Igbo Olodumare: Ohun gbogbo tó wà nínú ìwé Fagunwa ló wà nínú igbó náà

Abawọle Igbo Olodumare

Oríṣun àwòrán, Ondo State Government

Fun igba akọkọ, ẹnu alagba Daniel Olorunfemi Fagunwa, ti ọpọ eeyan mọ si D.O Fagunwa ni wọn ti gbọ nipa Igbo Olodumare.

Iwe yii ti Fagunwa kọ lọdun 1949 si ni awọn eeyan kan gbagbọ pe o jẹ iwe arosọ keji ti wọn yoo kọ ni ede Yoruba lẹyin iwe Ogboju Ode Ninu Igbo Irunmole.

Idi ni pe akọni onkọwe naa kọ iwe kan to pe akọle rẹ ni Igbo Olodumare, ti ọpọ eeyan si maa n ro pe arosọ lasan ni iwe naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn ọpọ eeyan ni ko mọ pe Igbo kiji-kiji kan wa nipinlẹ Ondo lagbegbe ilu Okegbo, tii se ilu abinibi Fagunwa, ti wọn n pe ni Igbo Olodumare.

Irinajo si Igbo Olodumare lati ilu Okegbo, to wa loju ọna Ife si Ondo si to ogun Kilomita.

Iwe Igbo Olodumare ti D.O Fagunwa kọ

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Fun iyalẹnu, ọpọ awọn orukọ ti Fagunwa mẹnuba ninu iwe rẹ lo wa ninu Igbo Olodumare ta n sọrọ rẹ yii bi o tilẹ jẹ pe awọn ohun aramọnda bii iwin, idan, ati ọpọ adiitu ti poora nibẹ.

Sugbọn ẹ jẹ ka wo awọn ohun to wa ninu igbo naa to farapẹ awọn ohun ti Fagunwa mẹnuba ninu iwe rẹ.

Àkọlé fídíò, Kollington ṣàlàyé bí orin Fuji ṣe bẹ̀rẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà

Awọn ohun aramọnda to wa ninu Igbo Olodumare:

Abawọle Igbo Olodumare:

Ni ẹnu ọna abawọle igbo ẹrujẹjẹ naa ni akọle kan wa to n se apejuwe ọna sinu igbo ọhun.

Amọ ohun iyalẹnu ni bi wọn se ni igbin tobi ju ijapa lọ ninu igbo naa.

Akọle naa si lo ni "Eyi ni ọna ilu Igbo Olodumare nibi ti igbin ti ga ju Ijapa lọ

Akọle Igbo Olodumare

Oríṣun àwòrán, @battravels

Oke Langbodo:

Bakan naa ni Oke Langbodo wa ninu Igbo Olodumare, ara igi kan si ni wọn so akọle to n juwe ọna sori oke naa si.

Irin arinwọdi si ni ki eeyan to gun oke yii, eyi ti kii se eremọde rara.

Ori oke yii si ni wọn ti sọ pe igbin tobi ju ijapa lọ, aarin gbungbun Igbo Olodumare si ni Oke langbodo wa.

Oke Langbodo

Oríṣun àwòrán, @battravels

Ere Baba Onirungbọn yẹukẹ to n gbe ibi gegele okuta:

Ere baba onirungbọn yẹukẹ naa wa ninu igbo olodumare yii.

Baba naa, ninu aworan yii lo de fila, ti irungbọn rẹ si gun lọ gbọọrọ, bẹẹ lo dudu pẹlu.

Koda, baba naa fi igi kan hanu to dabi ikoko taba, to si joko dabu ẹsẹ rẹ sori ara wọn.

Baba Onirungbọ̀n yẹukẹ

Oríṣun àwòrán, Sunshine

Apata Adimula:

Ẹsẹ bata to to mẹtalelaadọrin ni eeyan yoo ka ko to de ori Apata Adimula, nibi ti awọn agbaagba meje ti lọ sepade pẹlu Ojola ibinu, tii se olori ejo aye gbogbo, gẹgẹ bo se wa ninu iwe Fagunwa.

Fagunwa ni ẹẹkan ninu ọdun kan si ni Ojola ibinu naa maa n jade sita, ẹni to sọ pe o ni ori bii ti eeyan.

Aworan Ojola Ibinu

Oríṣun àwòrán, @TaoheedLawal

Aginju Idakẹrọrọ:

Aginju Idakẹrọrọ yii ni Fagunwa se apejuwe rẹ pe o dakẹ mini-mini, eku ati ẹyẹ kii ke nibẹ, bi abẹrẹ si bọ silẹ, eeyan yoo gbọ iro rẹ.

Fun iyalẹnu, ni aginju idakẹrọrọ ninu Igbo Olodumare loju aye, wọn kii faye gba ki ẹnikẹni bara wọn sọrọ, wọn kan maa n fi ọwọ se apejuwe fun ara wọn ni.

Igbo idakẹrọrọ

Oríṣun àwòrán, @CAPRITOLU

Ibẹ tutu mini mini lootọ, to si dabi ẹni pe ojo sẹsẹ rọ ni nigba ti awọn agbegbe yoku ninu igbo naa si gbona.

Bakan naa ni oju ọna si Isalu Ọrun, Ibujoko Olowo Aye ati odo ewe gbese ati Ọgbun Ainisalẹ wa ninu Igbo Olodumare gẹgẹ bi Fagunwa ti se apejuwe rẹ.

Àkọlé fídíò, Ikogosi-Ekiti: Ilu ti omi tutu ti dapọ mọ gbigbona