Osinachi Nwachukwu: Nǹkan márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọkọ Osinachi, Peter tí wọ́n fi ẹ̀sùn ikú rẹ̀ kàn

Peter Nwachukwu ati Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, others

Lati ọjọ Ẹti to kọja ti gbajumọ olorin ẹmi, Osinachi Nwachukwu, ti di oloogbe, ni ọpọ ti n darukọ ọkọ rẹ, Peter Nwachukwu pe o lọwọ si iku rẹ.

Ọpọ eeyan to mọ tọkọtaya naa, to fi mọ gbajumọ olorin ẹmi, Frank Edwards, lo n jẹri pe Ọgbẹni Nwachukwu lo lu iyawo rẹ pa.

Lọwọlọwọ, Peter Nwachukwu ti wa ni ahamọ ọlọpaa nilu Abuja, nibi ti wọn ti n fi ọrọ wa l'ẹnu wo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Taa gan-an ni Peter Nwachukwu?

  • Pasitọ ni Nwachukwu ninu ijọ Dunamis International Gospel Centre, Abuja, nibi ti iyawo rẹ ti jẹ adari orin ẹmi.
  • Ọmọ bibi ilu Omaboma, nijọba ibilẹ Nnewi South, nipinlẹ Anambra ni.
  • Ẹnikan to mọ ọ, Dokita Felix Onyimadu, sọ fun BBC pe, Okekenwa ni orukọ ti awọn obi rẹ sọ ọ.
  • Dokita Onyimadu sọ pe oun ko mọ nkan pupọ nipa ọkunrin naa, nitori pe ko si orukọ rẹ ninu iwe akọsilẹ awọn ọmọ ilu rẹ.
  • Iroyin sọ pe o ti le ni ẹni aadọta ọdun.
  • Nibi ipagọ orin ẹmi kan lo ti pade iyawo rẹ, Osinachi gẹgẹ bi ẹbi rẹ ṣe sọ, ki wọn o to ṣe igbeyawo.
Àkọlé fídíò, Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì

Mama Osinachi, Arabinrin Madu, sọ fun BBC pe lẹyin ọdun mẹjọ ni oun to fi oju kan ọmọ oun nigba to ṣe igbeyawo pẹlu Peter.

Bakan naa ni ẹbi naa sọ pe Ọgbẹni Nwachukwu ko gba ki Osinachi wa ẹbi rẹ tabi ki awọn naa o wa.

Koda, wọn sọ pe awọn ti gbe kuro nile arakunrin naa ri, nigba to n fi iya jẹ. Ṣugbọn, oloogbe pada sile ọkọ rẹ "nitori pe ko fẹ ki ẹnikẹni tu nkan ti Ọlọrun ti so pọ".

Amin iyasọtọ kan

Àwọn ọlọ́pàá ti fi páńpẹ́ òfin gbé ọkọ olórin ẹ̀mí "Ekwueme" fẹ́sùn lílu ìyàwó rẹ̀ dójú ikú

Peter àti Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, Facebook

Àkọlé àwòrán, Peter àti Osinachi Nwachukwu

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti nawọ́ gán Peter Nwachukwu, ẹni tó jẹ́ ọkọ olórin ẹ̀mí, Osinachi Nwachukwu tó dágbére fáyé lọ́jọ́ Ẹtì tó kọjá.

Ẹ̀sùn lílu ìyàwó rẹ̀ dójú ikú ni wọ́n fi kàn án.

Agbẹnusọ iléeṣé ọlọ́pàá FCT, Josephine Adeh ló fi ìdí ọ̀rọ̀ ọ̀hún múlẹ̀ fún ikọ̀ ìròyìn BBC.

Adeh ni àwọn nawọ́ gán Peter Nwachukwu lẹ́yìn tí ẹ̀gbọ́n olóògbé akọrin náà mú ẹjọ́ wá sí àgọ́ ọlọ́pàá láti fi ẹ̀sùn kàn ọkùnrin náà wí pé ó máa ń lu ìyàwó rẹ̀ nígbà tó wà láyé àti pé lílú tó lu obìnrin náà kẹ́yìn ló ṣekúpa.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ní ìwádìí ti ń lọ lọ́wọ́ láti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Láti ìgbà tí ìkédè ikú Osinachi ti jáde lọ́jọ́ Ẹtì ni àwọn ènìyàn ti ń gbe onírúurú ìròyìn lórí ayélujára wí pé níṣe ni ọkọ rẹ̀ máa ń lù ú bí i bàrà léyìí tí ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ wí pé òhun ló ṣokùnfà ikú rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ àti àwọn olólùfẹ́ akọrin ẹ̀mí náà ní gbogbo ìgbà ni ọkọ rẹ̀ máa ń nà án.

Frank Edwards, tí òun náà jẹ́ akọrin ẹ̀mí, lórí Instagram ló kọ́kọ́ fẹ̀sùn kan ọkọ Osinachi wí pé gbogbo ìgbà ló máa ń sọ ìyàwó rẹ̀ di àpò ẹ̀ṣẹ́.

Lẹ́yìn èyí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ náà ti ń bọ síta láti sọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa arábìnrin náà.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀

Osinachi tó dágbére sáyé lẹ́ni ọdún méjìlélógójì ní ọjọ́ Ẹtì lẹ́yìn tó lo ọjọ́ mélòó kan ní ilé ìwòsàn kan ní ilú Abuja.

Ìròyìn tó kọ́kọ́ jáde ni wí pé àìsàn jẹjẹrẹ ọ̀nà ọ̀fun ló ṣekúpa Osinachi àmọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ ní irọ́ tó jìnà sí òótọ̀ ni ìròyìn náà.

Orin Ekwueme tí Osinachi ṣe pẹ̀lú Prospa Ochimana ló sọ di ìlúmọ̀ọ́ká.

Bákan náà ló jẹ́ aṣáájú akọrin ìjọ Dunamis International Gospel Centre.

Ọkọ àti àwọn ọmọ mẹ́rin ni Osinachi fi sáyé lọ.

Ẹkùn sọ bí ìròyìn ikú gbajúgbajà olórin ẹ̀mí tó kọ orin 'Ekwueme' ṣe jáde

Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awọn olólùfẹ́ orin ẹ̀mí ti n fi ọrọ ibanikẹdun sita lati ṣe idaro iku gbajugbaja olorin Kristẹni ọmọ Naijiria Osinachi Nwachukwu.

Olorin naa to le ni ẹni ogójì ọdun dagbere faye lọjọ Ẹti n'ilu Abuja.

Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are
Àkọlé fídíò, Màmá mi jẹ́ ọ̀gá akọrin ní ṣọ́ọ̀ṣì C&S ní Ile Ife, níbẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ

Ko to di pe o ku, Osinachi a maa kọ orin ẹ̀mí ti ilẹ yoo mi títí kódà ti awọn to n gbọ́ ọ yoo maa fi ọkan wọn sunmọ Ọlọrun.

O máa n kọ iwe orin to sì di gbajumọ fun orin rẹ to kọ pẹlu gbajumọ olorin míì Prospa Ochimana "EKWUEWE". Orin naa gbayii to de ibi pe o ti lé ní èèyàn milionu mọ́kànlélógún to tí woo lori YouTube.

Osinachi Nwachukwu ati Pasitọ Enenche

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Osinachi tun ti ba ọpọlọpọ eeyan kọrin bíi orin "Nara Ekele" pẹlu ilumọọka Pasito àti adari ìjọ Dunamis International, Pasito Paul Enenche to tun jẹ Pasito fún Osinachi torí o wa lara awọn adari orin akọrin ìjọ Dunamis.

Bakan naa, o tun bá Ema kọ orin to gbajumọ yìí "You no dey use me play ó". Òun naa si ṣẹ̀ṣẹ̀ gbe orin kan jade ni to pé akọ́lé rẹ ni "God of all power".

Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, Osinachi Nwachukwu

Ohun tí àwọn eeyan ko tun le gbagbe rẹ si ni pe o maa n fi ede abinibi rẹ, Igbo kọrin ni gbogbo igba ti ara àwọn to n gbọ́ ọ yoo si maa dìde.

Osinachi fi ọkọ rẹ ati ọmọ mẹrin saye lọ.

Bawo lawọn eeyan ṣe mọ Osinachi to?

Latigba ti iroyin iku rẹ ti jade lori ayelujara làwọn akẹgbẹ rẹ ati awọn olólùfẹ́ rẹ ti n fi ọrọ ibanikẹdun síta lori ayelujara àti ránṣẹ́ si ẹbi rẹ.

"Ọjọ́ mẹfa sẹ́yìn péré ni mo pe Ọgbẹni Peter Nwachukwu láti fi erongba mi han pe mo fẹ́ gbe orin kan jade pẹlu ìyàwó rẹ Osinachi Nwachukwu ati pe ka jọ ṣepàdé papọ", Edwin kọ èyí jáde lórí Facebook.

"Wọn gba ìpè mi wọlé àmọ́ wọn ni kí n fún àwọn ni akoko lati gbàdúrà nípa rẹ.

Mo wá l'Abuja lọjọ Aje tí mo sì tún pe wọn, wọn ní àwọn yoo da ìpè mi padà".

Edwin ni gbogbo ọjọ kejì ni fóònù wọn fi wa ni pípa "afi to di asiko yii ti mo ri ìròyìn náà, mo si pe wọn láti gbọ́ òótọ́ boya o ṣẹlẹ̀, èyí dun mi gidi gan, mi ò sì gbagbọ pé o ṣẹlẹ̀ ".