Coronavirus pandemic numbers:Ṣé ìrètí wà pé coronavirus yóò dínkù lásìkò ooru?

Ọkọ kan n lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwadii ti awọn onímọ̀ ṣe ko ti i fihan boya itura tabi ayipada yoo de ba itankalẹ aarun coronavirus lasiko ooru.

O dabi ẹni pe eero pe ooru le fi opin si Itankalẹ coronavirus ti dawọ duro, bi aarun naa ṣe n tan kaakiri agbaye. Sugbọn ṣe iwadii tuntun ni ireti ninu ?

O ti ya ju lati mọ boya o ni ìgbà ti aarun coronavirus tuntun yii ma n jade.

Lati mọ eyi, ao nilo lati sakiyesi ayipada to n deba itankalẹ rẹ ni ibi kan lati ibẹrẹ ọdun si opin ọdun.

Ṣugbọn a le ṣe agbeyẹwo itankalẹ rẹ ni orisirisi orilẹ-ede ti oju ọjọ wọn yatọ si ara wọn fun àmì.

Ẹri wo lo wá?

Awọn ẹri kan wà pe awọn to ni aarun coronavirus wọpọ julọ ni awọn agbegbe to ni ọgbẹlẹ tabi ti ko gbona ju.

Iwadii kan ti ẹ fihan pe awọn orilẹ-ede ti aarun naa pọ si - awọn ibi to ti n tan kiri nipa ifarakanra - ní oju ọjọ to jẹ ko gbona-kò tutu, ju awọn agbegbe ti aarun naa ko ti wọpọ.

Iwadii kan tun se agbeyẹwo ọgọrun ìlú ni China, nibi ti coronavirus ti kọlu eniyan to le ni ju ogoji, o si tọka si i pe ti oju ọjọ ba tutu gan-an, aarun naa ko ni i fi bẹ ẹ tankalẹ.

Abajade iwadii miran ti wọn ko ti i ṣe agbeyẹwo rẹ sọ pe botilẹjẹ pe ko si ibi ti aarun coronavirus tuntun yii ko de ni agbaye, itankalẹ rẹ kóra jọ si awọn agbegbe ti ọgbẹlẹ wá - ko to o di ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta.

Ṣugbọn bi awọn oluwadii kan ni London School of Hygiene and Tropical Medicine, ṣe sọ, aarun coronavirus ti tan de gbogbo agbegbe ti ajọ eleto ilera l'agbaye, WHO, n mojuto. Bo ṣe n mu wọn nibi ti ooru ti n mu, lo n mu wọn nibi ti otutu wà.

Njẹ iyatọ wa laarin àríwá si gúúsù?

Nitori bi nkan ṣe ri pẹlu awọn aarun miran, to fi mọ aisan otutu, o jọ pe o ni asiko to ma n waye ni iha àríwá. Sugbọn àwọn agbegbe ti ojo ti ma n rọ, to si sunmọ aarin, n ni ìrírí kan naa.

Ati pe diẹ lara awọn agbegbe tutu to ti ni itankalẹ aarun naa ni abẹle, bi Malaysia ati Democratic Republic of Congo, sunmọ agbedemeji, nitorina o le maa fun wa ni ẹri to daju nípa bi nkan yoo ṣe ri nibo miran.

Okun omi nla

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìdí miran tun ni bọọlu gbigba l'agbaye ati bi eniyan ṣe pọ to laye.

Ni wọn igba ti aarun naa si ti tan kaakiri agbaye diẹ diẹ - nipa irinajo kiri agbaye - ti oju ọjọ si ti n yi pada, o ṣòro lati tọka si ipa oju ọjọ.

Njẹ awọn coronavirus yooku ni asiko ti wọn ma n tan kaakiri?

Ẹri wa pe awọn aarun coronavirus yooku saba ma n tan kaakiri lasiko òtútù, gẹgẹ bi iwadii awọn oluwadii lati University College ni London ati London School of Hygiene and Tropical Medicine se fi mulẹ.

Wọn beere lọwọ bí i ẹgbẹrun meji eniyan, boya ẹnikẹni ninu ile wọn ni àmì aisan to ni ṣe pẹlu èémí.

Wọn si sọ fun ẹnikẹni ti o ba ni àmì kankan lati lo íretí fi ṣe ayẹwo orisirisi aarun.

Afikun nipa aarun Coronavirus
Banner

Lati ara iwadii yii , awọn oluwadii naa ṣe akiyesi pe asiko otutu ni coronavirus lọ soke pupọ, ni asiko kan naa ti aisan otutu maa n wà. Awọn to ni i lasiko ooru ko pọ.

Ọkan lara awọn to kọ iwe naa, Ellen Fragaszy ni UCL sọ pe "o se e ṣe ki a ri itura díẹ̀ lasiko ooru". Sugbọn ko si idaniloju pe bi aarun tuntun yii ṣe n ṣe niyẹn.

Bi awọn to ni i ṣe n pọ si, to si n tan kaakiri agbaye fihan pe a ko gbọdọ ni ìrètí pe ara yoo tu wa ni asiko ooru.

Njẹ aarun yii da bi awọn coronavirus yooku ?

Aarun coronavirus tuntun yii, ti wọn n pe ni Sars-Cov-2, to n fa Covid-19, jọ pe o n tan kaakiri bi awọn aarun coronavirus yooku.

Ṣugbọn nkan to mu ko yatọ ni bi o ṣe n mu ki aarẹ ko mu awọn eniyan, ati iye eniyan to ti pa.

Dokita Michael Head, ni Fasiti ilu Southampton, sọ pe idagbasoke ati ipa aarun coronavirus tuntun yii "yatọ patapata si aisan otutu to wọpọ.

O sọ pe "O ku ki a maa woye pe boya aarun Covid-19 yoo dinku bi ayipada ba ṣe n deba oju ọjọ bi i ooru ati otutu.