Mo ti kọkọ sọ fún Toyin Abraham pe mi o le ṣe amúgbálẹ́gbẹ rẹ̀- Sam Olatunji

Oríṣun àwòrán, Toyin/instagram
Gbajúmò osere tíátà lobinrin, tó ń kopa ninu ère tíátà lédè Yorùbá àti oyinbo ní Toyin Abraham.
Ọ̀pọ èèyàn ni kò mọ pe arẹwà obìnrin náà la ọpọ ìṣòro kọjá, ẹni ta sì ro pe kò le è pagọ ni, tó sì di ẹni tó ń kọlé alárrinrin lónìí.Nígbà tó ń mẹnuba diẹ ninu ìṣòro tí Toyin tí là kọjá, alukoro àti Alakoso fún osere-binrin náà, Sam Olatunji kéde pé ọpẹ ló yẹ fún Ọlọ́run.
o ni ti bá wo bó ṣe yí ìgbésí ayé Toyin Abraham padà sí rere báyìí, yàtọ̀ sí ipò aláìní tó wà tẹ́lẹ̀.Nígbà tó ń fi ẹ̀mí imoore rẹ hàn sí Ọlọ́run lójú òpó Instagram rẹ, Olatunji mú ọjọ́ tó kọ́kọ́ pàdé osere-binrin náà wá sí ìrántí, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ibaraẹnisọrọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Olatunji ni: "Toyin lo fi atẹjisẹ kan ránsẹ sí mi lọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn lórí ẹ̀rọ ilewọ BBM, pé ki ileesẹ mi wá máa ṣe àkóso àti alarina isẹ rẹ.
Taa mọ sí Public Relations. Ń ko roo ní ẹẹmeji tí mo fi sọ fun pé owó ìṣẹ wa wọ́n pupọ."
"Ìdí tí mo fi sọ̀rọ̀ bẹẹ ni pé, a kì í ṣiṣẹ́ pọ pẹ̀lú àwọn osere tíátà lédè Yorùbá, ẹnìkan ṣoṣo tó kanka nínú wọn, èyí un Funke Akindele, nikan la ń bá ṣiṣẹ."
Ṣùgbọ́n Olatunji ni, riro ni ti eniyan, àmọ́ sise ni ti Ọlọrun, torí nígbà tó di ọdún 2017, ní gbajumọ akọroyin orí ayélujára kan, Stella Dimoko-Korkus kesi òun pé, òun ni òun sọ fún Toyin pé kò pé òun, láti máa sisẹ Alarina fun-un, ó ni akoko yii gan an ni àìmọye abawọn si tí tá sì aṣọ ààlà Toyin Abraham.
"Mo wá rí isẹ yìí bíi anfaani fún mi láti ṣe àtúnṣe si ìwà ìgbéraga tí mo hù sí osere-binrin náà ṣáájú nígbà tí mo ní owó isẹ wa wọ́n pupọ.
A pinnu láti fojú rira, ìrísí Toyin lọ́jọ́ taa kọkọ rira dàbí tí gbajumọ osere ti ko sí lójú ọpọn mọ, ẹni tí ipenija ayé àti ibalorukọjẹ lorisirisi tí sọ di idakuda, kódà, kò jọ gbajumọ osere rárá. "
Olatunji salaye pe: Mo kọ́kọ́ fẹ́ kọ láti bàa ṣiṣẹ́ àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ sọ wípé kí n gba, tí ìtọ́ni sì wá fún mi lórí ohun tó yẹ ká ṣe láti mú àyípadà rere bá ayé rẹ. "Òṣìṣẹ́ alarina Toyin Abraham náà ni, ẹ̀rọ ibaraẹnisọrọ ti osere-binrin náà mú lọ́wọ́ lọ́jọ́ naa sì ku ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ náírà, tí yóò fi sanwó fóònù náà tán.Olatunji ni òun sọ fún pé, kò jẹ ki awon ṣe àyípadà pátápátá bá ìtàn ayé rẹ tó bá fẹ́, tó sì gba sí òun lẹ́nu, ó ní bẹ́ẹ̀ lo bọ aṣọ ìgbéraga silẹ, tó sì ń ṣiṣẹ́ náà."A gbé ìlànà kan kalẹ, a kesi àwọn akọroyin, a mú àyípadà bá ibasepọ rẹ, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé làálàá mi lórí rẹ kò já sí asán."
- Kí làwọn ìdàmú tí Coronavirus n mú bá àgọ́ ara?
- Ṣé ìrètí wà pé coronavirus yóò dínkù lásìkò ooru?
- Link
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémíSam tun tesiwaju pe: "Ní ọjọ́ to ra ilé rẹ nílùú Ibadan, owó beba lo fi san gbogbo àìmọye mílíọ̀nù owó ilé naa lẹẹkan ṣoṣo.

Ń ko tọrọ agbe fún ìyá Awero, Larry àti bàbà Feyikọgbọn, ẹ má sọ ire di ibi mọ́ mi lọ́wọ́ - Foluke Daramola
Foluke Daramola ṣalaye kikun lórí ahesọ àwọn eeyan lorí pé òun ń tọrọ owó fáwọn Baba Feyikọgbọn àti Iya Awerolásìkò ìgbélé coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Foluke/instagram
Gbajúmò osere orí ìtàgé lobinrin, Foluke Daramola, ẹni tó máa ń béèrè àánú fún àwọn akẹẹgbẹ rẹ tó nílò iranlọwọ, ti ń rawọ ẹ̀bẹ̀ sáwọn aráàlú pé kí wọn má ṣe sọ isẹ àánú tí òun ń ṣe di ibi mọ òun lọ́wọ́.Daramola, ẹni tó kígbe síta bẹẹ lójú òpó Instagram rẹ lọ́jọ́ Ẹti ṣàlàyé pé, àwọn ènìyàn kan ló ń kígbe kiri pé ìyá ńlá lo ń jẹ àwọn àgbààgbà mẹtẹẹta nínú osere tíátà tí òun dárúkọ náà, torí òun ń tọrọ agbe fún wọn.
Foluke, ẹni tó ní inú òun bàjẹ sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wá ń béèrè pé, òun kò mọ idi ti àwọn èèyàn ṣe máa ń dori ọ̀rọ̀ kodò, táwọn èèyàn sì ń pe oun nípa àwọn àgbàlagbà mẹtẹẹta náà."Iya Awero, ọnku Larry àti Baba Feyikọgbọn kò fìgbà kankan tọrọ oúnjẹ àbí iranwọ lọ́nà kọna lọ́wọ́ mi rí, mo kan béèrè iranwọ fún wọn gẹ́gẹ́ bíi ara aáyán mi láti ṣe atilẹyin fún wọn."
Foluke Daramola ni: "Kódà èmi àti ọnku Laary ń jó papọ nínú fídíò tí mo gbé síta ni, tí wọn sì sọ fún mi pé àwọn fẹ́ ṣe filọlẹ ìwé táwọn kọ nígbà tí Ìyá Awero ní àwọn fẹ́ ṣe ọjọ́ ìbí.
Èmi kò wá mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń ní iya ń jẹ àwọn èèyàn yìí.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
"Ẹ jọ̀wọ́ nítorí Ọlọ́run, ẹ má jẹ́ kí oore di ibi mọ mi lọ́wọ́. Mo kan ń tiraka láti ṣe ojúṣe mi ni bí ọmọ ṣe ń satileyin fún òbí, àwọn èèyàn yìí ní àwọn ọmọ gidi tó ń tọju wọn."
Ó ní èyí kò wu etí gbọ rárá, bẹ́ẹ̀ ni kò dára, òun kò sì fẹ́ bẹẹ torí àwọn náà kò tọrọ oúnjẹ àti owó lọ́wọ́ òun rí.
Lásìkò igbele Covid-19 yìí náà ni Foluke Daramola tún lọ kí bàbá Feyikọgbọn nílé láti fun ní ẹ̀bùn owó èyí tó mú káwọn èèyàn kan rò pé ìyà ló ń jẹ bàbá yìí, tí Foluke ṣe lọ fún ní owó.
Bákan náà ni isẹ àánú tó ń ṣe lásìkò igbele Covid-19 yìí tún gbe dé ọdọ Ìyá Awero.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Foluke wá rawọ ẹ̀bẹ̀ pé káwọn ọmọ aráyé má ṣe sọ isẹ àánú di isẹ ibi mọ òun lọ́wọ́.

Funke Akindele tọrọ àforíjì, Lateef Adedimeji d'obìnrin, Bàbá Ire kó ìrẹsì lọ Ogbomoṣo
Yoruba Films: Funke Akindele tọrọ àforíjì, Lateef Adedimeji d'obìnrin, Bàbá Ire kó ìrẹsì lọ Ogbomoṣo

Oríṣun àwòrán, Instagram
Awọn oṣere tiata Yoruba ṣi n dara papaa julọ loju opo Instagram wọn, bo tilẹ jẹ pe konle-o-gbele wa nita.
Bo tilẹ je pe ijọba kede konile-o-gbele nipinlẹ Eko, Ogun ati olu ilu Naijiria, Abuja nitori ajakalẹ aarun coronavirus, ọpọ nnkan lo ṣi ṣẹlẹ lagbo oṣere lọsẹ yii.
Awọn oṣere tiata Yoruba ṣi n dara papaa julọ loju opo Instagram wọn.
Wọnyi ni awọn ohun to ṣẹlẹ lọsẹ yii lagbo awọn oṣere tiata Yoruba lọsẹ yii.
Funke Akindele
Gbajugbaja oṣere ti ọpọ mọ si Jenifa tọrọ aforiji lọwọ awọn ololufẹ rẹ lẹyin to ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọkọ rẹ, Abdulrasheed Bello ti ọpọ mọ si JC Skillz ti o si tun fi fọnran fidio ayẹyẹ naa to fi si oju opo Instagram rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ti fi ọwọ ofin mu Funke Akindele ati ọkọ rẹ lori ẹsun pe ohun ti wọn ṣe lodi si ofin konile-o-gbele to wa lode.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 4
Wọn gbe wọn lọsi ileẹjọ majisireti nibi ti wọn ti sọ pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn, adajọ ni ki wọn san owo itanran pẹlu tii ṣe ẹgbẹrun un lọna ọgọrun naira fun ẹnikọọkan wọn pẹlu iṣẹ sinsin ilu.
Amọ, Funke Akindele ti rawọ ẹbẹ sawọn eeyan wi pe ki wọn jeburẹ, o ni oun gba pe ohun t'oun ṣe ku diẹ kaato.
Kolawole Ajeyemi
Kolawole Ajewole to jẹ ọkọ gbajugbaja oṣere, Toyin Abraham ti dide iranwọ fawọn ara ilu Ogbomoṣo, tii ṣe ilu abinibi rẹ.
Ajewole ni o ṣe pataki fun oun lati ṣe iran fawọn eeyan ilu oun lasiko ajakalẹ aarun coronavirus yii ti ijọba ni kawọn eeyan maa takete si ara wọn.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 5
O ṣalaye loju opo Instagram rẹ pe oun yoo pin irẹsi, o ni kawọn eeyan maa pe lori eto Gelede to waye lori ile iṣẹ redio Parrot.
Lateef Adedimeji
Gbajugbaja oṣere, Lateef Adedimeji gbarada lẹyin to ro dẹdẹ to kan dudu bi awẹlẹwa obinrin.
Niṣẹ lo tọju to si tọ ẹnu, koda o tun fijo bẹẹ ninu fọnran to fi lede lori oju opo Instagram rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 6
Bi o ṣe n jo, bẹẹ naa ni awọn eeyan n na lowo ti o si n sọ pe ''Iya Peju ti fẹ jẹ gbese.''
O ki awọn onigbagbọ atawọn musulumi ninu fidio ọhun ku ọdun Ajinde, bakan naa lo ki wọn ku ọjọ Jimọ.
Peju Ogunmola
Gbajugbaja osẹre, Peju Ogunmola dupẹ lọwọ Eleduwa fun anfaani lati wa laaye bi o ti n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.
O bẹbẹ pe ki Ọlọrun tubọ maa bukun fun oun bi oun tun ti le ọdun si.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 7
Peju ni ọjọ ibi oun jẹ ọjọ kan to ṣe pataki julọ ninu igbesi aye oun.
Bẹẹ ni o ki ara rẹ ku ọjọ ibi wi pe ẹmi oun yoo ṣe ọpọ rẹ laye ati laaye.