Ẹ wo bí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò pápákọ̀ òfúrufú Akure ṣe lu ọkọ mi tí ẹ̀jẹ̀ bò ó – Arábìnrin ké gbajarè lórí Twitter

Obinrin ti wọn lu ọkọ rẹ ni Papakọ ofurufu

Arabinrin kan ti sọ iriri bi awọn ẹṣọ agbofinro ni papakọ ofurufu Akure, ni ipinlẹ Ondo ṣe fi iya jẹ ọkọ oun, ti wọn si lu jatijati.

Arabinrin naa pẹlu orukọ @tAtolani8 lori Twitter sọ iriri rẹ ni Ọgbọnjọ, Oṣu Karun un, ọdun 2022.

O ni ọkọ ofurufu Eko si Akure ni oun wọ ni ọjọ naa ti ọkọ rẹ si ti n duro de lati gbe kuro ni papakọ ofurufu naa.

O wa ọkọ rẹ gunlẹ ni ibi ti wọn n wa ọkọ gunlẹ si, amọ ni igba ti wọn ma fi pada de ibẹ, wọn ti ba ‘chain’ ni ẹsẹ mọto naa.

O beere fun awọn to wa ni idi siso ọkọ rẹ mọlẹ, ki oun le san owo itanran ki oun si kuro nibẹ.

‘’Ọkọ mi lo ba awọn ẹṣọ alaabo to wa nibẹ, amọ ko si ẹnikẹni to fun ni esi, ti wọn si n fi ṣe yẹyẹ.’’

Papakọ ofurufu Akure

‘’Lẹyin naa ni ọkọ mi yọ ‘’chain’’ ara ọkọ rẹ, to si ripe wọn ko de mọlẹ rara amọ bi o ṣe fẹ jade ni gbogbo awọn ẹṣọ agbofinro naa jade.’’

‘’Wọn pe awọn to wa ni ẹnu ọna, ti wọn si kesi wa lati pada lọ san owo itanran naa.’’

Ọkọ mi pada lati lọ san owo naa amọ ni ṣe ni wọn bẹrẹ si ni sọ ọrọ odi si niwaju mi. Ọkan lara wọn tilẹ sọ pe ko ni ẹkọ, ti ọkọ mi si sọ wi pe wọn ko lẹtọ lati sọ iru ọrọ naa si oun.’

Lẹyin naa ni wọn gbe igbesẹ lati de mọ ‘guard room’ wọn amọ o kọ, ti wọn si bẹrẹ si ni naa pẹlu igi, irin ati ohun to le se eniyan leṣe.

Arabinrin naa fi fidio si ori Twitter nibi ti ẹjẹ ti n san ni ori ọkọ rẹ, ti o si n bẹbẹ pe ki wọn jẹ ki oun ma lọ, sẹ wọn fẹ pa oun si ibi bayii ni.

Iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa – FAAN

Ileeṣẹ to n risi ọrọ ofurufu lorilẹede Naijiria ti fesi si iṣẹlẹ naa.

Loju opo Twitter ni wọn ti ni ki obinrin naa ma binu, pẹlu adehun wipe awọn yoo ṣewadii iṣẹlẹ naa.