Kemi Afolabi: Àwọn akẹgbẹ́ mí ṣe gudugudu méje láti ṣèrànwọ́ fún mí, ẹ̀rù náà fúyẹ́ láti gbé

Kemi Afolabi

Oríṣun àwòrán, Screen shot/kemiafolabiadesipe Instagram

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba Kemi Afolabi, to ni aisan aronileegun, Lupus, ti fi idupẹ ranṣẹ si gbogbo awọn ọmọ Naijiria to na ọwọ iranwọ si lasiko aisan to n la kọja.

Ninu akọjade to fi si oju opo Instagram rẹ lo ti dupẹ lọwọ ẹbi, ara ati awọn ọrẹ rẹ to fi mọ awọn ololufẹ fun aduroti wọn.

Laipẹ yii ni oṣerebinrin naa fi lede wi pe aisan ki sẹẹli ara ma a ba ara ja, ki egungun si maa ro ni ja gbogbo ara, iyẹn Lupus, n ba oun finra.

O ni dokita si ti sọ fun oun pe ko ni ju ọdun marun un si ti oun yoo lo laye, eleyii to ti lo ọdun kan ninu rẹ.

Loju opo Instagram rẹ ọhun lo ti fi lede pe kii ṣe igbesẹ to rọrun ni fun ohun lati ma sọ itan oun ati idojukọ ti oun la kọja fun awọn eniyan.

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

Mo kede aisan to n se mi sita, ki n le jẹ iwuri fawọn eeyan miran to ni aisan naa:

Nigba to n salaye idi to fi kede aisan to n ba finra sita, Kemi Afolabi ni ''Gbogbo agbara mi ni mo lo lati sọ fun awọn ọmọ Naijiria ohun ti mo n la kọja''

O fikun pe ''Amọ mo nilo lati ṣe bẹẹ ki n le jẹ iwuri fun awọn eniyan to n la iru nkan bayii kọja tabi ju bayii lọ, ki awọn naa le ni agbara lati ṣe ohun to tọ.''

''Ọpọlọpọ eniyan lo jade si mi ni ojoojumọ, ti wọn gbadura fun mi, ti wọn si n ṣikẹ mi lọna to wu ni lori''

''Ifẹ ti wọn fihan mi jẹ ki n ni okun ati agbara lati ja fitafita ki n le wa laye, ki n si wa ni alaafia si ju ti tẹlẹ lọ''

''Bi o tilẹ jẹ pe irinajo itọju aisan ti mo n la kọja ko dẹrun fun emi ati awọn ẹbi mi amọ iranwọ yin jẹ ki ẹru naa fuyẹ fun wa lati gbe.''

KEMI AFOLABI

Oríṣun àwòrán, KEMI AFOLABI/INSTAGRAM

Awọn akẹgbẹ mI ṣe gudugudu meje lati ṣeranwọ fun mi...

Ninu ọrọ rẹ ni o ti fi lede bo ṣe dun mọ oun ninu bi awọn ọrẹ ati ojulumọ to fi mọ awọn akẹgbẹ oun lagbo tiata, ṣe jiroro lori ati ran oun lọwọ, ti wọn si n fi owo na ran oun lọwọ.

''Kii ṣe owo nikan, wọn tun n yọju si mi lati wo alaafia mi ni igba de igba''

Adura mi ni pe ẹ ko ni fi aisan lo igba laye yin, iranwọ Eledumare a dide si yin, ti alaafia a si jọba ni aye gbogbo ẹyin ololufẹ mi.

Bakan naa lo gbadura fun awọn to n la idojukọ kan kọja abi omiran pe, iranwọ a de fun wọn ati okun ati agbara lati ja fun ẹmi wọn.