Mother with six set of twins: Ọkọ sá fún mi, ẹbí kọ̀ mí nítórí pé mo bí ìbejì lẹ́ẹ̀mẹfà

Nkan ẹni kii di meji, ki inu o bi ni. Bẹẹ ni Yoruba n wi.
Bi nnkan ẹni ba wa di pupọ, ni ilọpo-ilọpo, ṣebi o yẹ ka gba ilu, ka gba ijo ni.
Amọ eyi ko ri bẹẹ fun arabinrin kan to bi ibeji lẹẹmẹfa ọtọọtọ, ti gogbo wọn si wa laaye.
- Alaafin bi ibeji l‘ẹẹmeji lọsẹ kansoso
- ''Ìrírí mí rèé lóri bí mo ṣe fún ìbejì mí lóyún tó sì tún bí ọmọ méjì fún mi''
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá tó bí ìbejì
- Àrà mérìírí! Ìbejí tí a bí ní ọdun 2021 àti 2022 pẹ̀lú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dògún láàrin wọn
- Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ń se ọbẹ̀ tó máa ń fún wọn ní ìbejì ní Igbo-Ora
- Wo àwọn ìbejì tó mú ẹ̀dọ̀ àti egungun àyà kan ṣoṣo wá látọ̀run
- Obìnrin kan bí ibejì lẹ́yìn ọjọ́ 26 tó bí ọmọkùnrin
Ọrọ ọmọ bibi yii mu ki awọn ẹbi ati ọrẹ sa fun Gladys Bulinya. Koda, ọkọ rẹ to n fun loyun awọn ọmọ naa paapaa salọ.
Ibẹru mu ọkọ naa, to si gbagbọ pe ogun aye tabi eedi lo mu iyawo rẹ nigba to bi abala to kẹhin ninu awọn ibeji naa lọdun 2010.
Iṣẹlẹ yii lo sọ Gladys di iya n da a gbe pẹlu mẹwa lara awọn ọmọ rẹ ninu yara kan to fi koriko kọ nitosi adagun odo Lake Victoria lorilẹ-ede Kenya.
Irinajo mi ree lori bi mo se bi ọmọ mejila:
O sọ fun akọroyin BBC to ṣabẹwo si pe, ile ẹkọ girama ni oun wa nigba to kọkọ loyun awọn ibeji akọkọ, John ati James, lọdun 1993.
Ọrẹkunrin rẹ nigba naa ko ti i dagba to ẹni to le ṣe igbeyawo.
Nigba to bimọ, awọn obi rẹ fi dandan mu lati gbe awọn ọmọ naa lọ si ileewosan to wa lagbegbe wọn lati fi wọn tọrẹ.
Idi ni pe aṣa wọn gẹgẹ bi ẹya Bukusu, ko faaye gba ki eeyan o bi ibeji. Igbagbọ wọn ni pe ofo ati adanu ni awọn ọmọ naa ma n ko ba ẹbi.
Iku si ni fun awọn obi wọn ti ẹnikan ninu awọn ibeji naa ko ba ku.
Laipẹ, baba to bi ọrẹkunrin rẹ gbọ nipa awọn ibeji naa, o si gba wọn sọdọ lati ma a tọju wọn. Oun kii sẹ ẹya kan naa pẹlu wọn.
O tun 'kagbako' ibeji ninu igbeyawo rẹ akọkọ ati ikeji:

Lẹyin ọdun marun-un, Gladys tun bẹrẹ irinajo ifẹ pẹlu olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan, wọn si ṣe igbeyawo.
Ile awọn obi ọkọ rẹ lo n gbe to tun fi bi ibeji miran - Duncan ati Dennis. Bayii ni wọn sẹ le jade nitori ibẹru pe ẹnikan yoo ku ninu ẹbi wọn.
Kaka ki awọn obi rẹ gba a sile, niṣe ni wọn fi dandan fi fun ọkunrin kan to fi ogun ọdun ju u lọ lati fi sẹ aya, ko ma ba a ko 'ori buruku' ran wọn.
Bo tun ṣe bẹrẹ si ni bi ibeji re e . o bi ikẹta, ikẹrin ati ikarun-un. Ẹlẹkẹfa to bi lọdun 2010 lo mu ki ọkọ sa kuro nile lai boju wẹhin.
'N ko kabamọ pe mo bi awọn ọmọ ni'
O ṣalaye fun akọroyin BBC pe "oriṣiriṣi iṣẹ ẹgbin ni mo n ṣe lati fi tọju awọn ọmọ mi mẹwaa. Mi o mọ ibi ti ọkọ mi wa. Ko si nkan to le fi ran wa lọwọ gan-an to ba wa pẹlu nitori ko ni agbara lati sẹ iṣẹ kankan mọ nitori ọjọ ori."
Ṣugbọn, o ni oun ko kabamọ pe oun bi awọn ọmọ naa, nitori pe ibukun lati ọdọ Ọlọrun ni wọn jẹ fun oun.
Ni bayii, o ṣalaye pe oun ti fi aidunnu faramọ didi ile ọmọ pa, botilẹ jẹ pe o tako igbagbọ rẹ gẹgẹ bi ọmọ ijọ Katoliiki.
O ni "ọmọ ijọ Katoliiki ni mi. Nigba ti mo gbe igbesẹ naa, mo tọrọ̀ aforiji lọwọ Ọlọrun, o si damiloju pe o mọ nipa nkan ti mo n la kọja, to si ti dariji mi."





















