá àwọn nọ́ọ̀sì agbẹ̀bí, àwọn dókítà àti àwọn òṣìṣẹ́ ìlera miran sọ̀rọ̀.
- Ṣe mo lè fún ọmọ mi lọ́yàn lai fòyà?
Àwọn òbí ń fún ọmọ wọn lọ́yàn

"Ní nkan ti a mọ̀, kò sì ewu nínú kí ọmọ máa mú ọyàn daada, gẹ́gẹ́ bí Cadee ṣe sọ gbogbo ìwádìí tí wọn ti ṣe kó sì àfihàn pé àwọn ọmọ lè kó aarun Coronavirus láti ara ọmú mímú, nítorí náà ìyá leè fún ọmọ lọ́mú
Kini mo ní láti ṣe tí mo bá ń gbé ilé Kojú-sí - mi-kín-kojú-sì-ọ?
Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ni wọn ń gbé ilé tí ó súnmọ́ ara wọn èyí sì mú kí ìsúnfúnraẹni kí ó nira díẹ̀. Ó ní kí àwọn ènìyàn gbìyànjú láti má súmọ́ ẹni tí ó bá ní oyún, tí ó bá sì ṣeé ṣe kí wọn pèsè yàrá ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó yàtọ̀ fún aláboyún Bákan náà lọ fi kún pé ó ṣe pàtàkì kí a máa fí omi àti ọṣẹ fọ ọwọ ni gbogbo ìgbà. Orísun: Unicef























