Ilorin Conjoined Twins: Àwọn òbí ìbejì tó lẹ̀pọ̀ ní ọ̀kàn àwọn bàjẹ́ láti rí ibèjì wọn tó
Ohun ayọ ati idunnu ni ọmọ bibi jẹ, gbogbo obi ati ẹbi lo si maa n fi oju sọna lati ki ọmọ tuntun kaabọ saye ni kete ti alaboyun ba ti loyun.
Amọ eyi ko ri bẹẹ fun arabinrin Tawakalitu Ahmed ati ọkọ rẹ nilu Ilorin, ẹni ti ọba oke fi ibeji lanti-lanti ta lọrẹ.
Idi ni pe awọn ibeji naa lẹ pọ ni lati igba aya lọ soke nigba to bi wọn, bi o tilẹ jẹ pe ayẹwo to se ninu oyun ko fihan pe awọn ibeji to wa ninu rẹ ti lẹpọ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to la kọja ninu oyun ati lẹyin to bi awọn ibeji naa tan, Tawakalitu ni ibanujẹ nla lo gba ọkan oun lati ri pe awọn ọmọ naa ko pe lara.
O ni ọpọ ọrọ ti ko dara ni awọn eeyan ti sọ nipa awọn ọmọ oun, ti wn si gba iya mi nimọran lati fi oogun pa wọn nitori abami ọmọ ni wọn
O ni isẹ abẹ to jẹ aseyọri ti wọn se fun awọn ibeji naa nile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti Ilorin lo tun mu ayọ pada si ọkan oun.
Bakan naa, awọn dokita to sisẹ abẹ yii ba BBC Yoruba sọrọ lori ọna ti wọn gba ati irinsẹ ti wọn lo lati ya awọn ibeji naa, ninu isẹ abẹ oni wakati meje to jẹ aseyọri.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ǹjẹ́ o mọ àwọn òṣèré bí Oyin Adejọbi, Funmi Martins àtàwọn míì tó ti dágbére fáyé?
- Ìtàn ìgbé ayé Isola Ogunsola 'I-sho Pepper', ògbóǹtagí òṣèré tíátà tó s'eré Yorùbá yíká Nàìjíríà
- Kí ló wà ní ìdí igbá tí àwọn olorì Aláàfin máa ń tí lóde Ọ̀yọ̀
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
- Igbo Olodumare rèé, níbi tí Ìgbín ti tóbi ju Ìjàpá lọ
- Ìdílé márùn-ún tó gbajúmọ̀ fún òwò ẹrú nílẹ̀ Yorùbá
- Wo ìtàn ayé gbajúmọ̀ adigunjalè méje nílẹ̀ Yorùbá
Ohun ayọ to tun wa nibẹ ni pe ile iwosan ẹkọsẹ isegun naa ti gba awọn obi awọn ibeji naa sẹnu isẹ, ki wọn le ri owo tsju awọn ọmọ naa.




