Ẹ̀bẹ̀ Tinubu lórí títàbùkù Buhari kò tó, APC sì le fìyà jẹ́ lórí ohun tó sọ - Alaga APC

Alaga ẹgbẹ oselu APC nil.ẹ wa, Abdullahi Adamu

Oríṣun àwòrán, APC

Awọn asaaju ẹgbẹ oselu APC nilẹ Naijiria ti wo sakun awọn ọrọ ti asaaju ẹgbẹ oselu naa ati oludije fun ipo aarẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu sọ si aarẹ Muhammadu Buhari.

Nigba to n woye lori awọn ọrọ ti Tinubu sọ nipa Buhari naa, alaga ẹgbẹ APC, Sẹnetọ Abdullahi Adamu sisọ loru rẹ pe o si seese ki ẹgbẹ naa fi iya jẹ Tinubu lori ọrọ to sọ si aarẹ.

Adamu, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ ni olu ile ẹgbẹ oselu APC nilu Abuja lọjọ Satide ni awijare Tinubu lori isẹlẹ le ma tan sibẹ, ki ẹgbẹ APC si tun gbe awọn igbesẹ miran lori rẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, Asiwaju Tinubu lo salaye nilu Abeokuta nipinlẹ Ogun lasiko abẹwo rẹ lọjọbọ pe oun ni alatilẹyin gboogi si aarẹ Buhari to fi wọle ibo.

Amọ Tinubu ti wa fi atẹjade kan sita lẹyin abẹwo naa lati wi awijare rẹ lori awọn ọrọ to sọ eyi to n fa awuyewuye lori ayelujara ati yika Naijiria.

Sugbọn alaga ẹgbẹ oselu APC naa ni bi Asiwaju se tọrọ aforiji lori ọrọ rẹ naa ko tii to, o si tun seese ki ẹgbẹ oselu APC fiya jẹ lori awọn ọrọ naa.