Corornavirus: Kini Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti ṣe fun baba tọ ni ọmọ òun ko gbọdọ tèlé oun déle nitori o ṣẹ̀ṣẹ̀ de lati Eko?

Oríṣun àwòrán, Fayemi
Gómìnà ìpínlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ni òun ti yan baba ti fọran rẹ tan ka ori ayelujara lásìkò to n ba ọmọ rẹ jà pe ko le tẹ̀lé òun lọ ile lai ṣe ayẹwò Covid-19 lẹ́yìn to ti irin ajo de lati ìpínẹ̀ Eko gẹ́gẹ́ bi asoj;u ìjọba lori ọ̀rọ̀ Covid-19 nipinlẹ Ekiti.
Gomina fi ọ̀rọ́ yìí léde lorí atẹjísẹ́ twitter rẹ̀ lasàn òní pe inú oun dùn fún igbésẹ ọ̀gbẹ́ni Femi Adeoye pẹlu bi o ṣe ṣe pẹlu ọmọ bíbí rẹ̀ nítori pé o ni igboya, o si nifẹ ìpińll Ekiti lọ́kan.
O ní ọ̀gbẹ́ ni Adeoye yoo ran ìjọba lọ́wọ́ láti maa tan àwọn ipolongo lori ààrun corornavirus, yóò si jẹ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe lori ọ̀rọ̀ coronavirus nípìnlẹ̀ Ekiti
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

O kò leè wọ inú ilé mi lẹ́yìn ìrìnàjò láti Eko, lai ṣe àyẹ̀wò Coronavirus - Bàbá yari fún ọmọ
Coronavirus symptoms vs cold-O kò leè wọ inú ilé mi lẹ́yìn ìrìnàjò láti Eko, lai ṣe àyẹ̀wò Coronavirus - Bàbá yari fún ọmọ

Oríṣun àwòrán, others
Yorùbá ni ọmọ ẹni kii burú títí, ká lè fún ẹkùn pa jẹ àmọ́ èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹlu bàbá kan ni Ondo, tó le ọmọ rẹ síta nítorí ibẹru àrùn Coronavirus.
Bí ere orí itage si ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ri nigbati bàbá kan, Arákùnrin Babafemi, yari kanlẹ pé ọmọ òun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ìlú Èkó de, gbọ́dọ̀ ṣe ayẹwo àrùn Coronavirus, kí òun tó gbà á sínú ilé .
Babafemi, tíì ṣe òṣìṣẹ́ fẹyinti kan nileesẹ àjọ ẹsọ ojú pópó FRSC ṣàlàyé pé, òun ti sọ fún ọmọ òun láti dúró sí Eko, àmọ́ tí kò gbọ .
"Mo ti ní kí ọmọ mi má ṣe wá sí Ado Ekiti àmọ́ kò gbọ ọrọ si mi lẹ́nu. Ní báyìí tó sì ti dé sí Ado, ó gbọ́dọ̀ ṣe ayẹwo àrùn Coronavirus ni, kò to dára pọ mọ wa."

Oríṣun àwòrán, other
Babafemi ni kí òun to gba ọmọ òun sínú ilé, yóò kọ́kọ́ lo ọjọ́ mẹ́rìnlá na ni ibùdó iyasọtọ nítorí òun kò leè fi ẹbí òun sínú ewu àrùn Covid-19.
Baba náà ni ó yẹ kí òun fi ọ̀rọ̀ obìnrin oloyun tó wà sì Èkìtì láti ìlú Èkó ṣe arikọgbọn, ẹni tó ko àrùn Coronavirus wá Ekiti láti Eko.
N30m lawọn to ji Komisana gbe l'Ekiti fẹ gba kí wọn tó tú u sílẹ̀-Mọlẹbi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn to ji Komisana eto ọgbin gbe ni ipinlẹ Ekiti ọgbẹni Folorunsho Olabode gbe ti beere ọgbọn miliọnu naira gẹgẹ bi owo tawọn yoo gba ki wọn to tu silẹ.
Ni irọlẹ ọjọ Aiku lawọn ajinigbe yi da ọkọ rẹ lọna ni opopona Isan Iludun ni Ekiti.
Wọn ji Kọmisana naa ati eeyan kan ti wọn jọ wa ninu ọkọ gbe ti wọn si tun yinbọn pa Kansilọ nijọba ibilẹ Ilejemeje kan ti wọn jọ wa ninu ọkọ naa.
Ninu ohun ta ri gbọ ninu awọn iwe iroyin ilẹ Naijiria,eeyan kan ninu mọlẹbi Kọmisana sọ fun awọn akọroyin ni iAdo Ekiti lọjọ Aje pe awọn ajinigbe naa ti pe awọn lori ago ti wọn si ti beere owo ẹmi ọgbọn miliọnu naira.
Eni ta n wi yi sọ pe ninu ibẹrubojo ni awọn eeyan ilu Kọmisana naa ti se Iye wa ti wọn si n rawọ ẹbẹ si Gomina la ti sa gbogbo agbara lati ri pe wọn doola ẹmi ọmọ awọn.
''A n bẹ Gomina Kayode Fayemi ati awọn agbofinro lati sa gbogbo agbara wọ́n ki wọn ba le doola rẹ''
Ewẹ alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekoto Sunday Abutu to tẹpẹlẹmọ ipinu ajọ naa lati wa Kọmisana naa jade ni awọn ko mọ si owo ẹmi tawọn ajinigbe naa n beere.
''A ko mọ si pe awọn ajinigbe naa n beere owo ki wọn to tusilẹ.Wọn o ti sọ fun wa''
Bakanna ni ọkan lara awọn ọmọ ile asofin nipinlẹ Ekiti ti ni ara ohun ti Coronavirus da silẹ ni ijingbe yi jẹ nitori ohun ni ko jẹ ki wọn se ifilọlẹ ikọ alaabo Amọtẹkun lasiko.
Tope Ogunleye to n soju ẹkun idibo Ilejemeje ni ''inu mi ko dun si gbogbo ohun to n sẹlẹ yi.Awọn ọdaran yi ko sẹsẹ ma sọsẹ laaye ibi ti wọn ti ji Kọmisana gbe.Mo mọ wi pe Gomina Fayemi ko fi ọrọ yi sere rara''
Ogunleye ni nigba ti Covid-19 yoo ba fi kasẹ nilẹ, gomina yoo raaye lati se ifilọlẹ ikọ Amọtẹkun.
O sọ pe awọn eeyan awọn to mọ tibu toro agbegbe naa ni yoo wa nibẹ ti wọn yoo si le awọn ọdaran kuro ni ipinlẹ Ekiti.

- Coronavirus: Àwọn ohun tí a kò tíì mọ̀ nípa àrùn Covid-19
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
- Ṣé òògùn Chloroquine lè dènà ààrùn Coronavirus bí?
- Coronavirus tún ti ṣe ọṣẹ́ lórí iṣẹ́ líla ojú ọ̀nà relùwe láti Eko sí Ibadan - Ìjọba àpapọ̀
- Àrùn Coronavirus fa'lẹ̀ya láwọn ìletò aláwọ̀dúdú ní Amẹ́ríkà

Lagos lockdown: Iná jó dúkìá ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó l'Eko

Ina nla kan tun sọ lọsan oni lagbegbe college Road Road, Abatan Ọgba ni ilu Eko.
Titi di asiko ti a fi n ṣa iroyin yii jọ, ko tii si ẹni lee sọ ohun gan ni pato to fa ijamba ina naa.
Ileepo NNPC to wa ni agbegbe naa ni ina naa ti sọ eyi ti o jo ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye.



- Coronavirus: Àwọn ohun tí a kò tíì mọ̀ nípa àrùn Covid-19
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
- A fẹ́ lo ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn tó ye àrùn Coronavirus láti fi ṣe ìwòsàn fún àwọn tó wà lórí àárẹ- UK
- Coronavirus: Kíni àwọn àmì tuntun tó n fihàn?
- Ọjoọ́ mélòó ni Coronavirus ń lò lára kí ènìyàn tó gba ìwòsàn?




Coronavirus in Nigeria: Nàìjíríà yóò wo tí aráàlú bá bínú lórí àfikún igbele Covid-19 - Dele Momoodu

Oríṣun àwòrán, dele momodu
Gbajumọ akọroyin àti olóṣèlú kan, Dele Momoodu tí woye pe o ṣeé ṣe kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wo, tí àwọn aráàlú bá fi bínú lórí àfikún igbele àrùn Coronavirus.
Dele Momoodu, lásìkò to ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé, kí ìjọba tí àwọn èèyàn mọle kọ ní ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà láti dènà àrùn Coronavirus.
"Tí ẹ bá wo orílẹ̀ èdè Ghana, ó ní ọ̀nà tí ìjọba ń gba láti dènà ifarakinra. Yorùbá si ní ebi kii wọnú, kí ọ̀rọ̀ miran wọ, ebi sì ni ìṣòro ni orílẹ̀ èdè wa".
"Ilẹ̀ Nàìjíríà kii se UK, Amẹ́ríkà àti Faranse. Kò sí oúnjẹ, kò sì iná, ẹ wá fẹ tí àwọn èèyàn mọle, kò leè ṣeé ṣe, èmi kò sì mọ bí ijọba wá ṣe fẹ ṣe. "
Bákan náà ni Dele Momoodu koro ojú sì bí ìjọba ṣe kó owó sórí tabili, tí wọn sì ń pín bíi ìgbà tí wọn ń pín àkàrà, èmi kò sì tíì rí èèyàn tó ní òun ti rí owó náà gbà.
"A ti pariwo títí fún ìjọba, wọn kò gbọ, Nàìjíríà kò sì ní àkọsílẹ̀ gidi. Kí ló dé tí ìjọba kò ṣe lọ nọ́mbà àsùnwọ̀n owó ni banki láti fi pín owó náà àti pé ọna wo ni wọn gba mọ àwọn aláìní."
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí akojọpọ esi tí ileesẹ tó ń gbógun ti àrùn nilẹ yìí, Momoodu ni Naijiria kò ní àkọsílẹ̀ tó dára lórí iye èèyàn tó ní Coronavirus ni Naijiria, bẹ́ẹ̀ sì ni ọpọ àwọn èèyàn tó wà nibẹ lo ń fẹ́ jẹun láti ara àìsàn náà.
Lórí erongba aṣáájú ẹgbẹ́ APC àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Eko tẹ́lẹ̀, Senato Bola Hammed Tinubu láti di aarẹ Naijiria lọ́dún 2023, Momoodu ni lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, Tinubu sì lo kajuẹ julọ láti darí orílẹ̀ èdè yìí.
O ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni Tinubu kò fẹ́ lórí bí àwọn èèyàn ṣe ń pariwo rẹ pé kò wá díje nítorí ó ti ìgbésẹ ọhun bíi ìwà ọyaju sì aarẹ Buhari to wa lori aleefa, nígbà tí kò tíì parí ṣáá isejọba rẹ.

Oríṣun àwòrán, dele momodu
Momoodu ni "Ọpọlọpọ owó tí awọn eniyan kan ní Tinubu kò yìí, kii na fún ara rẹ nìkan nítorí pé ó ní ojú àánú pupọ, tó sì máa ń rán aráàlú lọ́wọ́,koda tipátipá lọ máa ń fi jẹun."
"Bí APC ba fà Olóye Tinubu silẹ láti díje fún ipò Ààrẹ Naijiria, ó dá mi lójú pé, ó tó gbangba sùn lọyẹ, òun ni yóò mókè laarin awọn oludije yòókù nítorí pé ó kúnjú òṣùwọ̀n, tí yóò sì soro kò tó má di aarẹ Nàìjíríà."
Momoodu tún woye pe ìlànà wiwo ọ̀rọ̀ ẹṣin, ẹ̀yà àti owó láti fà oludije kalẹ ni Naijiria kò bójú mú nítorí ẹni tí kò bá ní owó láti pin tàbí jẹ́ ẹlẹ́ṣin tó kàn láti díje, wọn kò ní ṣe atileyin gùn onitohun.
Coronavirus in Nigeria: Àwọn Ìpínlẹ̀ tí coronavirus kò tíì dé ní Nàìjíríà, àti ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé láti dènà rẹ̀

Oríṣun àwòrán, others
Titi di ọjọ Kejila, oṣu Kinni, ọdun 2020, orilẹ-ede China nikan lo tii ni awọn to ni aarun coronavirus.
Sugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ kẹtala, oṣu Kínní, aarun naa ti di ti gbogbo agbaye, nitori pe orilẹ-ede bi Thailand, Japan, South Korea àti America ṣe bẹ̀rẹ̀ si i ni akọsilẹ ti wọn naa.
Lẹyin naa ni aarun naa bẹ̀rẹ̀ si tàn de awọn orilẹ-ede yooku, to fi mọ Africa.
Lọwọ-lọwọ, o ti to miliọnu meji eniyan to ti ni aarun naa.
Itan Iṣẹlẹ COVID 19 ní Naijiria:
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ni Naijiria kọkọ ni akọsilẹ aarun naa, lẹyin ti ọmọ orilẹ-ede Italy kan ni i.Lẹyin naa ni akọsilẹ ẹni keji waye lọjọ kẹsàn-án, oṣu Kẹta. Ọmọ Naijiria ni.Lẹyin eyi ni awọn to ni n pọ si.
Níbo ni ọrọ coronavirus de duro bayii ni Naijiria?
Lọwọ lọwọ, eniyan irinwo ati meje ni ajọ to n dena aarun ni Naijiria, NCDC, sọ pe o ni coronavirus.
Awọn ipinlẹ ti aarun naa ti de ni
Lagos
Abuja
Osun
Edo
Oyo
Bauchi
Akwa Ibom
Kaduna
Ogun
Enugu
Ekiti
Kwara
Rivers
Benue
Ondo
Delta
Katsina
Anambra
Niger
Kano
Apapọ wọn jẹ: mọkandinlogun ati Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.
Àwọn ipinlẹ ti Covid-19 ko ti i de ni NaijiriaBi aarun yii ṣe n tankalẹ to naa ni a ṣi ni awọn ipinlẹ ti ko tii de ni Naijiria.
Ipinlẹ mẹrindinlogun ni coronavirus ko ti i de ni Naijiria naa niwọnyii:.Gombe
Adamawa
Plateau
Borno
Ebonyi
Cross River
Sokoto
Kebbi
Imo
Bayelsa
Taraba
Kogi
Nasarawa
Zamfara
Yobe
Jigawa
Igbesẹ wo ni wọn n gbe lati ri pe ajakalẹ aarun yii ko de ipinlẹ wọn?
Lootọ ni coronavirus ko ti i de awọn ipinlẹ naa, sugbọn lati igba to ti de Naijiria ni diẹ lara wọn ti gbe awọn igbesẹ lati ri i daju pe ko wọ ipinlẹ wọn, àti ọna ti wọn yoo gba koju rẹ to ba ṣèèṣì wọle.
Ipinlẹ Borno gbé igbimọ amusẹya kalẹ lati sisẹ pẹlu awọn ileesẹ aladani, ile ijọsin ati awọn ajọ ti kii se ti jọba lati koju aarun naa, to ba fi le wọ ibẹ.
Lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ipinlẹ Kebbi kede pe ki gbogbo ileewe o wa ni titi pa.Ipinlẹ Ebonyi naa fi ofin de ipejọpọ ọpọ eniyan, lọjọ kẹtalelogun, ọsu kẹta.
Bakan naa ni ipinlẹ Bayelsa ati Imo kede lọjọ kẹrindinlọgbọn pe ki awọn ileewe di titi pa, wọn si tun fi ofin de ipejọpọ ọpọ eniyan to ba le ni àádọ́ta.
Ni ti ipinlẹ Abia, o ti gbogbo ẹnu ibode ipinlẹ naa pa fun ọsẹ mẹrin, o si tun pasẹ pe ki gbogbo araalu o joko sile. Àwọn ile itaja oúnjẹ àti òògùn nìkan ni ofin naa yọ silẹ.
Ijọba ipinlẹ Cross River fi ofin de ipejọpọ nile ijọsin.Kebbi àti Taraba ko ti ẹ gba ki ẹnikẹni wọle si tabi jade kuro ni ipinlẹ naa.
Niṣe lo yẹ ki onikaluku maa fọwọ wọn loorekoore ki wọn si tẹle gbogbo imọran ajọ WHO lori didẹkun itankalẹ ajakalẹ aarun coronavirus laisko yii.
- Èèyàn 16 míràn tún ti ní àrùn Coronavirus ní Naijiria
- Ǹjẹ́ òògùn vitamin C lè pa coronavirus?
- Kí ló mú àwọn aládùúgbò Mọ́ṣáláṣí Alhaja kọlu àwọn ọlọ́ọpàá?
- Kínni ìtàkùn ayélujára 5G nííṣe gan na pẹ̀lú ààrùn coronavirus?
- Coronavirus: Ọmọ márùn ún ni mo ní, ṣùgbọ́n kò sí oúnjẹ fún wa lásìkò ìgbélé yìí -Olùgbé ìlú Eko
''O lè kó coronavirus nípa ṣíṣe eré ìdárayá, ẹ gbélé yín lásìkò yìí,''- onímọ̀ ètò ìlera
Coronavirus in Nigeria: ''Èèyàn lè kó coronavirus nípa ṣíṣe eré ìdárayá, ẹ gbélé yín lásìkò yìí,''
Onimọ nipa eto ilera, Dokita Ikubese Wilson ṣe atupalẹ bi eeya ti le ko aarun coronavirus nipasẹ ṣiṣe ere idaraya.
Ilana ijinasiraẹni jẹ ọkan gboogi lara awọn igbesẹ ti ajọ eto ilera agbaye, WHO gbe kalẹ gẹgẹ bi ara ọna ti a le gba dena itankalẹ aarun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Twitter/globaltimesng
Nitorinaa, ko jẹ iyalẹnu pe ilana ijinasiraẹni yii wa lara awọn igbesẹ ti ijọba lẹkajẹka gbogbo ni orilẹede Naijiria tẹnpẹlẹ mọ julọ gẹgẹ bi ọna lati din ọwọja aarun naa ku nilẹ yii.
Lati fi idi ilana naa mulẹ, awọn ijọba ipinlẹ bii Eko tilẹ fi ofin gbee lẹyin, ofin yii si wa lara eyi ti wọn gbe kalẹ ni ile ẹjọ lati fi gbajugbaja oṣere sinima, Funkẹ Akindele ati ọkọ rẹ j'ofin ni ọjọ Aje.
- Bí mo ṣe ṣẹ́gun Coronavirus rèé - Seyi Makinde
- Coronavirus: Ọmọ márùn ún ni mo ní, ṣùgbọ́n kò sí oúnjẹ fún wa lásìkò ìgbélé yìí -Olùgbé ìlú Eko
- Èèyàn mẹ́fà míràn tún ti ní àrùn Coronavirus ní Naijiria
- Kí ló mú àwọn aládùúgbò Mọ́ṣáláṣí Alhaja kọlu àwọn ọlọ́ọpàá?
- Èyí ni ìdí tí coronavirus ṣe n pa àwọn kan, tí kò sì pa àwọn kan
- Coronavirus- Atọ́nà bí nkàn ṣe ń lọ ní Afirika
Amọṣa, ohun to wa n ṣe ọpọ ni haahinin bayii ni bi awọn eeyan ko ṣe karamasiki ilana yii.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ijọba apapọ paṣẹ konile-o-gbele lawọn ipinlẹ kan bii Eko, Ogun ati Abuja, ohun ti o n farahan bayii paapaa lori ayelujara ni pe ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko fẹ ki jijoko pa sile o sọ awọn di nnkan miran ti wọn si ti bẹrẹ ere idaraya kaakiri lati fi na eegun ati ara wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Amọṣa o, nipasẹ ṣiṣe eyi, ọpọ wọn lo ti n darapọ mọ ibi ti ọpọ ero wa, ti wọn si ti n t'ipasẹ bẹẹ fi ara wọn sinu ewu ati ko arun Coronavirus.
Nibayii ọpọ aworan eyi lo si ti lu ori ayelujara pa.
Ọpọ igba ni igbesẹ ijọba lo ti ba oniruru iha araalu pade.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Arabinrin kan to ni ki a fi orukọ bo oun laṣiri ṣalaye pe ni agbegbe ti oun n gbe ni ilu Eko ni oun ti maa n ṣe ere idaraya lati na eegun ati ara oun.
O ni nigba ti oun yoo fi jade ni ọjọ Aje, 'igboro ti daru' loun lee fi we nitori iye awọn to wa nigboro lati ṣe ere idaraya. O ni eyi lo mu ki oun pinnu lati dawọ duro naa.
Ni aipẹ yii ni awọn olujọsin ni mọṣalaṣi kan ni ilu Eko kọlu awọn oṣiṣẹ ikọ amuṣẹya ti ijọba gbe kalẹ ti wọn wa kan si wọn pe ki wọn pa ofin naa mọ nitori nṣe ni ileejọsin naa kun bamubamu fun awọn to wa kirun.
Njẹ eeyan le ko aarun coronavirus nipa ṣiṣe ere idaraya?
Onimọ nipa eto ilera, Dokita Ikubese Wilson ṣe atupalẹ bi eeya ti le ko aarun coronavirus nipasẹ ṣiṣe ere idaraya.
Dokita Wilson ṣalaye pe o ṣeeṣe ki eeyan ti ipasẹ ere idaraya ko aarun covid-19 nitori sisun mọ ẹni to ni aarun naa lara.
Bakan naa lo sọ pe kokoro aarun covid-19 le wa laaye yala lara ohun elo ere idaraya ti ẹni to ni aarun naa ba ti lo, nitorinaa ''asiko yii ko dara fun ṣiṣe ere idaraya nitori ewu to wa nibẹ pọ.''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Dokita Wilson tun ṣalaye pe ti eeyan ba n ṣe ere idaraya, eemi ẹni naa maa pọ si, bakan naa ni afẹfẹ to n jade lati inu ẹdọ foro naa yoo pọ si.
''Ti ẹni to n ṣe ere idaraya ba mi, eemi naa yoo maa jade leralera, ti ẹni naa ba si ni aarun coronavirus, ẹlomiiran ti wọn jọ n ṣe ere iadaraya le ko aarun naa lara rẹ,'' Dokita Wilson lo woye bẹẹ.
O rọ awọn eeyan lati maa ṣe ere idaraya ninu ile wọn lasiko ti ofin konle-o-gbele wa lode nitori ewu to wa ninu ṣiṣe ere idaraya loju popo tabi ni gbọngan ere idaraya lasiko yii.
O ni fifi ẹmi ẹlomiiran wewu ni ṣiṣe ere idaraya pẹlu awọn mii tumọ sii lasiko yii.

















