Adisa Olashile: Mo fẹ́ kí bàbá rẹ́rìn-ín ni mo ṣe ya àwòrán rẹ̀, N1m ni mo ta fọ́tò náà

Baba Onilu

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oriire ni gbe alawọ rere ko ni, ni ọrọ baba onilu kan to pade oloriire kan to se ni aanu.

A se lootọ ni pe ọjọ ta ba se oriire, gaga ni ara maa n ya ni, bẹẹ ni ọrọ ri fun baba Onilu kan, to rin pade oloore rẹ.

Irinajo ti baba naa ati ọkunrin kan si rin pade ara wọn lo yi igbe aye baba yii pada, to si gba owo tuulu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bii iroyin kan ti alaanu baba onilu, Adisa Olashile gbe soju opo ayelujara Twitter rẹ, o ni oun ko mọ baba naa ri tẹlẹ rara.

Bawo ni Baba Onilu ati alaanu rẹ se rin pade?

Baba onilu yii lo maa n gbe ilu kiri agbo ariya lati lu ilu gba owo.

Baba naa, ti yoo ti to ẹni aadọrin ọdun tabi ju bẹẹ lọ, lo saba maa n duro si adugbo Secretariat nilu Ibadan lati lu ilu.

Alaanu rẹ, Adisa Olashile to n sinru ilu lọwọ nilu Ibadan, nipinlẹ Oyo salaye bo se ba baba naa pade.

Olashile ni gbogbo Ọjọbọ ti oun ba lọ fun ipade awọn agunbanirọ to n sinru ilu, ni oun maa n ri baba naa ni agbegbe Secretariat yii.

"Emi kan fẹ ki baba yii rẹrin lati ipasẹ ẹrọ ayaworan mi ni, lo jẹ ki n ya aworan rẹ lati gbe soju opo ayelujara mi.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Aworan Baba onilu ti mo ya si feremu jẹ oju ọpọ eeyan ni gbese:

Nigba ti mo si gbe aworan naa sita tan ni ọjọ kinni osu kẹrin ọdun 2022, mo wa ke sawọn eeyan lori ayelujara pe se wọn ri bi oju baba yii se gun rege pẹlu ẹrin."

Olashile ni se ni baba naa n rẹrin nigba ti oun n fi awọn aworan rẹ ti oun ya han an.

Olashile wa ya aworan naa si ara feremu nla gẹgẹ bii onisẹ ọna to jẹ, so si se afihan rẹ lori ayelujara.

Ọpọ eeyan to ri aworan naa lo n jẹ dodo baba onilu, ti wọn si n fi da oniruru ara lori ayelujara.

Koda, wọn se aworan naa bii igba to wa loju ode iwe iroyin atigbadegba ati bii yoo ti rẹwa to, ti wọn ba lo fọto baba ọhun ninu iwe iroyin.

Fọto baba onilu ati alaanu rẹ

Oríṣun àwòrán, @adisaolashile

Agunbanirọ tun ra foonu igbalode fun baba onilu:

Gẹgẹ bii Olashile se salaye, oun ri aworan baba onilu ti oun ya bii isẹ ọna ta ni owo gọbọi .

Awọn aworan baba onilu naa ni agunbanirọ yii ta ni oju opo ayelujara kan ti wọn n pe ni OpenSea ni miliọnu kan, o le diẹ naira.

Idaji owo naa si ni Olashile ko fun baba onilu.

Amọ oun mọ pe baba naa nilo owo ọhun ju oun lọ, lo mu ki oun lọ ko idaji owo naa fun baba yii.

Bakan naa lo gbe fidio ibi to ti n fun baba naa ni owo gọbọi yii sita fun araye ri.

Ọpọ eeyan si lo wa n kan saara si ayaworan to n sinru ilu naa pe o ku ọmọ se.

Lẹyin naa lo gbe aworan naa le baba yii lọwọ, bakan naa lo gbe sinu mọto rẹ lọ sagbegbe Iwo Road lati ra ẹrọ ibaraẹnisọrọ olowo nla fun.

Baba Onilu wa kan ilu sawọn agunbanirọ to jẹ akẹẹgbẹ Olashinle nibadi, ti gbogbo wọn si n fi tayọtayọ jo si ilu baba naa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2