Eletricity Tarriff: IKEDC ní sísan owó iná ọba tayọ èèyàn yókù kò lòdì sófin

Osisẹ amunawa to wa lori opo

Oríṣun àwòrán, Instagram/ikejaelectric

Bi wọn ba ni ko san owo ina ọba to le si eyi to n san lati le gbadun ina ọba, bi elo lo lero pe o le san?

Njẹ o si tọ ki awọn kan ma gbadun ina ọba nitori pe wọn ni agbara lati san owo ina ọba ju awọn akẹgbẹ wọn lọ?

Eyi lawọn ibeere to jẹ yọ lẹyin ti ileeṣẹ ajọ to n pin ina ọba nipinlẹ Eko, Eko Electricity Distribution Company, buwọlu iwe adehun kan pẹlu awọn olugbe kan lagbegbe Magodo Estate.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adehun naa lo fun wọn ni anfaani lati maa san owo to pọ ju eyi to yẹ lọ, to si lowura ju tawọn ẹgbẹ wọn lọ, ki wọn lee maa ri ina ọba lo laisẹju.

Lai dena pẹnu, awọn eeyan kan ni Magodo Estate ti n gbadun ina ọba fun bi ogun wakati lojumọ tori pe, wọn buwọlu adehun ti wọn pe orukọ rẹ ni Premium Power Deal, pẹlu ajọ amunawa yii.

Aworan opo ina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu ifọrọwanilẹnuwo BBC Yoruba pẹlu agbẹnusọ ileeṣẹ amunawa IKEDC, Felix Ofulue, o ṣalaye pe akanṣe eto adehun tawọn ni pẹlu awọn ara adugbo Magodo, lo mu igbadun ina ọba yi bawọn.

Felix Ofulue ko sọ pato iye kan pato ti awọn onibara wọn pataki yii n san, amọ o ni awọn fi owo le iye owo ti wọn n san lori lilo ina, ti eleyi si wa ni ibamu pẹlu ofin lilo ina ni Naijiria.

Ofulue fikun pe ''Lati nnkan bi ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2019, lawọn eeyan Magodo ti n gbadun ina wakati mẹrinlelogun lojumọ.

Awọn to n kawe ninu okunkun pẹlu abẹla

Oríṣun àwòrán, @EKEDP

A ṣe agbekalẹ ina ọba to yatọ fun wọn ni. Bi ẹnikẹni ba fẹ jẹ iru anfaani yii naa, a ṣetan lati ṣe bẹẹ ti gbogbo eto ati adehun laarin wa ba ti wa ni ṣẹpẹ"

Kini kawọn ti ko ni owo wa ṣe bayi?

Kola Olubiyo to jẹ oludari ajọ to n ja fun ẹtọ araalu lẹka ohun amuṣagbara woye si ọrọ yii, to si ni labẹ ofin karakata ina ọba, ko si ohun to buru ninu iru adehun bẹẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, o ni ọrọ naa dabi ka ni ọlọja gbe ọja silẹ, to si n wa awọn ti yoo ra lowo to peye ni.

''Ofin gbawọn laaye lori igbesẹ yii ati pe, awọn ileeṣẹ to n pese ina ọba ti ṣadehun pẹlu ijọba lati ma san owo ina ọba ti ijọba n pese, ko si le pe wọn ti wọn ko ba ri ọja wọn ta loju owo ti wọn fi ra''

Ẹrọ amunawa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pupọ eeyan lo n lo ẹrọ amunawa lati pese ina fun ara wọn ni Naijiria

Olubiyo ni kii ṣe gbogbo eeyan lo le ma fara da aiṣedeede ina ọba paapa julọ, awọn to ba ni ile iṣẹ to n mu owo wa lojumọ.

O ni iru adehun yii jẹ ọna abayọ, amọ o ku ki ijọba gbe igbesẹ lati ri pe awọn mẹkunnu ko farakasa eto yii, tori pe wọn lee ma lowo lati san bii awọn olowo.

Abẹla to n tan ninu okunkun

Oríṣun àwòrán, @EKEDP

''Ijọba ni lati mu atunto ba ẹka ina ọba ki awọn ara ilu baa le jẹ mudunmudun eto ijọba awarawa. Bi awọn olowo ba le san owo nla, ki wọn fi le ri ina ọba lo, ki ni ki awọn mẹkunnu ṣe?''

Olubiyo tun rọ ijọba lati yẹ ọrọ naa wo daada, ki o to kọja afẹnusọ.