Kemi Afolabi: kíni lupus?, kí ló le fàá?, àmì àti ìtọ́jú rẹ̀ rèé

Kemi Afolabi

Oríṣun àwòrán, Olubayode Alebiosu

Àkọlé àwòrán, Kemi Afolabi

Onírúurú ìbéèrè ló ti ń gba ọ̀kan àti ẹnu àwọn ènìyàn láti ìgbà tí gbajúgbajà òṣèrébìnrin Kemi Afolabi ti kéde wí pé ọdún márùn-ún ni àwọn dókítà sọ fún òun wí pé ó kù fún òun lókè eèpẹ̀ nítorí àìsàn lupus tó ń bá a fínra.

Pẹ̀lú omijé lójú ni Kemi Afolabi fi kẹnu bọ ìròyìn lórí ohun tí ó ń là kọjá láti ìgbà tó ti gbọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀ lẹ́nu àwọn dókìtà.

Nínú fọ́nrán kan tó fi sórí ayélujára lọ́jọ́ Ẹti lórí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó ṣe pẹ̀lú gbajúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan Chude Jideonwo ni Kemi Afolabi ti ṣíṣọ lójú eégún pé àìsàn lupus ló ń bá òun fínra.

Láti ìgbà tí ìròyìn yìí ti gbòde ní àwọn ènìyàn ti ń bèèrè wí pé kí ló ń jẹ́ lupus àti pé kí ló ń fà á gan?

Àmì àpẹẹrẹ lupus
Àkọlé àwòrán, Àmì àpẹẹrẹ lupus

Kí ló ń jẹ́ lupus?

Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka ètò ìlera UK ṣe sọ ìyẹn UK National Health Service, àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ ni lupus, tó sì máa ń fa ara ríro, kó máa rẹ ènìyàn àti kí nǹkan máa ṣú sí ènìyàn lára.

Lupus jẹ́ àìsàn tí kò gbóògùn ṣùgbọ́n ènìyàn le ṣe àmójútó rẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ tí ènìyàn bá tètè mọ̀ wí pé ó wà lára.

Bákan náà ló jẹ́ àìsàn tó máa ń bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀ kó tó di ńlá.

Tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀, ó máa ń fa ara ríro, kó máa rẹ̀ ènìyàn ní gbogbo ìgbà àti kí ara máa ṣú.

Bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ àìsàn tó máa ń mú ènìyàn tóbi ní gbogbo ara, ọkàn, ọ̀nà ọ̀fun àti kídìnrín nígbà tó bá ti pẹ́ lára díẹ̀ si.

Nígbà tó bá búrẹ́kẹ́ tán, ó máa ń dá ọgbẹ́ sínú ọkàn, ọ̀nà ọ̀fun àti kídìnrín, kí ènìyàn máa wú lódìlódì tó sì lè mú ẹ̀mí lọ.

Báwo ni ènìyàn ṣe lè dá lupus mọ̀?

Lupus tó tún ń jẹ́ "systemic lupus erythematosus" jẹ́ àìsàn tó ṣòro láti mọ̀ lára nítorí ó jọra pẹ̀lú àwọn àìsàn mìíràn.

Àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ni àwọn dókítà máa ń ṣe láti ṣe àwárí lupus.

Bákan náà ni wọ́n máa ń ní kí ẹni tí wọ́n bá funra pé ó ṣeéṣe kó ní lupus ṣe X-ray fún àyẹ̀wò ọkàn, kídìnrín àti àwọn ẹ̀yà ara mìíràn tí wọ́n bá lérò wí pé ó le ṣe àkóbá fún.

Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ti ṣe àwárí lupus ní àgọ́ ara rẹ̀, yóò máa ṣe àyẹ̀wò lóòrè kóòrè láti le wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí nígbà gbogbo.

Àkọlé fídíò, Mi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babalawo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré - Fadeyi Oloro

Àwọn àpẹẹrẹ lupus

Àwọn àpẹẹrẹ lupus ni:

•Ara ríro

•Kó máa rẹ̀yàn ní gbogbo ìgbà bí ènìyàn tilẹ̀ sinmi

•Kí nǹkan máa ṣú sí èèyàn ní imú àti ẹ̀rẹ̀kẹ́

•Orí fífọ́

•Owó ẹnu

•Ara gbígbóná

•Kí irun èèyàn máa ja

•Kí ara èèyàn máa ṣu nínú òrùn

Àkọlé fídíò, Mo bá Obasanjo ṣiṣẹ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun àti nínú oko, ìdí tí ẹ̀mí rẹ̀ fi gùn rèé - Olórin Amona tete bo

Kí ló ń fa lupus?

Kò ì tíì ìwádìí tó fi ohun tó ń fa lupus múlẹ̀ gan an ṣùgbọ́n ó jẹ́ àìsàn tí ẹ̀yà ara le lé lọ.

Kìí ran ènìyàn, èyí túmọ̀ sí pé kìí ṣe àìsàn tí èèyàn le kó láti ara ẹnì kan sí ẹlòmíràn.

Àmọ́ lára àwọn ohun tó le fa lupus nìyìí:

•Òògùn

•Òòrun

•Ọmọ bíbí

•Kí obìnrin ma ṣe nǹkan oṣù mọ́

•Fáírọ̀ọ̀sì

Ìwádìí fi hàn pé obìnrin ló sábà máa ń ní lupus ju ọkùnrin lọ, tó sì wọ́pọ̀ nílẹ̀ Adúláwọ̀ àti ilẹ̀ Asia