Coronavirus death: Háà erin wó! Ẹ wo iye ọmọ Yorùbá tó bá Coronavirus lọ lókè òkun

Awon omo naijiria ti Coronavirus ti pa ni ile okere
Àkọlé àwòrán, Háà erin wó! Ẹ wo iye ọmọ Yorùbá tó bá Coronavirus lọ lókè òkun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajakalẹ Aarun Coronavirus lo bẹ silẹ lorilẹ-ede China loṣu kejila ọdun 2019.

Ni eyi to ti ṣọṣẹ to pọ lawọn orilẹ-ede agbaye bii Spain, Italy, Uk àti America nibi ti ẹgbẹlẹgbẹ ẹmi ti sọnu.

Bayii, eniyan mẹfa lo ti jẹ Olorun nipa ni orilé-ede Naijiria yatọ si awọn ọmọ Naijiria to wa loke okun to ti doloogbe.

Alaga fún àjọ tón ri si ọrọ àwọn ọmọ Nàìjíríà lókè òkun, Abike Dabiri Erewa sì ti ṣe fídíò kan láti bu ọlá fún àwọn ọmọ Naijiria to tio doloogbe lẹyin odi nibi ti wọn ti n muṣẹ aje ṣe.

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ́ àwọn arúgbó nìkan ni ààrùn coronavirus ń mú?

Abikẹ Dabiri ki awọn olóògbé náà gẹgẹ bii akọni to ṣubu loju ija lasiko ajaklẹ arun coronavirus.

Nínú orúkọ àwọn èèyàn mẹ́tàlá náà tijọba kéde rẹ, márùn-ún nínú wọn lo jẹ́ ọmọ Yorùbá.

Bẹẹ si ni láàárín orúkọ àwọn alaisi tó jẹ́ Yorùbá náà, mẹrin nínú wọn lo kú sí Ilẹ UK, ọkan yoku sì kú si Amẹrika.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Awọn tó kú sí ilẹ UK ni Agba amofin Kole Abayomi, Bode Ajanlekoko, Adeola Onasanya àti Alfa Sa'adu.Ẹnikan ṣoṣo tó kú sí ilẹ Amẹ́ríkà ni Akeem Adigun.

Àkọlé fídíò, Eniyan mẹfa lo ti ku nitori arun Coronavirus yii lorileede Naijiria.

Bákan náà, àwọn ọmọ Nàìjíríà márùn-ún miran, tí kìí ṣe ẹ̀yà Yorùbá lo tún bá àrùn Covid-19 lọ ní Amẹ́ríkà, tí mẹta míì sì kú ni UK. Àwọn to kú ní Amẹ́ríkà ni Bassey Offiong, Caleb Anya, Mmaete Greg, Laila Abubakar àti Patricia Imobhio.

Àwọn tó kú sí ilẹ UK ni Carol Jamabo, Ugochukwu Erondu àti Chidinma Olajide.Lọ́wọ́-lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ tí ń saayan láti kó àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà lókè òkun wálé.

Àkọlé fídíò, Ilu Ubang, jẹ ilu kan nibiti ede ti awọn ọkunrin wọn n sọ yatọ si ti awọn obinrin wọn.