Coronavirus tips: Ìlànà ojúlówó márùn ún tó kápá ìtànkálẹ̀ COVID-19

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arun Coronavirus ti tan kalẹ jakejado agbaye ti o si ti da ipaiya silẹ toun ti bi iye eeyan to n ko arun naa se n pọ tawọn to tọwọ rẹ ku naa ko si din ku.
Pupọ awọn ilu lofin konileogbele ti fẹsẹmulẹ,lilọ bibọ ọkọ ofurufu ni ijọba wọgile tawọn ajọdun ati ayẹyẹ miran naa si ti dẹnukọle.
- Èèyàn 13 mííràn tún ti lùgbàdì ààrùn Coronavirus ní Naijiria
- Ń ko tọrọ agbe fún ìyá Awero, Larry àti bàbà Feyikọgbọn, ẹ má sọ ire di ibi mọ́ mi lọ́wọ́ - Foluke Daramola
- 82% ọkùnrin ní kó mọ̀ pé òun ní àìsàn jẹjẹrẹ asẹtọ ní Naijiria
- Àwọn Alákòso gárèjì ló kó ìbọn àti àdá tọ ọlọ́kadà wá ní Soka-Alága ẹgbẹ́ ọlọ́kadà Ọyọ
Ilẹ Yuroopu ni ajakalẹ yi ti gbogo julọ ti o si jẹ wi pe ni Latin Amẹrika orileede Amẹrika ati ilẹ larubawa,iye awọn to n ko arun naa pọ si.
Amọ awọn orileedekan ti ribi dawọ itankalẹ arun naa eleyi ti o ti pa eeyan ẹgbẹrun mẹẹdogun titi di ọjọ kẹtalelogun osu Kẹta ti o si ti ran eeyan 340,000 lagbaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pupọ awọn orileede to wa ni Asia toun ti pe wọn sunmọ China nibi ti ajakalẹ yi ti bẹrẹ ni wọn ti n ribi mu adinku ba ajakalẹ arun yi.
Onimọ nipa ajakalẹ arun Tolbert Nyenswah to jẹ ọjọgbọn ni fasiti John Hopkins sọ pe'' o ni awọn orileede kan ti wọn gbe igbesẹ lati koju arun yi,mo si lero pe o yẹ ki a kẹkọ lọdọ wọn'' Alamuleti China ti se Taiwan fapẹrẹ ti iye eeyan to wa nilu wọn jẹ miliọnu mẹtalelogun le diẹ ko ni ju iye eeyan marundinlọgọrun to ko aisan naa ti eeyan meji si ku.
Bẹẹ lọmọ sori ni Hong ati Japan ti iye eeyan to ko aisan naa ko pọ to tawọn orileede to jina rere si China lọ.Ki wa lawọn igbesẹ ti wọn gbe.
Diẹ ninu wọn re e gẹgẹ bi ọjọgbọn Nyenswah ti se sọ
1. Sise ayẹwo lera lera

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn onimọ ti BBC ba sọrọ fidi ọrọ yi mulẹ pe sise ayẹwo fawọn eeyan ni ọna kan gbogi la ti mu adinku ba itankalẹ Coronavirus.
Yatọ si nkan ti ọjọgbọn Nyenswah sọ pe a ko le mọ bi arun ba se nipa lara awọn eeyan to lalai se ayẹwọ lati mọ iye eeyan to mu, awọn onimọ mi to fi mọ ọga agba ajọ ilera lagbaye Tedros Ghebreyesus ni sise ayẹwo fun ẹnikẹni to ba ni apẹrẹ arun naa ni ọna ati mu adinku ba itankalẹ kokoro aifojuri yi.
Asiri ibẹ gẹgẹ bi awọn onimọ ti se sọ ni pe awọn orileede to ba n se ayẹwo ni iye awọn eeyan tuntun to n ko arun naa ma n dinku lẹyin wa.
2. E ya awọn to ba ti ni arun yi sọtọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara nkan ti South Korea fi se aseyọri nipa mimu adinku ba iye eeyanto ni arun yi ni pe wọn ya awọn to ba ni arun yi sọtọ.
Toju tiyẹ laparo awọn ilẹ yi fi n se ayẹwo bẹẹ si ni wọn n tọpinpin awọn to ba ti niarun yi.
Koda ni Taiwan Singapore ati Hong Kong wọn ya awọn to ba ni arun yi sọtọ niile wọn ti wọn si fi ijiya owo itanran ẹgbẹrun mẹta dọla lelẹ fẹnikẹni to ba tapa si ofin yi
3. Ipalẹmọ ati igbesẹ kiakia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ojọgbọn Nyenswah, to ti saaju bawọn sisẹ lati koju Ebola nigba to ja ni iwọ oorun Afrika ni ọna kan pataki lati koju itankalẹ arun ni ki awọn tọrọ kan gbe igbesẹ ni kiakia lati le dena itankalẹ arun yi laarin awọn eeyan.
O ni awọn orileede bi Taiwan ati Singapore ko lọra nipa wiwa awọn to ni arun yi ati yiya wọn sọtọ.
Iwe igbadegba kan lori ilera ti ẹgbẹ awọn onimọ ilera Amẹrika gbe jade sọ pe aseyọri Taiwan nipa kikoju Coronavirus ko sẹyin pe wọn ti n mura kalẹ lati igba ti ajakalẹ SARS ti kọkọ bẹ silẹ nibẹ.
O ni saaju ki wọn ti fidi ọrọ itankalẹ lati ara ẹni kan si omiran ni aarin osu kini ọdun ni Taiwan ti bẹrẹ si ni se ayẹwo awọn arinrinajo to n wọ ilẹ wọn lati ilu Wuhan ti arun yi ti kọkọ sẹyọ.
Iru igbesẹ kiakia yi naa ko jẹ nkan ti Hong Kong naa fi sere ti eleyi si ranwọn lọwọ lati le dẹkun ajakalẹ naa.
4. Itakete si ara ẹni lawujọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọna miran ti a le fi dena itankalẹ arun yi ni ki a ri wi pe a tẹle ilana ki awọn eeyan ma talanga sirawọn ti wọn ba wa nita tabi laarin eeyan.
O ni awọn orileede ti o sunmọ China to yẹ ki ajakalẹ arun yi pọ lọdọ wọn ribi fi ilana yi lelẹ ti wọn si tẹlẹ.
Nigba ti yoo fi di ipari osu Kini ọdun yi, Hong Kong gẹgẹ bi apẹrẹ ti ni ki wọn ti gbogbo ile iwe ti wọnsi ti wọgile gbogbo ayẹyẹ eleyi ti yoo u ki awọn eeyan ma darapọ mọ ara wọn.
5.Titẹle ilana itọju ara ẹni ati imọtoto to peye

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ipari awọn onimọ salaye pe ki a ri pe a moju to ilera ara wa ka si tun gbajumọ imọtọto.
Bi a ko ba gbagbe bi wọn ti se n sọ fun wa, ọwọ fifọ pẹlu omi ati osẹ se pataki.
Pupọ awọn ilẹ Asia lo ti kẹkọ lara ajakalẹ arun SARS ni ọdun 2003.
Wọn ti mọ pe ti awọn ba gbaju mọ imọtotọ awọn ko ni ni arun naa bẹ si ni awọn ko ni le ko ran ẹlomiran.
Bakanna ni ajọ WHO ti se sọ fun wa pe ọwọ fifọ ati imọtoto se koko ti a ba fẹ dena ajakalẹ arun.
Lawọn ikorita kaakiri orileede bi Singapore,Taiwan ati Hong Kong awọn aye wa ti wọn fi omi ati osẹ ifọwọ si fawọn eeyan ti lilo ibomu si jẹ nkan to kari laarin awọn eeyan wọn.














