Ogun Majek: Lórí ọ̀rọ̀ Ogun Majek, mi ò lọ́rọ́ láti sọ, ẹ lọ pe ẹni tára rẹ̀ kò yá- Mr. Latin lórí àìsàn Ogun Majek

Oríṣun àwòrán, Other
Ni ọjọ Aiku ni gbajumọ oṣere tiata kan lorilẹede Naijiria, Folukẹ daramọla gbee sita pe ojojo n ṣogun ara ogun o le fun eekan oṣere, Ogun Majek ti o si nilo amojuto to peye.
BBC News Yoruba kan si agba oṣere naa to si fi ye wa pe igbagbọ oun ni pe ẹgbẹ awọn oṣere n gbe igbesẹ lori ọrọ oun.
- Auxiliary lo ń jà káàkiri ìlú Ibadan lọ́jọ́ Aje, ẹgbẹ́ ọlọkọ èrò NURTW kọ - Ejiogbe
- Ìyàwó mi ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ tuntun, kò si oúnjẹ fún wa torí ìgbélé Coronavirus- Yakubu
- Atirobẹ́lẹ́ṣindọ́gba ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ní ìsin yìí-Ọlọ́fàiná
- Baba Latin ṣe bẹbẹ lori èto Se o láya, sùgbọ́n...
- Mo lè sọ arúgbó dí ọmọge nígbàkúgbà - Hakeem Effect
- 'Dokita ilé ìwòsàn ló gba ẹsẹ̀ lọ́wọ́ mi'
Eyi lo mu ki BBC News Yoruba gbe ọrọ naa tọ ẹni ti awọn oṣere tiata Yoruba yan gẹgẹ bi aarẹ wọn, iyẹn Ọgbẹni Bọlaji Amuṣan ti ọpọ mọ si Mr. Latin.
Ọgbẹni Amuṣan ni oun ko lọrọ lati sọ lori rẹ ati pe ki BBC News Yoruba o lọ bi alagba Majek leere ohunkohun ti a ba fẹ.
Mr. Latin to n beere ohun gan to kan ileeṣẹ BBC lori ọhun ni ko sohun to buru nibẹ bi ileeṣẹ BBC naa ba da si ọrọ ọhun.
Gbogbo alaye akọroyin ileeṣẹ BBC lati jẹ ki o di mimọ fun ẹni ti awọn oṣere onitiata yan gẹgẹ bi aarẹ TAMPAN naa mọ pe ara ojuṣe ti ileeṣẹ iroyin lee ṣe fun pipe akiyesi iranwọ fun itọju agba oṣere naa lo bọ sẹyin eti rẹ to si ni oun ko lọrọ lati sọ nipa rẹ.
"Ẹ mọ nnkan to ṣẹlẹ , lori eleyii mi o ni ọrọ kankan lati sọ, ẹni ti ara rẹ ko ya, ẹ pe wọn, oun ti wọn ba ti sọ naa ni mo sọ"
'Ẹ o lee fi tipatipa mu mi sọrọ abi ṣe ẹ le fi tipatipa mu mi sọrọ ni'
Ogun Majek, òṣèré tíátà ní iléèwòsàn UCH lòun ti ń gba ìtọ́jú kí àrùn Coronavirus tó wọ̀lú

Oríṣun àwòrán, Other
Eekan oṣere tiata ati sinima lorilẹede Naijiria, Gbọlagade Akinpẹlu ti ọpọ mọ si Ogun Majek to wa ni idubulẹ aisan lọwọ bayii ti ṣalaye pe aisan oun ko ṣẹṣẹ bẹrẹ ati pe ọpọlọpọ asiko loun lo ni ileewosan nla UCH nibi ti oun ti n gba itọju.
Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, lori ẹrọ ibanisọrọ, alagba Ogun Majek ṣe e lalaye pe ajakalẹ arun Coronavirus to de lo gbe oun kuro ni ileewosan naa.
O fi kun pe awọn ẹgbẹ oṣere lorilẹede Naijiria, TAMPAN ti da si ọrọ oun wọn si ti n gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ.
O ni ọkan imoore loun ni fun ẹgbẹ naa atawọn alaṣẹ rẹ fun bi wọn ko ṣe da oun da wahala naa.

Oríṣun àwòrán, others
Ni ọjọ Aiku ni ọkan lara awọn oṣere sinima lorilẹede Naijiria,
Gbajúmò òṣèré tíátà, Ogun Majek ń ṣàìsàn líle, ó sì nílò ìrànwọ́ owó yín- Foluke Daramola

Oríṣun àwòrán, Instagram/Foluke Daramola
Ọkan lára àwọn gbajumọ osere tiata lọkunrin lédè Yoruba, Gbolagadé Akinpelu, tí gbogbo èèyàn mọ sì Ogun Majek, n ṣàìsàn báyìí, to sì lè pupọ.Bákan náà ni Ogun Majek nílò iranlọwọ owó láti fi tọju ara rẹ, ko le bọ lọwọ àìsàn náà.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Gbajumọ osere tiata lobinrin, Foluke Daramola lo fi idi ọ̀rọ̀ yii mulẹ lójú opo Instagram rẹ pẹlu àfikún pe, Ogun Majek nílò owó láti fi ṣe itọju ara rẹ.
- Ìtàn Manigbagbe: Àwọn àjakalẹ-àrun to ti wáyé rí ṣáájú Coronavirus
- Àwọn Ìpínlẹ̀ tí coronavirus kò tíì dé ní Nàìjíríà, àti ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé láti dènà rẹ̀
- Kí làwọn ìdàmú tí Coronavirus n mú bá àgọ́ ara?
- Yewande bí'mọ tuntun jòjòló, Mercy Aigbe pàdánù èèyàn rẹ̀, Toyin Abraham fèsì lórí aṣoju NCDC
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
Bákan náà lo fikùn pé, àwọn èèkàn ọmọ ẹgbẹ́ osere tiata kan náà tí ń sá ipa wọn láti ṣe itọju Ogun Majek, àmọ́ ìyànjú wọn yìí kò tíì tó láti wo àìsàn baba náà sàn pátápátá.
- 'Màálù tó bá tàsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ níwájú ilé mi, ó dẹran àsun!"
- Ṣe wahala wá ti ọkọ bá kọ̀ láti fún aya tó ti kọ̀ silẹ lára ogún rẹ?
- Oúnjẹ alẹ́ ni wọ́n ń fi Ọ̀ọ̀nì ṣe níbí
- Òṣèrè tíátà Muideen Oladapo gbàràdá lórí ètò 'Ṣé o láyà?'"Àìsàn baba Ogun Majek le pupọ, tó sì jẹ ara àwọn àìsàn tó maa n gbẹmi ẹni ní. Baba Ogun Majek nílò ìranwọ owó yín lásìkò yìí, kí wọn leè gbádùn padà".
Daramola wá ń ké sí àwọn ẹlẹyinju àánú ọmọ Naijiria, lati dìde ìranwọ fún Ogun Majek ko lee ri owo to to owó láti fi ṣe ìtọ́jú ara rẹ nílé ìwòsàn, ó ní káwọn aráàlú dakun, ogún Majek nílò iranlọwọ wọn.
"Àjọ aláàánú Para Foundation ń rawọ ẹ̀bẹ̀ si ọkàn àánú yín láti ṣètò iranlọwọ fún baba Ogun Majek, kò lè e bọ nínú ipò ikaanu tó wa.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Foluke Dramola
Foluke ni iye kíyè táwọn ara ilu bá ní yóò seranwọ láti gba ẹ̀mí Ogun Majek la, àwọn ko si fẹ ki ẹ̀mí rẹ bọ lásìkò yìí tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdánù Pa Kasumi.



















