Abba Kyari: Àwọn ojúṣe olórí àwọn òṣìṣẹ́ fún ààrẹ Nàìjíríà

Abba Kyari

Oríṣun àwòrán, Others

Olori awọn oṣiṣẹ fun Aarẹ Naijiria jẹ alarina laarin aarẹ ati ijọba.

Aarẹ lo si maa n yan ẹni ti yoo ba jẹ olori oṣiṣẹ fun, eyi ti ko nilo ontẹ ilẹ aṣofin. Aarẹ Olusegun Obasanjo lo da ipo naa silẹ lasiko iṣejọba rẹ lọdun 1999.

Eyi si ni akọsilẹ awọn Olori Oṣiṣẹ aarẹ to ti jẹ lati igba naa:

  • Abdullahi Mohammed - Oṣu Karun 1999 si oṣu Kẹfa 2008
  • Gbolade Oṣinowo - Oṣu Kẹfa, 2008 si oṣu Kẹsan, 2008
  • Mike Oghiadomhe - Oṣu Karun 2010 si oṣu Keji 2014
  • Jones Arogbofa - Oṣu Keji 2014 si oṣu Karun 2015
  • Abba Kyari - Oṣu Kẹjọ 2015 si oṣu Kẹrin 2020

Awọn ojuṣe olori awọn oṣiṣẹ fun aarẹ Naijiria

Ojuṣe Olori awọn oṣiṣẹ aarẹ yatọ sira wọn lati iṣejọba kan si omiran. Ko si da lori amuyẹ ẹni ti wọn ba yan nikan, o tun ni i ṣe pẹlu afojusun ilana iṣejọba aarẹ to wa lori oye.

  • Lara awọn ojusẹ rẹ ni yiyan ati amojuto awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ to ṣe koko,
  • ṣiṣe ilana ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ yoo ma gba ṣe iṣl wọn,
  • amojuto bi awọn eniyan ṣe n wọ ile aarẹ, Aso Villa si,
  • amojuto iwọlejade iroyin nileeṣẹ aarẹ
  • mimojuto awọn nkan to le ṣe anfaani tabi pa aarẹ lara,
  • iduna-dura pẹlu ile aṣofin, ati awọn ẹka ileeṣẹ ijọba to kú lati ṣe amulo ilana iṣejọba aarẹ, ati gbigba aarẹ nimọran lori oriṣiriṣi iṣẹlẹ.
  • Oun lo maa n ṣe eto bi iṣẹ aarẹ yoo ṣe lọ lojoojumọ
  • Amojuto ati ṣiṣeto gbogbo ipade ti aarẹ ba fẹ ẹ ṣe, to fi mọ ipade igbimọ alaṣẹ orilẹ-ede Naijiria
  • tun jẹ alarina laarin aarẹ ati olu ileeṣẹ awọn ologun Naijiria
  • Ṣiṣe agbeyẹwo ati atunṣe si ọrọ ti aarẹ ba kọ silẹ lati sọ ni gbangba
  • Ṣiṣe amojuto apo asunwọn owo fun itọju aarẹ, ati fifi ontẹ lu lilo ọkọ ofurufu aarẹ fun awọn oṣiṣẹ ijọba
  • Oun lo maa n fi erongba aarẹ to a
  • Ohun kan to daju ni pe Aarẹ nikan lo le sọ bi ẹni naa yoo ṣe l'agbara to, ati pataki rẹ.

Abba Kyari: Ta a ni yóò rọ́pò Abba Kyari gẹ́gẹ́ bi olórí òṣìṣẹ́ Buhari?

Awọn onwoye nipa eto oṣelu ti bẹrẹ si ni woye ẹni ti yoo rọpo olori oṣiṣẹ Aarẹ Buhari, Abba Kyari to d'oloogbe.

Ọjọ Ẹti ni Kyari d'oloogbe ni ipinlẹ Eko lẹyin ọsẹ diẹ toni aarun coronavirus.

Ọkan pataki ninu ijọba Aarẹ Buhari ni Kyari, ti o si tun jẹ ọrẹ timọtimọ si Aarẹ Buhari.

Onimọ nipa eto oṣelu, Dokita Abubakar Kari sọ wi pe awọn eniyan wa ti yoo rọpọ aye ti Abba Kyari fi silẹ.

Àkọlé fídíò, Ètò ìsìnkú Abba Kyari tako ìlànà ìjìnàsíraẹni lórí ààrùn covid-19- Àwọn ọmọ Nàìjíríà yarí

Lara awọn ti Kari sọ wi pe o le rọpo Kyari ni Asoju ilẹ Naijiria, Babagana Kingibe, Adari ileeṣẹ ẹṣọ ibode lorilẹede Naijiria, Hammed Ali ati Minisita fun eto ẹkọ, Adamu Adamu.

O sọ pe ọrẹ ni Adamu Adamu ati Hammed Ali jẹ si Aarẹ Buhari.

"Ko ni i jẹ iyalẹnu, ti aarẹ ba mu ọkan ninu awọn mejeeji."

O tẹsiwaju lati sọ pe ipo Olori awn oṣiṣẹ fun aarẹ yatọ si ti gomina, nitori naa mi o lero pe Gomina Nasir El-Rufai wa lara awọn ti aarẹ le yan".

Awọn kan ti ẹ n sọ pe boya Minisita fun ọrọ abẹle tẹlẹ, Abdulrahman Dambazau le gba ipo naa, nitori pe o ti n dafun tolo si tipẹ.

Ṣugbọn, onimọ nipa oṣelu naa sọ pe pẹlu bi Buhari ko ṣe pada yan sipo minisita fun igba keji, o ṣeeṣe ko ma yege lati di olori oṣiṣẹ rẹ.

Amin iyasọtọ kan

Babagana Kingibe

Ipinlẹ Borno naa lo ti wa gẹgẹ bi oloogbe Abba Kyari,bẹẹ lo si ti di ipo mu ni awọn ẹka ijọba l'orilẹ-ede Naijiria.

O si tun jẹ ọrẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari, amọ awọn miran bu ẹnu atẹ lu ọna ti o n gba ṣe oṣelu.

Hammed Ali

Oríṣun àwòrán, Hammed Ali

Hammed Ali

Hammed Ali ni Adari ileeṣẹ aṣọbode lorilẹede Naijiria.

Fun ọpọlọpọ ọdun ni o fi wa pẹlu aarẹ Buhari gẹgẹ bi ọmọ ogun Naijiria.

Ohun ti awọn eniyan mọ Hammed Ali si ni pe kii huwa jẹgudujẹra tabi lu owo ilu ni ponpo, ti o si ma n ṣọra ni ọdọ awọn ọrẹ rẹ.

Adamu adamu

Oríṣun àwòrán, Adamu adamu/twitter

Adamu Adamu

Lati ibẹẹrẹ iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari ni ọdun 2015 ni Arakunrin Adamu Adamu ti jẹ minisita fun eto ẹkọ.

Adamu jẹ onkọwe to ti kọ ọpọlọpọ nkan nipa bi o ṣe n lọ l'orilẹ-ede Naijiria.

O jẹ ẹni to ni ọpọlọpọ oye nipa eto oṣelu abẹle Naijiria.

Nasir El-rufia

Oríṣun àwòrán, Kaduna Govt

Nasir El-Rufai

Nasir El-Rufai ni Gomina ipinlẹ Kaduna lọwọlọwọ.

Iroyin sọ pe El-Rufai duna duna fun ipo olori awọn oṣiṣẹ ni ọdun to kọja, amọ ileeṣẹ BBC ko ni ẹri to fi idi iroyin yii mulẹ.

Awọ̣n onwoye so wi pe to ba bọ si ipo naa, yoo ṣeeṣe fun lati dije dupo fun aarẹ orilẹede Naijiria ni ọdun 2023.

Amọ, awọn miran tun woye pe o ṣeeṣe ko ma ri aye fun ati du ipo naa.