Ẹ yọwọ́ Tinubu kúrò láwo ìdìbò abẹ́nú APC - Ẹgbẹ́ Gaskiya Youth Movement sọ fún ilé ẹjọ́

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress kan lábẹ́ ìdarí ẹgbẹ́ tí wọ́n pè ní Gaskiya Youth Movement ti wọ́ gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Eko, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lọ sí ilé ẹjọ́.

Ohun tí wọ́n ń bèrè fún ni pé kí ilé ẹjọ́ yọ ọwọ́ Tinubu kúrò láwo níbi ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú náà tí yóò wáyé ní ọjọ́ kẹfà sí ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹfà ọdún 2022.

Bákna náà ni wọ́n pe ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC náà lẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ Tinubu.

Kí ni wọ́n ní Tinubu ṣe?

Lára ohun tí ẹgbẹ́ ṣe wọ́ Tinubu lọ sí ilé ẹjọ́ pé kí ilé ẹjọ́ dájọ́ pé kò lè kópa nínú ètò ìdìbò abẹ́nú náà kò ṣẹ́yìn àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó rọ̀ mọ́ ọjọ́ orí àti ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Tinubu.

Wọ́n ní kí ilé ẹjọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyà Tinubu lé díje sípò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tàbí ẹgbẹ́ mìíràn.

Wọ́n ní kí ilé ẹjọ́ kéde pé òfin kò fi àyè gba Tinubu láti díje sípò Ààrẹ Nàìjíríà nínú ẹgbẹ́ òṣ]elú APC tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn.

Ọ̀kan pàtàkì ní Tinubu jẹ́ nínú àwọn olùdíje sípò Ààrẹ tó ń léwájú nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress.

Ó ti ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Eko fún ọdún mẹ́jọ láàárín ọdún 1999 sí 2007.

Ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn tó dá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress,APC sílẹ̀, òun sì ni adarí àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà.