D.O Fagunwa: Akọni Òǹkọ́wé, tó kó ipa sí àgbéga èdè Yorùbá kú àmọ́ dúkìá rẹ̀ ń fọhùn síbẹ̀

BBC Yoruba sabẹwo si ile ati yara ti gbaju-gbaja onkọwe ni, D.O fagunwa lo nigba aye rẹ, iyalẹnu lo jẹ pe lẹyin ọdun 61 to ti papoda, ijọba tabi ẹlẹgbẹjẹgbẹ kankan ko satunse ile ati dukia to fi silẹ.

Aga Fagunwa
Àkọlé àwòrán, Igba n lọ, igba n bọ, aye ko duro si oju kan. Aga to wa ninu yara Daniel Ọlọrunfẹmi Fagunwa ree, eyi ti baba lo nigba aye rẹ.
Aga Fagunwa
Àkọlé àwòrán, Awọn aga manigbagbe ti Fagunwa lo ree. Boya ori ọkan ninu awọn aga yii gan lo ti kọ ọkan ninu iwe rẹ
Ẹnu ọna yara Fagunwa
Àkọlé àwòrán, Ẹnu ọna abawọle yara D.O Fagunwa nile rẹ to wa ni Oke Igbo ree.
Ibusun Fagunwa
Àkọlé àwòrán, Ko si ohun ta mu wa saye, ko si ohun ta mu lọ sọrun. Ori ibusun Fagunwa ree bi o tilẹ jẹpe awọn eeyan kan tun ti lo ori ibusun yii lẹ yin iku rẹ
Ilẹ yara Fagunwa
Àkọlé àwòrán, Lara awọn eroja ta foju ri ni yara Fagunwa ree. Lero tiyin, se ko yẹ ki ijọba fi ile atawọn dukia ti Fagunwa lo yii se ibudo irinajo afẹ fun iran Yoruba, ka si tun ibẹ se.
Ilẹ yara Fagunwa
Àkọlé àwòrán, Awọn ẹni atẹẹka to ti dogbo, ta ri ni yara Fagunwa ree. O daju pe ọjọ ti lọ lori wọn
Abawọle ile Fagunwa
Àkọlé àwòrán, Ọwọ lo n tun ara se. Ko ba dara ti ijọba tabi ajọ alaanu ba tun ile Fagunwa se di ibi apewawo. Tiwa n tiwa.
Abawọle ile Fagunwa
Àkọlé àwòrán, O yẹ ka maa se agbelarugẹ awọn ọlọpọlọ pipe ọmọ Kaarọ Oojire to ti kọja lọ, ko si yẹ ka jẹ ki dukia wọn segbe pẹlu wọn
Oju ferese Fagunwa
Àkọlé àwòrán, Ọmọ Yoruba, ẹ dide lati maa seranti awọn akọni wa to ti lọ bii Fagunwa. O yẹ ka tun ile rẹ se ju bayi lọ
Ile Fagunwa
Àkọlé àwòrán, Iroyin ko to afojuba. ni aduru iwe ti baba Fagunwa kọ, ko yẹ ka gbagbe awọn ohun to fi silẹ.
Ẹnu ọna ile Fagunwa
Àkọlé àwòrán, Itan nla ni igbe aye D.O Fagunwa kọ wa pe ohun ta ba gbe ile aye se lo ja ju, kii se ọrọ̀ ta ba ko jọ. Fagunwa ko ipa tiẹ si idagbasoke ọmọniyan lai le dukia aye lasan. Ẹ wo, ilẹkun yii fidi rẹ mulẹ.