Kemi Afolabi: N kò mọ ohunkohun nípa ayédèrú ojú òpó Facebook tó ń bèèrè ìrànwọ̀ lórúkọ mi

Kemi Afolabi-Adedipe

Oríṣun àwòrán, kemiafolabiadesipe/Instagram

Ogun awitẹlẹ kii pa arọ, eyiun arọ to ba gbọn, bẹẹ si ni ta ba n sunkun, a maa riran.

Eyi lo mu ki gbajugbaja osere tiata nni, Kemi Afolabi figbe sita pe ki awọn ololufẹ oun sọra gidi, ki wn maa baa ko sọwọ awọn onijibiti lori ayelujara.

Kemi Afolabi lo kede lọjọ Ẹti to kọja pe aisan Lupus n ba oun finra eyi to n ro oun ninu egungun ara, ti awọn dokita si ti kede pe o ni oun ko ni ju ọdun mẹrin lati lo loke eepẹ.

Osere tiata naa fikun pe owo to to miliọnu kan naira ni oun n na lojumọ lati ra oogun ati se ayẹwo lori aisan naa, ti oun si ti ta lara dukia oun.

Idi si ree ti ọpọ awọn akẹẹ gbẹ rẹ lagbo tiata atawọn ololufẹ rẹ se n rọjo ẹbun ati adura le lori, lati seto iranwọ fun lori itọju ara rẹ.

Àkọlé fídíò, Áńkọ́fù ológun kéré fún ọwọ́ mi àmọ́ wọ́n fi okùn dì mí kúrò nílé lọ sí bárékè Odogbo

Amọ nibayii, Kemi Afolabi ti wa kede pe oun kẹẹfin awọn ọbayejẹ ẹda kan, ti wọn n beere iranwọ ni orukọ oun lori ayelujara lai jẹ pe oun mọ nipa rẹ.

Ẹ wo ọna ti Kemi Afoalabi ni fẹ gba lu araalu ni jibiti lorukọ oun:

Ninu ikede to gbe soju opo Instagram rẹ, osere tiata naa gbe aworan ohun ti awọn onijibiti naa gbe soju opo Facebook ni orukọ rẹ sita.

Ninu aworan naa ni wọn gbe aworan kemi Afolabi si, ti wọn si kọ orukọ rẹ soju opo Facebook tuntun ti wọn si ni orukọ rẹ naa, ti wọn pe ni Kemi Afolabi Adedipe.

Iwadii fihan pe ilu Eko ni awọn onijibiti naa ni awọn wa, ti wọn si fi nọmba kan soju opo naa fun awọn eeyan to ba fẹ pe wọn.

Kemi Afolabi ni ọrọ to sọ labẹ aworan naa ni "O ti de etigbọ mi pe awọn ọbayejẹ kan n lo anfaani ipo ti mo wa lati lo orukọ ati aworan mi loju opo Facebook.

Ohun ti Kemi Afolabi kọ soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, kemiafolabiadesipe/Instagram

Awọn onijibiti naa si se eleyi lai jẹ pe mo mọ nipa rẹ tabi gba asẹ lọwọ mi lati se bẹẹ.

Oju opo Facebook mi tootọ ni Kemi Afolabi/Afolabi Kemi, kii si se Kemi Afolabi Adedipe.

Mo wa n rọ ẹyin ololufẹ mi lati mase naani awọn iroyin to ba n jade loju opo awọn onijibiti naa.

Ẹ ri daju pe awọn eeyan ko ko sọwọ awọn gbajuẹ yii nidi iwa jibiti ti wọn n hu."