Spanish flu and other pandemic: Ẹ fọkàn balẹ̀, àwọn àjàkálẹ̀ àrùn kan rèé to burú ju Coronavirus lọ

Wọn ní ìgbà kan ń lọ, ìgbà kan ń bọ̀, ayé kò dúró soju kan torí ẹṣin ta ta ta, ó kú, ènìyàn rìn, rìn rìn, ó sọnu.
Ọ̀rọ̀ àjakalẹ-àrun Coronavirus to gbòde yìí, tó ń pá ọmọdé àti àgbà, ọkùnrin at obìnrin, aláwò funfun àti dúdú, kò jẹ tuntun rárá nítorí ìgbà èyí kii ṣe akọkọ tí irú àjakalẹ-àrun báyìí yóò wáyé yíká agbaye.
Ìdí sì rèé tí BBC Yoruba fi wọnú ìtàn lọ, láti jẹ ki awon eeyan mọ nipa ọpọ ìṣẹ̀lẹ̀ àjakalẹ-àrun tó ti wáyé ṣáájú kàakíri àgbáyé, kódà, wọn fẹẹ ju ogún lọ, gẹ́gẹ́ bàa ṣe kaa lójú òpó itakun agbaye.
Eyi sì ni yóò fi ọkàn wa balẹ pé, àkókò Coronavirus tá ń lá kọjá yìí náà yóò lọ.
Igbà rẹ kò sì ní tọ lọ bíi orere, àwa sì laa borí rẹ, gẹgẹ báwọn ará ìgbàanì tí borí àjakalẹ-àrun to wáyé lasiko tiwọn.
Àwọn àjakalẹ-àrun to tí wáyé ri:
Àjakalẹ-àrun Ẹyi àbí Ṣanponna, tí wọn pé ní Antonine Plague:
Àjakalẹ-àrun olode yìí wáyé láàárín ọdún 165 CE ni àwọn ilẹ̀ tó wà lábẹ́ àkóso ìjọba Róòmù.
Orúkọ apàṣẹ wàá tó ń darí ìjọba Rome nígbà náà, Emperor Marcus Aurelius Antoninus Augustus si ni wọn fi sọrí àjakalẹ-àrun naa, èyí tó fẹẹ run gbogbo ilẹ̀ naa.

Ó kéré tán, ẹgbẹ̀rún méjì èèyàn ló ń jẹ́ Ọlọ́run nipe lójúmọ́ nítorí àrùn Sanponna ọ̀hún, tó sì ń tàn kalẹ kiri bíi owara ojo.
Gẹ́gẹ́ bàa ṣeé rí gbọ́, àwọn jagunjagun ilẹ Rome lọ ń ti ojú ogun bọ láti agbègbè ìwọ oòrùn Asia tí wọn tí lọ jagun, wọn kẹru, wọn kẹru laimọ pé wọn tí kò àrùn sanponna taa mo sì small pox mọ.
Arun yii náà je àrùn masunmọmi àbí mafarakanmi nígbà náà, tó sì wò òfin 180CE ko to dawọ duro.
Eyí tó gbà tó ọdún mẹẹdogun gbáko, tó sì gba ẹ̀mí ìdá mẹ́wàá ninu ọgọrun un àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, àrùn yìí jé akiri madalesi.
Àjakalẹ-àrun kejì to tún gbaju gbaja ni ibà Maáwú-maáwú, tí wọn ń pè ní Plague of Justinian àbí Black death:
Iba yìí ló máa ń mú àwọn èèyàn ni otútù, tí abiya, koropọn ati ẹyin etí wọn yóò sì máa wù.
O n jẹ kí wọn jẹ ìrora fún ọpọ ọjọ́, títí tí wọn yóò fi mí kanlẹ.
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
- Ìdílé márùn-ún tó gbajúmọ̀ fún òwò ẹrú nílẹ̀ Yorùbá
- Ìtàn ayé Ọba Seriki Abass ti Badagry, tó ní aya 128, ọmọ 144
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Kí ló fà ogun Ìjàyè àti ìṣubú Kurunmi, ìfẹ́ ìlú ni àbí orí kunkun?
Kódà, àwọn miran nínú wọn kò ní jẹ ará ayé, bẹ́ẹ̀ni wọn kò ní jẹ́ èrò ọrun, tí wọn yóò sì dákú lọ rangbondan fún ọpọ ọjọ́.
Ọpọlọ àwọn miran nínú aláìsàn yìí kò sì ní pe mọ kí wọn tó kú nítorí ìrora ńlá tí wọn ń jẹ.

Ìtàn fi ye wá pé ó tó mílíọ̀nù lọ́nà àádọ́ta èèyàn ló bá ajakalẹ àrùn Maáwú-maáwú yìí lọ, èyí tó bẹ silẹ laarin ọdún 482 sí 565 CE, to sì gba to ọdún metalelọgọrin kò to kaṣẹ nilẹ.
Kódà, a rí gbo pé nínú ọdún kan, lásìkò tí ajakale àrùn náà dojú rẹ, èèyàn mílíọ̀nù mẹẹdogbon lo dagbere fàyè, tí èèyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń kú lojumọ.
A gbọ pe eku dúdú táa mọ sí Black Rats, to máa ń jẹ ohun ọ̀gbìn onihoro bíi àgbàdo àti ọkà bàbà lo ni kòkòrò aifojuri àrùn náà lára.
Awọn èèyàn tó sì jẹ oúnjẹ tí eku ohun tí fẹnu kàn, lọ ní àrùn ọhun, èyí tó ń tàn kalẹ kiri.
Agbegbe àríwá Áfíríkà ni ọwọja àrùn náà ti tàn yíká àgbáyé, títí tó fi dé orile-ede Italy àti Rome, tí wọn ń darí àgbáyé nígbà náà.
Ìdí sì rèé tí wọn ṣe fi orúkọ Emperor Justinian 1, to ń darí ìjọba ilẹ̀ Rome nígbà náà sọri ajakale àrùn naa.
Ajakale àrùn yìí náà jẹ mafarakanmi tàbí masunmọmi, tí àwọn èèyàn sì ń ṣe ara wọn mọle, gẹgẹ ba ti n se láyé ajakale àrùn Coronavirus yìí, kí wọn máa bàa kò àrùn náà.
Ajakale àrùn miran tó tún wà ní àkọsílẹ̀ pé ó tún ja ranyin-ranyin lagbaye ni ajakale àrùn kẹta, tí wọn ń pè ní 3rd Plague.
Ajakale àrùn yìí sí lọ wáyé láàárín ọdún 1855 sì 1959.
Orile-ede China, n'ilu Yunnan ni ajakale àrùn yìí tí kọ́kọ́ bẹ silẹ, a sì leè ṣe àpèjúwe rẹ bíi alefọ ara tó ń wáyé ní pọpọlọ ìtàn, abiya àti ẹyin ọrùn, tó sì fẹ́ fara jọ ajakalẹ àrùn Justinian.

Kòkòrò aifojuri taa mo si bacteria la gbọ pé ó ń faa, tí èèyàn kan bá sì fara kan ẹni tó ní kòkòrò yìí, laarin ọjọ́ méje, onítọ̀hún náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí rí àpẹẹrẹ pé òun náà tí kò jonbo àrùn náà.
Lára àwọn àpẹẹrẹ àrùn alefọ náà ni ibà, orí fifọ àti èébì.
Alefọ yóò jáde làwọn agbegbe ara tó sún mọ́ ibi tí kòkòrò ọhun gba wọlé sí agọ ara, yóò kọ́kọ́ wú, kò tóo fọ, tí yóò sì di egbò.
Ìtàn fi yẹ wá pé ajakale àrùn alefọ náà gbẹmi èèyàn tó lè ní mílíọ̀nù méjìlá laarin orile-ede China sí India.
O sì ṣoro títí wọ ọdún 1959, nígbà tí ẹdinku bá iye èèyàn tó ń kú, tí wọn kò sì ju ìgbà lọ mọ nínú ọdún kan.
Àjakalẹ-àrun miran to tí wáyé sẹ́yìn, tó tún burú ju Coronavirus lọ ní ajakale àrùn Òfinkin àbí òtútù aya taa mọ sì Spanish Flu
Eyí to wáyé láàárín ọdún 1918 sì 1920.
Odun meji gbáko sì lo fi wáyé, tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sì báa rìn.
Ajakale àrùn sì lọ sún mọ́ wá julọ nítorí ọdún mejilelogorun tó wáyé rèé, gbogbo agbaye sì lo gbo kìkì rẹ.
A ri kà lójú òpó itakun àgbáyé pé, kòkòrò aifojuri kan ló ń ṣokùnfà àrùn òtútù náà, èyí tí ọwọja rẹ tán káàkiri àgbáyé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí kò fìdí rẹ múlẹ̀ nípa ibi tó ti ṣẹ wá.

Oríṣun àwòrán, Wiki
A gbọ pé ìdá mẹ́ta èèyàn tó wà láyé ni òtútù àyà àbí ofinkin náà mú, tó sì lé ní eedegbeta mílíọ̀nù èèyàn tó fara kaasa ajakale arun aseku pani náà.
Ó si to èèyàn mílíọ̀nù lọ́nà àádọ́ta tó tí ipaṣẹ ajakale àrùn yìí jé Ọlọ́run nipe.
Eèyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọrinlelẹgbẹta ó dín marun un, 675,000 sì tẹrí gbasọ lorilẹ-ede Amerika nìkan.
Láàrín ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí ajakale àrùn náà bẹ silẹ, èèyàn mílíọ̀nù mẹẹdọgbọn lọ jáde láyé, èyí tó burú ju iye àwọn èèyàn ti ogun agbaye àkọ́kọ́ gbẹmi wọn lọ.
Ọ̀pọ̀ èèyàn tó kú láti ipase àrùn òtútù aya lo wà láàrin ọmọ oojọ́ si ọdún márùn-ún, pelu awon arúgbó.
Lásìkò tí ajakale àrùn náà wáyé, kò tíì sí abẹrẹ ajesara tí ń dènà kòkòrò aifojuri tàbí oogun tó ń pá kòkòrò tó lewu nínú ara, èyí tó mú kí ọwọja àrùn òtútù aya ohun burú jáì.
Ọ̀nà táwọn èèyàn sì fi ń gba ìwòsàn nígbà náà ni kí wọn takete sì ara wọn, tàbí kí wọn dá wa ninu ile, wọn.

Wọn yóò fi aṣọ bo imú àti ẹnu wọn, gẹ́gẹ́ bá ti ń ṣe lásìkò ajakale àrùn Coronavirus yìí.
Wọn ń mú imototo ara ní ọkunkundun, tí wọn kò sì kóra jọ pọ si oju kansoso lati farakinra.
Ajakale àrùn náà sì lọ wà ní àkọsílẹ̀ pé ó burú julọ nítorí iye èèyàn tó pa.
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
- Baṣọ̀run Gáà: Ó yan ọba mẹ́rin, tó sì pa ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àmọ́ ọba karùn-ún ló pa á
- Ọọ̀ni obìnrin, Lúwòó Gbàgídà rèé, akọni tó ń gun ọkùnrin ní ẹṣin rìn
- Sanusi Adebisi Idikan rèé, olówó tó ń san owó orí fún gbogbo ọkunrin ilẹ̀ Ibadan
Ajakale àrùn miran ti àwùjọ agbaye kò leè gbàgbé ni àrùn onigbameji taa mọ sí Kọlẹra, èyí tó wáyé láàárín ọdún 1817 sí 1824.
Agbegbe Asia náà ni ajakalẹ àrùn onigbameji ọhun tí wáyé, tó sì na ọwọja rẹ dé àwùjọ àgbáyé tó fi mọ ilẹ̀ Áfíríkà pẹlu.
Ọ̀pọ̀ ọmọ ogún Gẹ̀ẹ́sì àtàwọn èèyàn miran ló lugbadi àrùn yìí, tó sì gba ilẹ̀ Yúróòpù, Asia àti Áfíríkà kan.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lè ní ìgbà méfa ti àrùn onigbameji tún ti bẹ silẹ leyin ti ọdún 1817 náà, síbẹ̀, manigbagbe ni ajakale àrùn Kọlẹra àkọ́kọ́ ọhun.
A gbọ pe omi tó ní kòkòrò aifojuri lọ ń fà àrùn onigbameji náà, tó fi mọ igbọnsẹ tí a kò pamọ dáadáa.
A gbo pe o tó èèyàn mílíọ̀nù meẹdọgun tó bá ajakalẹ àrùn onigbameji náà lọ, kò tó di pé ó kasẹ nilẹ.
Arun aseku pani Aids àti kòkòrò rẹ, HIV náà jẹ ajakalẹ àrùn to gbẹmi ọpọ èèyàn, pàápàá ní ìran wa yìí.
Ajakale àrùn yìí ló sọ ara rẹ di ojo láwùjọ agbaye, tí kò sì bá orile-ede kankan ṣe ọ̀tá, tó sì ń pá ọmọdé àti àgbà.
Àkọsílẹ̀ fi yẹ wa pé títí di ọdún 2018, èèyàn mílíọ̀nù mejidinlogoji ni kòkòrò àrùn HIV àti AIDS ti sekupa jákèjádò agbaye.
Kódà, lọdun 1997 nigbati àrùn ọhun gbóná jain-jain, èèyàn mílíọ̀nù mẹta àti aabọ lọ gba ẹ̀mí wọn lairo tẹ́lẹ̀.

Bákan náà, láàárín ọdún 2005 sì 2012, tíì ṣe ọdún méje sì ara wọn, kòkòrò HIV àti AIDS tí pá mílíọ̀nù lọ́nà mejidinlogoji èèyàn, taa sì leè sọ pé ó burú ju Coronavirus lọ.
Ara ọbọ ni àwọn èèyàn kan tí kó àrùn náà, tó sì ń jà ranyin-ranyin bíi iso inú ẹku, a sì leè kò láti ara ibalopọ, omi ara ati ẹ̀jẹ̀ ara.Ní báyìí ó ti yẹ kó yẹ wá pé kò yẹ ká kò aya sókè nítorí ajakalẹ àrùn Coronavirus nítorí pé ọwọja àwọn àrùn tá mẹ́nubà lókè yìí gan lè ju ti Covid-19 lọ.

E je ka ṣe àwọn ohun tó yẹ ká ṣe láti jajabọ lọ́wọ́ àrùn náà bii titakete sì ìpéjọpọ èèyàn, ká máa fọ ọwọ wa ni oorekoore, ká sì dúró sínú ilé wa.
A ń gbà a ladura pé àrùn burúkú kò ní fi agọ̀ ara wa se ibùgbé, bí àwọn ará iwájú tí ṣe borí àwọn ajakale àrùn tó rekọja lọ, naa ni àwa yóò borí Covid-19. Àṣẹ.


















