Ayẹ́yẹ́ ìkẹ̀hìn fún Alaafin Oba Lamidi Adeyemi bẹ̀rẹ̀ ní Oyo, bó ṣe ń lọ rèé

Awọn eekan ti peju pesẹ sibi ayẹyẹ ikẹhin fun Alaafin ti ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi.
Eyi ni ayajo ayẹyẹ ogójì ọjọ leyin iku kabiyesi iku baba yeye Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi III n waye lóni ní ilu Oyo.
Awọn eeyan ti pọ nibi ayẹyẹ naa lati kaakiri orilẹede Naijiria si ni wọn ti wa.


Ayeye ogoji ọjọ naa n waye ni gbàgede ile iwe Olivet ni ilu oyo. Kabiyesi eku baba yeye dara pọ̀ mọ́ àwọn baba ńlá rẹ̀’ nígbà tó pé ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83], lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méjìléláàádọ́ta [52] tó ti wà lórí ìtẹ́ – àti gẹ́gẹ́ bí Alaafin tó ti pẹ́ jù lọ.

Aworan awọn lọbalọba ati eekan ilu to ti wa nibẹ ree
















