Ìròyìn ni mo lọ kọ, kí ọlọ́pàá tó ta mí níbọn - Toba Adedeji
Ori lo ko akọroyin kan, Toba Adedeji yọ lọwọ iku ojiji lasiko ti awọn ọlọpaa kan yinbọn mọ lẹsẹ nibi iwọde kan to waye ni ikorita Olaiya nilu Osogbo, nipinlẹ Osun. Nigba to n ba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ lori bi isẹlẹ naa se waye, Toba ni awọn akẹkọ kan lo n se iwọde lori bi osisẹ ọlọpa kan se pa ọrẹ awọn, ti awọn si ti lọ sin nilu Ilesa.
Bawo ni isẹlẹ naa se waye: Osisẹ Akọroyin naa ni oun ati awọn akẹẹgbẹ oun lawọn dijọ lọ sibi iwọde naa lati kọ isẹlẹ to waye nibẹ silẹ lai gbe ohun ija oloro kankan lọwọ. O fikun pe awọn akẹkọ to n se iwọde naa ko pe ogun niye, ti awọn si n duro ki wọn pọ diẹ si kawọn to maa ka aworan wọn silẹ amọ ko pẹ ni awọn osisẹ ọlọpa kan de pẹlu ọkọ Korope. "Ni kete tawọn osisẹ ọlọpaa naa, to wọ ẹwu ayẹta de sibi isẹlẹ naa ni awọn akẹkọ naa ti fẹsẹ fẹ amọ awa akọroyin lo ku nilẹ, ti awọn ọlọpaa si doju ibọn kọ wa. Wọn ta mi nibọn lẹsẹ, ti emi naa si se yẹnku yẹnku sare kuro nibẹ ki wn to gbe mi lọ sile iwosan. Ọna meje ni awọn dokita ti ran ẹsẹ mi nitori ọtan ibọn ti bu ẹran ara mi jade, ti n ko si ti le rin daadaa latri igba naa.
Ki ni ileesẹ ọlọpaa sọ nipa isẹlẹ naa: Lẹyin ti ariwo gbode kan pe awọn ọlọpaa ti ta akọroyin kan nibọn, ni ileesẹ ọlọpaa fi atẹjade kan sita pe ara akọroyin ti ibọn ba ti n ya, ti wọn si sekilọ llori pinpin iroyin eke kiri eyi ti wọn lo ni ijiya labẹ ofin. Ẹgbẹ Akọroyin nipinlẹ Osun fariga lori bi awọn ọlọpa se yinbọn mọ ọmọ ẹgbẹ wọn: Nigba ti wọn n ba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ, alaga ẹgbẹ akọroyin nipinlẹ Osun, Wasiu Ajadosu ati akọwe rẹ, Sina Abubakar ni awọn n fẹ ki ọga agba ọlọpaa nilẹ wa tete wa gbe Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Osun kuro nipinlẹ naa nitori awọn ko le ba sisẹ papọ mọ. NUJ Osun ni ajọsepọ to yẹ ko wa laarin awọn akọroyin ati ileesẹ ọlọpaa ti mẹhẹ, ọfọn si ti tọ si gbẹgiri, ẹlẹkọ ti ko ẹkọ rẹ lọwọ. Bakan naa ni wọn n rọ ileesẹ ọlọpaa lati kede bi isẹlẹ naa se waye fun araye, ko si fi oju ọlọpa to yinbọn mọ akọroyin naa han, ki wọn si tọrọ aforijin pẹlu.









