Gbogbo ìgbésẹ́ to yẹ ni a gbé kí ató gba ọ̀daràn to ni ààrun Coronavirus sí ọgbà wa- Agbẹnusọ ọgbà ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, others
Ìlé iṣẹ to n moju to ọgba ẹwọn lorilẹ-ede Naijiria ẹka ti ipinlẹ Ondo ní gbogbo ìgbésẹ̀ to yẹ ni àwọn ti gbe ki àwọn afunrasi ninu ikú ọmọ Fasonranti, Funke Olakunrin to de si ọgbà ẹwọn ni Ondo.
Ninu ọrọ rẹ agbẹnujsọ ọgba ẹwọn ipinlẹ Ondo Amofin Babatunde Ogundare, salaye pé ilé iṣẹ́ ọgba ẹwọn gan lo rọ ìjọba ipnilẹ Ondo láti lọ se ayẹwo fun awọn ọdaran naa ni ilana pẹlu ofin ti ajọ naa gbekalẹ láti igba ti aarun Covid-19 ti bẹrẹ
Babatunde ni bi wọn ṣe de ki esi ayẹwo to jade ni wọn ti wa ni aaye ọtọti (isolation Cell) wọn o si darapọ mọ awọn to ti wa lọgba ẹwọn tẹlẹ.
Lẹyin ti esi wa jáde ni ọgba ẹwọn ti fi gbogbo awon to ti ni nkan ṣe pẹlu wọn naa lọ farapamọ fun ọjọ mẹrinla gẹgẹ bi ilana NCDC, ayẹwo wọn si n lọ loorekoore.
O wa salaye pe ijọba ipinlẹ Ondo ati ọgba ẹwọn ti ṣe nkan to tọ, sùgbọ́n igbesẹ ọna ilera ti n lọ lọwọ botilẹ jẹ pe eyi ko ṣee sọ nitori irú ẹsẹ ti wọn ṣe, o si lewu lati sísọ loju eegun ibi ti wọn wa bayii, sugbọn itọju ti n lọ.
Àjọ ọlọpàá ìpínlẹ̀ Ondo kò gbọ́ ǹkankan nípa ọ̀daràn tó ní ààrun Corornavirus
Corornavirus: Àjọ ọlọpàá ìpínlẹ̀ Ondo kò gbọ́ ǹkankan nípa ọ̀daràn tó ní ààrun Corornavirus

Oríṣun àwòrán, others
Lẹ́yìn tí kọmísọ́nà ìlera ìpínlẹ̀ Ondo sọ fún BBC Yorùbaá pé awọn ẹlẹwọn atawọn oṣiṣẹ ọlọpaa ikọ kogberegbe SARS to muu ni wọn ti bẹrẹ si ni mojuto lati mọ boya wọn ti ti ara rẹ ko arun naa.
Àjọ ọlọpàá ni ko tí sí ìwé to fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún àjọ ọlọ́pàá lóri pé óṣeeṣe ki àwọn ọlọpàá kògbérègbè to kọ́kọ́ mú'àwọn ọ̀daràn náà ti tara wọ́n kó ààrùn Corornavirus.
Agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo Tee-Leo Ikoro ní kóda inú ìròyìn ní òun ti n gbọ gbogbo ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sùgbọ́n oun kò kófìrí rẹ láyìká
"Mo kàá nínú ìwé ìwé ìròyìn ni, kò sí ìwé kankan tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni ọfíísì mi"
Bákan náà ni agbẹnusọ ọlọ́pàá náà tún ni, " bi wọ́n ṣe mú, àti ibi ti wọ́n ti mú wọn òn kò mọ̀, bóya àgbẹnusọ ọlọpàá àpapọ̀ lé sàlàyé lórí rẹ̀ nítori àwọn ni wọ́n kéde bí wọ́n ríi àwọn ọdaran náà mú"
Ikoro ní ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo n ṣe gbogbo ǹkan to lè ṣe láti tẹ̀lé ìlànà àti òfin ti ìjọba là sílẹ̀.
Sáájú ni gómìnà ìpińlẹ̀ Ondo Arákùnrin Rotimi Akeredolu ti
Ọwọ́ àwọn alásẹ ọgbà ẹ̀wọn ní ọ̀daràn to ni Corornavirus wà báyìí-Kọmísọ́nà ìlera Ondo
Corornavirus: Ọwọ́ àwọn alásẹ ọgbà ẹ̀wọn ní ọ̀daràn to ni Corornavirus wà báyìí-Kọmísọ́nà ìlera Ondo

Ijọba ipinlẹ Ondo ni ọgba ẹwọn ilu Ọwọ ni afunrasi ọdaran to ni arun Coronavirus ṣi wa.
Ni ọjọ Aiku ni Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu kede faye pe ọkan lara awọn afunrasi ọdaran ti wọn n pe lẹjọ lori iku ọmọbiinrin aṣiwaju ẹgbẹ Afẹnifẹre, ...ti lu arun naa.
Kọmiṣọna feto ilera ni ipinlẹ Ondo, Dokita Wahab Adegbenro lo ṣalaye ọ̀rọ̀ yii lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ.
Dokita Adegbenro ni awọn ti ni ki awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria o mojuto ẹlẹwọn naa funrawọn.
O ni ko si idi meji ju wi pe ijọba ipinlẹ Ondo ko fẹ ohun ti yoo fa hilahilo tabi wahala ba aabo awọn alaisan yooku atawọn oṣiṣẹ to n mojuto wọn.
"Ẹ mọ wi pe o ṣeeṣe ko ni awọn ẹgbẹ ọdaran tirẹ to si lee fẹ mu ki wọn wa dojukọ abo lawọn ileewosan wa paapaa julọ awọn oṣiṣẹ wa."
O ni gbogbo awọn ẹlẹwọn atawọn oṣiṣẹ ọlọpaa ikọ kogberegbe SARS to muu ni wọn ti bẹrẹ si ni mojuto lati mọ boya wọn ti ti ara rẹ ko arun naa.
Ọ̀kan nínú àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú ọmọ Fasoranti ni Corornavirus

Lánàá òde yìí ni ìròyìn tàn pé àwọn afurasí ti ọlọpàá mú nítori wọ́n ni ọwọ́ nínú ikú tó pa ọmọbìnrin Fasoranti ni wọn ti ṣe àyẹwò ààrun Corornavirus fún nígbà tí wọ́n sí n réti àsìkò tí ìgbẹ́jọ́ wọ́n yóò jẹ́
Èsì àyẹwò tó jáde fi yéni pé àwọn ènìyàn mẹ́ta to tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ni ààrùn Coronavirus ni ìpínlẹ̀ Ondo jẹ ọ̀kan nínú àwọn afurasíu yìí.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo Rotimi Akeredolu ló fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lórí àtẹ́jíṣẹ́ rẹ̀
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ó ní ìjọba ti fi ọ̀rọ̀ yìí tó kọmísọ́nà ọlọpàá ní ìpínlẹ̀ Ondo léti, láti le wá àwọn ọlọpàá àtí àwọn SARS ti ó wà ni ìkáwọ́ wọ́n nágbà ti wọ́n ṣe àyẹ̀wò wọ́n
Adájọ́ pàṣẹ pé kí wọ́n o fi àwọn afurasí tó pa ọmọ Fasoranti sí ọgbà ẹ̀wọ̀n
Fasoranti's Daughter: Ilé ẹjọ́ ti sún ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí tó pa ọmọ Fasoranti sííwájú

Ile ẹjọ ti sun igbẹjọ awọn afurasi mẹẹrin tileṣẹ ọlọpaa fi ẹsun kan pe wọn lọwọ si iku ọmọ Reuben Fasoranti.
Owurọ ọjọ Ẹti ni igbẹjọ kọkọ waye lori awọn afurasi naa nile ẹjọ Majisireeti to wa nilu Akurẹ.
Awọn afurasi naa ni Masagi Lawal, Muhammed Usman, Adamu Adamu, ati Abubakar Hawawu.

Ẹsun ipaniyan, idaluru ati ijinigbe ni wọn fi kan wọn.
Oṣu Keje, ọdun 2019 ni awọn agbebọn ṣekupa Funke Olakunrin nipinlẹ Ondo.
- ''Ìséde káàkiri Nàìjíríà lọ̀nà àbayọ sí ìtànkálẹ̀ coronavirus, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àpá kò ní ká covid-19 mọ́''- Onímọ̀
- Ikú Dagrin pé ọdún mẹ́wàá, wo àwọn nǹkan mánigbàgbé nípa rẹ̀
- Nàìjíríà tún ní àkọsílẹ̀ ènìyàn 108 tó ní ààrùn coronavirus
- Wo àwọn nkan tí o le ṣe gẹ́gẹ́ bi aláboyún lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19
- ‘Pussypedia’ rèé, ojú òpó tó ń mú àdínkù bá ìṣòro ìmọ̀ nípa ẹ̀yà ara obìnrin
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2020 si ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe, ọwọ titẹ afurasi mẹẹrin lori ipaniyan naa.
Bakan naa ni awọn ẹbi oloogbe naa ti wa nile ẹjọ.

Botilẹjẹ pe agbẹjọro awọn afurasi naa ko yọju sile ẹjọ, Onidajọ Bob Manuel bẹrẹ igbẹjọ naa.
Ẹya Hausa ati Fulani ni awọn afurasi naa, gbogbo wọn lo si sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Nibayii, adajọ ti paṣẹ pe ki wọn o fi wọn pamọ si ọgba ẹwọn to wa ni ilu Ọwọ nipinlẹ Ondo titi di ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2020, ti igbẹjọ yoo tẹsiwaju.














