Iléẹjó ti fi ọkọ Osinachi olórin sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje Prison

Oríṣun àwòrán, Facebook/Osinachi
Ileẹjọ giga ni ilu Abuja ti ni ki wọn ti Peter Nwachukwu, ọkọ olorin to doloogbe Osinachi si ẹwọn Kuje Correctional Facility, titi di igba ti igbẹjọ ipaniyan ti wọn fi kan an yoo bẹrẹ.
Adajọ Agba, N.K Nwosu lo paṣẹ naa lẹyin ti ọkọ POsinachi ni oun ko jẹbi ẹsun onigun mẹtalelogun ti wọn fi kan oun, lori ẹsun iwa ipa ati ipaniyan ti ijọba fi kan an.
Ileeṣẹ adajọ agba lorilẹede Naijiria ati Minisita fun ọrọ idajọ lo fi ẹsun naa kan Peter, o fi tipatipa le Osinachi kuro ninu ile rẹ, eleyii to tako ofin Naijiria lori lilo ipa si eniyan, Violence Against Persons, VAP (Prohibition) Act, 2015.
O tun fikun pe o tun ti obinrin naa jabọ silẹ lati inu ọkọ to n rin loju popo.
Lẹyin naa ni Nwosu wa fi igbẹjọ naa si Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Kẹfa ni kiakia.
Ẹsun ti wọn fi kan ọkọ Osinachi…
Ijọba Naijiria fi esun onigun mẹtalelogun kan Peter wipe oun lo ṣokunfa iku iyawo rẹ, Osinachi lẹyin ọpọlọpọ lilu bi bara.
Nwachukwu ni wọn pe lẹjọ ni abẹ ofin section 104 ati 379 ti iwe ofin Administration of Criminal Justice Act, 2015 pẹlu ẹsun ipaniyan eleyii to tako iwe ofin Naijiria, to si le ri iku he to ba jẹbi ẹsun naa.
Ẹsun naa ka pe ‘’Peter Nwachukwu to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ni Ọjọ Kẹjọ, Oṣu Kẹrin,ọdun 2022 lọwọ ninu iku iyawo rẹ, Osinachi fun ọpọlọpọ igba to ti na obinrin naa pẹlu imọlara pe iku ni yoo jasi fun obinrin naa.
Bakan naa ni wọn fẹsun kan an pe o tii jade kuro ninu ọkọ rẹ lori ere to si subu lulẹ.
Ijọba ni eleyii fa ipaya to tako ofin Naijiria to tako iwa ipa si ẹnikẹni.
Ọjọ Kẹjọ, Oṣu Kẹrin ni Osinachi ku ni ileewosan kan ti wọn ko darukọ rẹ.
Osinachi olorin ẹmi naa to jẹ ẹni ọdun mejilelogoji lo ku lẹyin ọjọ diẹ ni ileewosan kan ni ilu Abuja.
Lẹyin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fi panpẹ mu ọkọ naa lẹyin ti awọn akẹgbẹ Osinachi pariwo sita pe ọkọ rẹ ma n naa ni gbogbo igba ni.












