Ẹ foríkorí, ẹ fẹnukò lórí ẹnìkan ṣaájú ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ – Ààrẹ Buhari sí àwọn olùdíje APC

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti gba àwọn olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC lámọ̀ràn láti foríkorí, kí wọ́n fikùnlukùn láti mú ẹnìkan láàárín wọn tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ láti dupò lọ́dùn 2023.
Ní álẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹfa ọdún 2022 ni Ààrẹ Buhari ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC .
Ààrẹ Buhari ní ìfẹnukò wọn nìkan ló le mú ẹgbẹ́ àwọn ṣe àṣeyorí níbi ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023.
Bákan náà ló ni ìpàdé náà wáyé ní ìtẹ̀síwájú ìfukùlukùn àwọn láti ri dájú pé ẹni tó gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gbàwo bọ̀ ní àwọn yan sípò gẹ́gẹ́ bí olórí.
Bẹ́ẹ̀ náà ló yin gbogbo àwọn olùdíje lákin ìgboyà àti ẹ̀mí ìfarajìn tí wọ́n ní láti sin orílẹ̀ èdè baba wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gbèrò láti ṣe Ààrẹ Nàìjíríà.
Ó fi kun pé wíwá ní ìṣọ̀kan àti pé ìmọ̀ àti èrò àwọn ṣọ̀kan ló jẹ́ kí àwọn jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ọdún 2015 àti 2019.
Ó ní ní àwọn àsìkò náà ìfẹ́ ìlú àti ti ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn ló múmú ní óókan àyà gbogbo olùdíje tí àwọn sì foríkorí láti pinu lórí ẹnìkan, ó ní èyí ni òun fẹ́ kí wọ́n tún ṣe ní àsìkò yìí.
Buhari tẹ̀síwájí pé bí ètò ìdìbò ọdún 2019 ṣe ń súnmọ́ etílé, ẹgbẹ́ APC gbọdọ̀ kọbi ara sí gbogbo àwọn àyípadà tó ti wáyé nínú ìlú, tẹ́tí sí gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn ń fẹ́, tú ara mú kí wọ́n sì di ara wọn ní òṣùṣù ọwọ̀.
Ó ní gbogbo àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní òun ti kọ́kọ́ bá ṣe ìpàdé tí òun sì sọ fún wọn wí pé ẹni tí àwọn ènìyàn Nàìjíríà yóò ní ìgbẹkẹ̀lé nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ tí yóò sì mú kí ẹgbẹ́ àwọn jáwé olúborí lásìkò ìbò.
Ààrẹ ní òun kò ní dẹ́kun ṣíṣe irú àwọn ìpàdé báyìí títí àwọn yóò fi parí gbogbo ètò ìbò náà.












