Oyo drivers'crisis: Auxiliary ń ní wá lára pẹ̀lú gbígba owó aitọ, a ń ko ọkọ̀ wa kúrò lójú pópó - Awakọ èrò

Oríṣun àwòrán, others
Àwọn awakọ èrò kan tó ń ná àdúgbò Bẹẹrẹ si Omi-Adio n'ilu Ibadan tí fi igbe ta pé, àwọn kó ni ṣiṣẹ mọ, tí àwọn si n kó ọkọ àwọn kúrò lójú pópó nítorí owó aitọ táwọn alakoso gareji ọkọ ńi kí àwọn máa san.
Àwọn awakọ ero náà, tó fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọlẹ́yìn alága àwọn alákòóso gareji ọkọ nipinlẹ Ọ̀yọ́, Alhaji Mukaila Lamidi, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ si Auxiliary pé, wọn kàn-án nípa fún àwọn láti máa san owó ni ibudokọ kọ̀ọ̀kan lojoojumọ, yàtọ̀ sí owo ti jọba ní kí àwọn máa san.
- Ọwọ́jà coronavirus yóò ṣì wà pẹ̀lú àgbáyé fún ìgbà pípẹ́- Ngozi Okonjo-Iweala
- Ìjọba àpapọ̀, ẹ so ifilọlẹ ẹ̀rọ alatagba 5G rọ na - ilé asofin àgbà
- Wo àwọn to ti rí ìwòsàn lọ́wọ́ àrùn coronavirus àti ibi tí wọ́n ti wá káàkiri Nàìjíríà
- Mẹ́rin nínú àwọn mọ́kànlá tó ń bọ̀ láti Sokoto tí wón mú l'Oyo ló ní Coronavirus
Àwọn ọlọkọ èrò naa, lásìkò ti wọ́n ń báwọn akọroyin ileeṣẹ iroyin kan, 'Oyo insight' sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé, ọọdunrun náírà péré ni ìjọba Ọ̀yọ́ paa ni àṣẹ fún àwọn láti máa san lojumọ, tí Auxiliary gan-an sì wá sọ fún àwọn fúnra rẹ, àmọ́ nígbà tó yá ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ padà wá pé, ibudokọ kọ̀ọ̀kan ni àwọn yóò ti máa san ọgọrun náírà báyìí ni àárọ̀ àti Alẹ́, èyí tí yóò jẹ́ egbèje náírà, #1, 400, yàtọ̀ sí owó tijọba.
Àwọn awakọ náà tún sàlàyé pé, ibùdókọ meje lo wà láàrin Bẹẹrẹ sì Omi-Adio, èyí tó mú kí owó tí àwọn yóò san ni àárọ̀ àti alẹ fáwọn Auxiliary jẹ́ egbèje náírà lojumọ, tí àwọn yóò sì tún san ọọdunrun náírà fún ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àmọ́ àwọn ti yari láti san owó náà.
Àwọn ọlọkọ náà ni àwọn pe ìpàdé pọ pẹlu awọn ọmọ igbimọ alakoso gareji lori ọrọ yìí ni ọjọ́ Ajé nítorí owó náà pọju fún àwọn láti san, ṣùgbọ́n ní kété tí wọn gunlẹ sì gareji Bẹẹrẹ naa pẹ̀lú àwọn tọọgi wọn, ní wọn ń na àwọn.
Wọn ní "wọn tí mú ọkàn lára wa, Alfa Coach Kehinde lọ sí agọ ọlọ́pàá Mapo, tí wọn si sọ si ahamọ pé, àwọn yóò fi jofin fún àwa yoku"
" Nígbà tá tún lọ sí agọ ọlọ́pàá láti gba Kehinde silẹ, ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà ni wọn ní ká mú wá ní ìbẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n ní báyìí, wọn ti ní ká san ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà."
Àwọn awakọ èrò náà wá ń rawọ ẹbẹ sì ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pé kò dá sí ọ̀rọ̀ náà, kò sì ṣàánú àwọn, nítorí àwọn tí setan láti san ọọdunrun náírà tí ìjọba ni kí àwọn san.
Iwo road crisis: Ẹgbẹ́ awakọ̀ ní wahálà wà, 'Auxilliary'ló sì ń fàá; ọlọ́pàá ní kò sí ìjà, pẹ̀sẹ̀ bí omi òwúrọ̀ ni Iwo road wà ní Ìbàdàn

Oríṣun àwòrán, others
Ọ̀rọ̀ di boo lọ, ko yàgò fún mi ní àárọ̀ ọjọ́ Aje nígbà ti rògbòdìyàn miran tun bẹ silẹ ni agbegbe Iwo Road nilu Ibadan.Ọ̀pọ̀ èèyàn, to ń pariwo pé àwọn awakọ èrò tún ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù wọn, ló ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn, tí ariwo si n waye làwọn ori redio kan nilu Ibadan pe ki awọn ọlọ́pàá máa lọ sí àgbègbè Iwo Road láti tètè bu omi pá iná wàhálà náà,
kó tó fẹ́ ojú sì.
- Coronavirus ló lé mi kúrò níléèwòsàn UCH n'Íbàdàn- Ogun Majek
- Ta a ni yóò rọ́pò Abba Kyari gẹ́gẹ́ bi olórí òṣìṣẹ́ Buhari?
- Àṣìṣe ló ṣẹlẹ̀ níbi ètò ìsìnkú Abba Kyari- FCTA
- Yewande bí'mọ tuntun jòjòló, Mercy Aigbe pàdánù èèyàn rẹ̀, Toyin Abraham fèsì lórí aṣoju NCDC
- Ìtàn Manigbagbe: Àwọn àjakalẹ-àrun to ti wáyé rí ṣáájú Coronavirus
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún BBC Yoruba, Alaga ẹgbẹ́ awakọ èrò ni Ipinlẹ Oyo, NURTW, tí ìjọba ti fofin de, Alhaji Abideen Olajide, tí gbogbo èèyàn mọ sì Ejiogbe, ṣàlàyé pé ẹgbẹ́ awakọ èrò kò lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn náà
rara."Kii se ọmọ ẹgbẹ́ awakọ èrò lo ń fa wàhálà, digbi la wá, a kò sì já, kódà, kò sì àwọn mọto wa ninu gareji ọkọ mọ gan àmọ́ àwọn èèyàn ti ìjọba yàn bíi Alakoso gareji lo ń ba ara wọn jà.""Oludari fún àwọn alakoso gareji ọkọ ti jọba yàn, Mukaila Lamidi - Auxiliary lọ ń jà káàkiri ìlú, nígbà ta si ti mọọ tẹ́lẹ̀, a kò sì fẹ́ kí orúkọ wa bajẹ, là ṣe ni sùúrù fún".

Oríṣun àwòrán, others
Ejiogbe fikùn pé, kii se àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn, NURTW, lo ń bá ja, àmọ́ ó ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kan, to ṣe apejuwe wọn bíi ọdalẹ tí kò ní sùúrù, tí wọn lọ bá Auxiliary ṣe Alakoso gareji, ní wọn dijọ ń bá ara wọn jà.Ejiogbe ni "lati ọjọ́ tí Mukaila ti ń dá wọn èèyàn láàmú, tó ń ṣe àwọn èèyàn lese, ìjọba ni irọ la n pa, ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn si lo wa ni agọ̀ ọlọ́pàá nípa rẹ, àmọ́ ń ko fẹ́ sọ̀rọ̀ pupọ nípa rẹ".Nígbà tí òun náà ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Ọtunba Lekan Alesinloye, tíì ṣe igbakeji akọ̀wé fún ẹgbẹ́ awakọ èrò nipinlẹ Ọ̀yọ́, NURTW, ti ijọba ti fofin de ṣàlàyé pe, àwọn awakọ tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ NURTW ni awakọ, àwọn
si ti kúrò ní gareji tí to ọdún kan.
Alesinloye ni "tẹ bá wà gbọ pé wọn ń jà ní gareji láti oṣù keje ọdún tó kọjá táwa ti kúrò níbẹ, kii se àwa." Àwọn Auxiliary náà ni, òun àti àwọn 'boys' rẹ ni wọn jọ ń ja, kódà, laarọ yìí ni àwọn èèyàn pe wa pe wọn tí ń já ní Iwo Road ó, à wa pé awon eeyan wá tó wà nibẹ, wọn ní Mukaila àti 'boy' rẹ kan to wa ni ile epo kan ni Iwo
Road ni wọ́n jọ ń ja, wọn ṣe é lese, wọn si gbe lọ, kò sì sí ẹnì tó mọ ibi tí wón gbé lọ".Alshinloye ni ẹni tó gbé lọ yìí kii se ara NURTW, ọmọ Auxiliary ni, kò sì sí òun tó kàn àwọn nibẹ torí àwọn Auxiliary kii se Ọlọkọ mọ, Alakoso gareji ni wọn.
Nigba tó ń ṣàlàyé ìdí tí wọn ṣe kó àwọn ọkọ wọn kúrò ní gareji gbogbo, igbakeji akọ̀wé ẹgbẹ́ awakọ NURTW ni "wọn ń bá àwọn ọkọ wa jẹ, ohun tó kú ní ká kò dúkìá wá kúrò nibẹ, a sì ti sá ipa wá kí gomina leè gbé ẹsẹ kúrò lórí
òfin ti wọn si de ẹgbẹ́ wá, tí aarẹ ẹgbẹ́ lapapọ gan tí wá rí gomina bíi ìgbà méjọ àmọ́ gomina kan ń tàn ni".Aleshinloye wá fikùn pé àwọn tí gbé ọ̀rọ̀ náà lo sílè ẹjọ́, tí àwọn sí ń dúró de idajọ ilé ẹ̀jọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Oríṣun àwòrán, others
BBC Yoruba tún kan sì alukoro Ọlọpaa nipinlẹ Ọ̀yọ́, Olugbenga Fadeyi láti fìdí rògbòdìyàn náà múlẹ̀, àmọ́ ó ní kó sì rògbòdìyàn kankan tó wáyé laarọ ọjọ́ Aje ni agbegbe Iwo road.Alukoro Ọlọpaa ni loore koore ni àwọn òṣìṣẹ́ Ọlọpaa ń wá ní agbègbè yìí àti àwọn àgbègbè miran nigboro Ibadan àti ní àwọn ìlú miran lọsan àti ní òru.
Ọyọ crisis: Àwọn ọmọ Nàìjíríà fẹ́ kí Gómìnà Seyi Makinde ó pe ìpàdé àlááfíà láàrín Sunday Igboho àti Auxilliary

Oríṣun àwòrán, seyi makinde
Awọn ọmọ Naijiria ti ke si gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde pe ko wa nnkan ṣe si iṣudẹdẹ ojo wahala to ṣu ni ipinlẹ naa bayii pẹlu bi awọn eekan meji kan, Sunday Igboho ati aṣiwaju ẹgbẹ ọlọkọ ero Lamidi Mukaila ti ọpọ mọ si Auxilliary.
Ni ẹnu ọjọ mẹta yii ni iroyin aawọ laarin awọn mejeeji yii bẹrẹ si ni lu si igboro pe ọrọ emi ni mo ju ọ, iwọ lo jumi laarin awọn mejeeji yii.
Pupọ lara awọn ọmọ Naijiria ti wọn fi ero wọn han loju opo Facebook BBC News Yoruba ni wọn fi aidunnu wọn han lori bi nnkan ṣe n lọ laarin awọn mejeeji yii.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Bakan naa lawọn miran n ke si ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ẹka agbofinro miran lati tọwọ ọmọ awọn mejeeji yii bọ aṣọ ki wọn to da omi alaafia ipinlẹ Ọyọ ru.
Awọn miran o yẹ ki awọn mejeeji yii pe aro ati ọdọfin inu wọn ati pe ko yẹ ki ọrọ bayii pin awọn mejeeji yii niya nitori pe 'ọmọ iya lawọn mejeeji yii' o
Sunday Igboho rán agbénipa sí mi láti gb'ẹ́mi mi-Auxilliary
Alaga ẹgbẹ àwọn Alakoso gareji ọkọ nipinlẹ Ọ̀yọ́, Alhaji Mukaila Lamidi, tí ọpọ èèyàn mọ sì Auxiliary, tí sọ̀rọ̀ lórí rògbòdìyàn tó wáyé ládùúgbò Soka, nílùú Ibadan laipẹ yìí.
Auxiliary, ẹni tó bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ tún mẹnuba bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe kan èèkàn àwùjọ kan, Oloye Sunday Adeyemo, tí àwọn èèyàn tún mọ sì Sunday Igboho.
- Síńimá kòṣewòtán, Pásítọ̀ fo fẹ́ǹsì láti sá mọ́ agbófinró lọ́wọ́ ní Àkúrẹ́
- Inú ìbèrù bojo ni àn gbé báyìí- Awọn ènìyàn àdúgbo, Ogba, Agbado Ijaye àti Agege
- Ìrìnàjò Toyin Abraham, láti orí gbèsè jíjẹ, ó di onílé, onimọto àti aya lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ
- 82% ọkùnrin ní kó mọ̀ pé òun ní àìsàn jẹjẹrẹ asẹtọ ní Naijiria
Auxiliary ni ọkùnrin kan tí wọn ń pè ní Remi Soka lo kọlu àwọn ọmọlẹ́yìn òun ti ìjọba yàn láti máa gba owó lọwọ àwọn ọlọkada ni adugbo Soka, tó na wọn pé àdúgbò òun ni ibẹ, wọn kò sì ní ẹtọ láti máa gba owó.
O fikùn un pé nígbà tí òun tún ń kọjá ní irọlẹ ládùúgbò náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Remi Soka yìí tún kọlu òun, wọn ń lẹ òkúta mọ òun, èyí tó mú kí ọkọ òun dúró ṣùgbọ́n wọn kò dúró de òun rárá.
"Òun gan kò lè dúró de mi láéláé àmọ́ wọn tí se àwọn ọmọ wa léṣe gan. Kódà, àwọn ọlọkada tó wà nibẹ gan tí mú ẹ̀sùn rẹ wà pé, Ó wá ń gba owó oúnjẹ fún Igboho, ẹni tí kìí se ọmọ Ibadan, tó wá ń fi ọwọ la ilẹ̀."

Oríṣun àwòrán, The Park Management Oyo State Facebook
Auxilliary ni: "Ọmọ mi ni Sunday Igboho, to sì tún rán àwọn agbenipa si mi lọ́nà Iwo, níbi ìsìnkú Alhaji Táwa, tí wọn dibọn bíi ọlọ́pàá SARS, àmọ́ mo fọwọ́ lẹran, mo ń wo ó ní.
Ó sì leè de ẹyin, kó padà máa pè mí wí pé òun kọ ni òun hùwà ọhun.
"Kódà, wọn tún máa ń pariwo pé kò sì ohun tí ìjọba fe ṣe, kò sì ìjọba. Gbogbo ohun tí Igboho sì ń sọ yẹ, kò leè sọ lójú mi torí òun gan lo ń dá gbogbo wàhálà yìí silẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì ṣiṣẹ fún ìjọba yìí, ìjọba to ṣiṣẹ fún tí parí."
"Ijoba APC ni Igboho tẹle pẹlu awọn Fẹlẹ, débi pé lórí ẹsẹ aimọdi, ẹ rán mí lọ síbi tí ń ko fẹ́, mo lọ, mo bọ. Ìjọba tèmi náà wá dé, ẹ ní a kò ní fi ara re lo o, ẹ ń da ìjọba láàmú.
"Nígbà tó ń ṣẹ lórí ahesọ ọ̀rọ̀ kan tó ní owó kotọ ni wọn ń gbà lọ́wọ́ àwọn ọlọkada, Auxiliary ṣàlàyé pé ìjọba ló yan àwọn sípò, ìjọba náà sì ni àwọn n pawo fún, kò sì sí owó kankan tí àwọn gba, tí ìjọba kò mọ sí.

Oríṣun àwòrán, The Park Management Oyo State Facebook
Auxiliary fikùn pé láti ọjọ́ tí aláyè ti dáyé, ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ọlọkọ ero NURTW, tó bá ṣiṣẹ fun oludije gómìnà kan, ní wọn yóò fi jẹ alaga ẹgbẹ́ NURTW, tí oludije náà bá di gómìnà.
O ni bo se wáyé rèé láyé ìjọba Abiola Ajimobi to koja, to fi dé Ekiti àti Osun, ìdí sì rèé tí Ajimobi fi fà Fẹlẹ silẹ bíi alaga NURTW láyé ijoba rẹ.

Oríṣun àwòrán, The Park Management Oyo State Facebook
Auxiliary wá parí ọrọ rẹ pé òun kò ní ẹnikẹ́ni tí òun ń bá ja àmọ́ ohun tí gómìnà Seyi Makinde fẹ, ní àwọn n ba fẹ́.
Alaga ẹgbẹ àwọn Alakoso gareji ọkọ nipinlẹ Ọ̀yọ́, Alhaji Mukaila Lamidi, tí ọpọ èèyàn mọ sì Auxiliary, tí sọ̀rọ̀ lórí rògbòdìyàn tó wáyé ládùúgbò Soka, nílùú Ibadan laipẹ yìí.
Àwọn Alákòso gárèjì ló kó ìbọn àti àdá tọ ọlọ́kadà wá ní Soka-Alága ẹgbẹ́ ọlọ́kadà Ọyọ
Folaranmi ni àwọn fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó ileesẹ ọlọ́pàá tó wà ládùúgbò Sanyo létí, tí wọn sì pe igun méjèèjì sí ìpàdé àlàáfíà ni iléesẹ ọlọ́pàá tó wà ní Iyaganku.

Oríṣun àwòrán, others
Bẹẹ bá gbàgbé, a ti mú ìròyìn wá ṣáájú nípa bí Sunday Igboho ṣe kesi gomina Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde láti yọ Auxiliary nípò Alakoso gareji, torí ìwà jagidijagan tó ń hù.
Àwọn Alakoso gareji ló ko ìbọn àti ada tọ ọlọkada wá ní Soka, Igboho kò lọ́wọ́ nibẹ - Alága ẹgbẹ́ ọlọkada l'OyoẸgbẹ́ àwọn ọlọkada nipinlẹ Ọ̀yọ́ tí ṣàlàyé ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa rògbòdìyàn tó wáyé lọ́jọ́bọ ládùúgbò Soka nílùú Ibadan èyí tó kàn àwọn ọlọkada.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí eto ìfọrọwerọ kan, alaga ẹgbẹ́ àwọn ọlọkada nipinlẹ Ọ̀yọ́, ACCOMMORAN, Alhaji Saheed Folaranmi ṣàlàyé pé, àwọn alakoso gareji ọkọ tijọba yàn ni eku ẹda, tó dá rògbòdìyàn àti ìwà itapa sofin silẹ ládùúgbò Soka.
"Àwọn alákòóso gareji náà ló yà wá sí Soka bíi eṣu, láti wá kọlu àwọn ọlọkada nítorí pé wọ́n kùnà láti sanwó tó yẹ."
"Ṣe ni wọn kò Ada àti ìbọn wá, tí wọn sì ń yinbọn sókè tako-tako, bẹ́ẹ̀ ni wọn sá ọpọ ọlọkada ni ada, tí wọn sì fara gba ọgbẹ lorisirisi, ọpọ wọn sì wà nílé ìwòsàn."
Folaranmi ni àwọn fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó ileesẹ ọlọ́pàá tó wà ládùúgbò Sanyo létí, tí wọn sì pe igun méjèèjì sí ìpàdé àlàáfíà ni iléesẹ ọlọ́pàá tó wà ní Iyaganku.
Bákan lọ fikùn pé lọ́nà àti rí dájú pé àlàáfíà túbọ̀ jọba láàárín àwọn tí ọrọ kan, ní òun tún ṣe kọ ìwé ẹ̀sùn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà sáwọn Aláṣẹ tó yẹ, kí wọn leè dasi ọrọ náà ní kíákíá.

Oríṣun àwòrán, Oyo
Folaranmi fikùn pé eekan àwùjọ kan, Oloye Sunday Adeyemo, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ sí Sunday Igboho kò sì lọ́wọ́ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà rárá, lòdì sí ahesọ ọ̀rọ̀ tó gba ilẹ̀ kan.
O wa fewe ọmọ mọ awon èèyàn tó ń sọ ahesọ ọ̀rọ̀ kiri láti má ṣe yí orúkọ Sunday Igboho wọnú rògbòdìyàn náà nítorí ẹni àlàáfíà nii ṣe.
Nígbà tó ń ṣàlàyé ibi tó yẹ kí àwọn ọlọkada maa sanwó oọjọ wọn sì, Folaranmi ni àwọn alákòóso àgbà, táa mọ sí Consultant ńìjọba Ọ̀yọ́ ni kí àwọn máa sanwó fún.
O ni wọn kò fún àwọn láṣẹ láti sanwó fáwọn Alakoso gareji nítorí amojuto ọkọ èrò ni ojúṣe wọn, tí ọ̀rọ̀ àwọn ọlọkada àti onimaruwa kò sì kàn wón.Alaga ẹgbẹ́ ọlọkada nipinlẹ Ọ̀yọ́ fikùn pe ọ̀nà láti wádìí òdodo ọ̀rọ̀ yìí ló mú kí ọga ọlọ́pàá pé kọmisana feto irinna, Ọjọgbọn Raphael Afonja lórí ẹ̀rọ ibaraẹnisọrọ, tí ọrọ onitọun kò sì yàtọ̀ sí ohun tí òun sọ.
Seyi Makinde: Sunday Igboho ní Auxilliary yóò da ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rú mọ́ Seyi Makinde lórí

Èèkàn àwùjọ kan, Oloye Sunday Adeyemo, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ sí Sunday Igboho, tí kesi gomina Seyi Makinde pé kò tètè fà alága àwọn Alakoso gareji ọkọ̀ nipinlẹ Ọ̀yọ́, Alhaji Lamidi Mukaila, tí inagijẹ rẹ ń jé Auxiliary létí, nítorí ìwà ìjẹgàba tó ń hù ní àárín ìlú.
Igboho, ẹni tó gbé ìmọ̀ràn náà kalẹ lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé ládùúgbò rẹ, Soka nílùú Ibadan lọjọbọ tokọjá, tún korò ojú sí Auxiliary, lórí bó ṣe da omi àlàáfíà ìlú rú ládùúgbò Challenge sì Bẹẹrẹ n'ilu Ibadan laipẹ yìí.
Bákan náà lo tún kesi gómìnà àti àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn láwùjọ nipinlẹ Ọ̀yọ́ láti gba Auxiliary nímọ̀ràn pé, kó ti ọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ nítorí bo se n lo ipò agbára tí wọn gbé lé e lọ́wọ́ nilo-kulo, tó si ń lo agbára apàṣẹ wàá láàárín ìlú.
Sunday Igboho wá ṣẹ lórí ahesọ ọ̀rọ̀ kan tó ní àwọn ọmọlẹ́yìn òun kọlu àwọn èèyàn Auxiliary ládùúgbò Soka nílùú Ibadan.Igboho ṣàlàyé pe, kò si ìgbà kankan tí awọn kọlu àwọn ọmọlẹ́yìn Auxiliary nítorí pé òun máa ń figba gbogbo wa ọ̀nà bí omi àlàáfíà ìlú yóò fi toro ni, tí idagbasoke yóò sì bá àwùjọ wa.
Ó mẹ́nu bàa pé Auxiliary gan fúnra rẹ̀ ló wá sí àdúgbò náà, láti wá mojuto bí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe ń ṣe àwọn ọlọkada tí kò sanwó ojúmọ́ bí ọṣẹ ti ń ṣe ojú.
"Ọkọ Jiibu Hilux ni Auxiliary gbé wa sadugbo Soka láti yaju sí àwọn ọlọkada nítorí bí wọn ṣe kùnà láti san owó ojúmọ́ tó yẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ kí wọn máa yọ àwọn ọlọkada náà lẹ́nu nítorí ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ní kí wọn má ṣe san owó náà mọ."Igboho ni Auxiliary kò tíì máa ṣisẹ ti ìjọba gbé lé e lọ́wọ́ bó ṣe yẹ, tó sì ń rọ gomina Seyi Makinde láti yan àwọn èèyàn tó mọ isẹ àkọ́so gareji ọkọ̀ sípò alága tí Auxiliary wà.


















