Seyi Makinde tara-pòrò lórí ìkọlù Owo, ó ké sáwọn tọ́rọ̀ ààbò kàn láti yé fọ́wọ́ lẹ́rán lórí ìkọlù agbébọn

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde náà ti ṣe àbẹ̀wò sí ìlú Owo láti bá àwọn ènìyàn ìlú náà kẹ́dùn lórí ìkọlù tí àwọn agbébọn ṣe tí ilé ìjọsìn St Francis Owaluwa, ìjọba ìbílẹ̀ Owo, ìpínlẹ̀ Ondo.
Makinde tó bá ìjọba àti gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ondo kẹ́dùn lórí ìkọlù náà ní ìjọba gbọ́dọ̀ ri dájú pé wọ́n ṣe ohun gbogbo tó yẹ láti dènà irú ìṣẹ̀lẹ̀ ní ọjọ́ iwájú.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ gómìnà Seyi Makinde, Taiwo Adisa ní gómìnà Rotimi Akeredolu àti Mínísítà fọ́rọ̀ abélé, Rauf Aregbesola ló gba Makinde ní àlejò ní ilé ìjọsìn tí àwọn agbébọn ṣe ìkọlù náà sí.
- Àwọn gómìnà APC dín olùdíje ààrẹ ku sí 5 kí ìdìbò tó bẹ̀rẹ̀
- Òní lòní ń jẹ́, bí ìpalẹ̀mọ́ fún ìbò abẹ́nú APC láti yan olùdíje Ààrẹ ṣe ń lọ rèé
- Tinubu, ewu ń bẹ níwájú, ṣọ́ra ko má jìn sí ọ̀fìn tí Abiola, Awolowo jìn sí - Fayose
- Ohun tí mo rí, ẹ̀yin kò ri ní mo ṣe di èèyàn burúkú lójú àwọn olóṣèlú - Sunday Igboho
Makinde nígbà tó ń bá àwọn ènìyàn tó farapa níbi ìkọlù náà sọ̀rọ̀ ní ilé ìwòsàn Federal Medical Centre, Owo níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú ní ìwà ìgbáṣùmọ̀mí gbọ́dọ̀ jẹ ohun ìtàn ní Nàìjíríà.

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó banilọ́kàn jẹ́ gidi ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti wí pé kò sí ìyàtọ̀ nínú ìkọlù tó wáyé ní Igangan ní ọdún kan sẹ́yìn àti èyí tó wáyé ní ọjọ́ Àìkú yìí.
Bákan náà ló rọ gbogbo àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ láti yé fọwọ́ lẹ́ràn lórí àwọn ìkọlù aburú tó ń fi ojoojúmọ́ wáyé ni Nàìjíríà.
Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wu òun láti sọ wí pé ẹ̀yà kan ni ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ń ṣẹlẹ̀ sí jùlọ, òun ní ìgbàgbọ́ náà ni kò ní fẹ́ràn kí irú ìkọlù bẹ́ẹ̀ máa wáyé sí àwọn.
Ó ní gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò gbọ́dọ̀ jí gìrì sí ojúṣe wọn, kí wọ́n ri dájú pé àwọn nawọ́ gán àwọn oníṣẹ́ láabi yìí, kí wọ́n sì fi wọ́n jófin.
Ṣáájú Makinde ti fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ráńṣẹ́ sí gómìnà Rotimi Akeredolu ní ọjọ́ Àìkú tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kọ́kọ́ wáyé.
Gómìnà náà gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ́ àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà sí afẹfẹ rere kó sì rọ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn lójú

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti kéde rẹ̀ wí pé ohun tó wà ní àkọọ́lẹ̀ lórí yíyan Aláàfin ìlú Oyo ní ìjọba yóò tẹ̀lé láti fi yan Aláàfin tuntun.
Makinde sọ èyí ní ìlú Oyo nbí ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹfà ọdún 2022 níbi ayẹyẹ ìkẹyìn fún Aláàfin Oyo àná, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta.
Ní ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2022 ni Ọba Adeyemi lọ darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀ lẹ́ni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin.
Ọdún méjìléláàdọ́ta ní Ọba Adeyemi Kẹta lò lórí àpèrè àwọn babańlá rẹ̀. Òun sì ni Aláàfin tó pẹ́ lórí ipò náà jùlọ
Gómìnà Makinde ní Aláàfin tó gbésẹ̀ náà gbé ìgbá ayé tó ṣe é mú yangàn àti pé Ọba ńlá tó mọ tìfun tẹ̀dọ̀ àṣà àti ìṣẹ̀ṣe Yorùbá ni ìlú Oyo pàdánù.
Báwo ní wọ́n yó ṣe yan Aláàfin tuntun?
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí ìjọba yóó ṣe yan Aláàfin tuntun, Makinde ní àwọn kò ní tàpá sí àkọsílẹ̀ tó ti wà nílẹ̀ lórí bí ipò Aláàfin ṣe máa ń jẹ́ jíjẹ.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ti wá ń bá òun wí pé ọmọ mẹ́tàlá ní Aláàfin àkọ́kọ́ bí àmọ́ àwọn ìran méjì péré ló ti ń jẹ Aláàfin lọ́jọ́ pípẹ́, pé àǹfàní rèé láti fa àwọn yóòkù wọ́lé.
“Ohun tí mo máa ń bèrè lọ́wọ́ wọn ní pé ṣe ó wà ní àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n èsì tí wọ́n ń fún mi ni pé ó wà ní àkọsílẹ̀ kan tí wọn kò buwọ́lù.”
“Mo sì fún wọn lésì pé ohun tó bá wà ní àkọsílẹ̀ èyí tí wọ́n buwọ́lù nìkan ni a máa tẹ̀lé láti yan Aláàfin tuntun.”
















