Pussypedia: Ṣé gbogbo obìnrin ló ń damira lójú ara lásìkò tó bá fẹ́ rí ọkùnrin?

Obinrin to la idi silẹ

Oríṣun àwòrán, María Conejo/BBC

Ti a ba n sọrọ nipa isẹda obinrin, a kii fẹ fi gbogbo ẹnu sọrọ nipa rẹ, nitori bi Ọba oke se obinrin ni ohun ọwọ ati ẹlẹgẹ.

Boya eyi si lo faa, ti awọn ohun to jọ mọ imọ ijinlẹ nipa isẹda ẹya ara obinrin ko se fi bẹẹ wọps lori itakun agbaye.

Ni ọpọ igba lawọn obinrin ti n se awawi pe awọn kii ri imọ nipa ohun to jẹ mọ oju ara wọn, to si jẹ pe ti wsn ba lọ sori ayelujara lati se awari imọ nipa oju ara wọn, 'iregbe' ni wọn sọ pe awọn maa n ri nibẹ.

Nigba to n ba BBC sọrọ, obinrin kan, Zoe salaye pe "nigba ti mo beere lọwọ Google pe se obinrin maa n da omira loju ara lasiko ti ara rẹ ba n poungbẹ lati ri ọkunrin (Ejaculation), gbogbo ohun to fi da mi lohun ni ko ye mi, koda, n ko mo itumọ awọn ede to fi n ba mi sọrọ abi ẹya ara to n mẹnuba."

O fikun un pe bi aye ti laju to yii, a si n gbe ni awujọ ti aibara dọgba laarin akọ ati abo ti n waye, ti ojuti si maa n wa fawọn obinrin ta ba n sọrọ ẹya ara ati isẹda wọn.

Obinrin to n bọ pata

Oríṣun àwòrán, María Conejo/BBC

Nitori awọn idiwọ yii lo wa mu ki Zoe ati Maria sefilọlẹ oju opo kan lori itakun agbaye losu keje ọdun 2019, eyi ti wọn pe ni 'Pussypedia', awọn eeyan to to ẹgbẹrun lọna aadoje si lo ti n bẹ oju opo naa wo lati wa imọ kun imọ wọn nipa ẹya ara obinrin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn imọ to n dahun si ọpọ ibeere awọn obinrin ni bi wọn se lee fọ oju ara wọn, titi de awọn ọna ti kokoro aifojuri lee gba sediwọ fun oyun nini ati ọmọ bibi.

Sugbọn bi awọn mejeeji se n gbiyanju pe ki oju opo naa pese ọpọ idahun fun awọn to n wa imọ, sibẹ, o dabi ẹni pe awọn ibeere kan si wa to nira lati wa idahun si loju opo naa.

Aworan idi obinrin

Oríṣun àwòrán, María Conejo/BBC

Idi ni pe ko fi bẹẹ si iroyin to fidi mulẹ nipa ẹya ara obinrin gẹgẹ bo se wa fawọn ọkunrin, bẹẹ si ni akọsilẹ awọn onimọ ijinlẹ nipa isẹda abo gan maa n tako ara wọn nigba miran, eyi ti ko see tẹle.

Zoe ni "Fun apẹẹrẹ, ti ẹ ba n wa ọrọ yii 'Penis' tii se ẹya ara ọkunrin, orisirisi imọ lẹ ri nipa rẹ amọ eyi ko ni ri bẹẹ, tẹ ba beere fun 'Vagina', tii se ẹya ara obinrin."

Zoe ati Maria si ti n saayan siwaju lati se afikun imọ loju opo Pussypedia, ko lee wa ojutu si isoro ti awọn obinrin n koju lati ni imọ nipa ẹya ara wọn atawsn ohun to rọ mọ.