D. O Fagunwa, Adebayo Faleti, Akinwumi Iṣọla, Lawuyi Ogunniran àti Oladejo Okediji ṣiṣẹ silẹ ki wọn to lọ

Awọn iwe akagbadun

Awọn Onkọwe ju onkọwe lọ gẹgẹ bi ọmọ ṣe ju ọmọ lọ.

Bi onirese ko ba fingba mọ, awọn to ti fin silẹ ko le bajẹ.

Bẹẹ iṣẹ awọn agba ọjẹ to ti lọ sinmi pẹlu awọn baba nla wọn a maa tọ wọn lẹyin ti aye a si maa ka wọn sii.

Litireṣọ akọsilẹ Yoruba de lẹyin ti mọọkọ-mọọka de ba ede Yoruba ni.

Ọpọlọpọ iwe lo ti jade to jẹ akagbadun ti awọn eeyan n ka fi kọ ẹkọ ṣugbọn ti awọn marun un ti a n gbe yẹwo loni yatọ.

Adebayọ Faleti, D. O Fagunwa, Akinwumi Isola, Lawuyi Ogunniran àti Oladejọ Okediji ni awọn agbaọjẹ onkowe ti a fẹ gbe iṣẹ wọn wo bayii.

Awọn iwe akagbadun ti a si fẹ gbeyẹwo naa ni: Aja lo lẹru, Eegun Alare, O le ku, Ogboju Ọdẹ ninu igbo Irunmọlẹ ati Ọmọ Olokun Eṣin.

O fẹrẹ ma si agbalagba onkawe ede Yoruba ti ko tii ni ka awọn iwe yii nitori wọn kun fun ẹkọ to dara lati ṣamulo laye ode oni

1) O le ku lati ọwọ Oloogbe Ọjọgbọn Akinwumi Orojide Iṣola.

Ọdun 1974 ni iwe yii jade ni eyi to ṣafihan iwa ati iṣẹ awọn ọdọ Yoruba ni asiko naa ninu itan Naijiria.

Iwe yii jẹ itan arosọ to da lori ọrọ ifẹ laarin awọn ọdọ mẹta ati ipa obi, ẹbi, ara, awujọ ati ọlaju aye igba naa lori ipinnu awọn ọdọ ọhun.

Àkọlé fídíò, ‘Ara fu mí nígbàtí bàbá gbé Bíbélì ìdílé fúnmi’

Ajani akẹkọọ to wa ni ipele aṣekagba ni fasiti nibiti sanmọnti gbe dun ile to tun jẹ ọlọgba ẹranko ni olu ẹda itan to nifẹ Aṣakẹ, Lóla àti Ṣade.

Iyawo ni Ajani n wa lataari pe iya rẹ n yọọ lẹnu nigba gbogbo pe ohun to kan fun un naa ni ki obinrin wa ni ẹẹdẹ rẹ.

Aṣake jẹ ololufẹ Ajani lati ibẹrẹ ṣugbọn ẹru Baba Kekere aburo baba rẹ to n tọju rẹ n ba a; Lọla jẹ akẹkọọ wọle fasiti to wa ni ipele aṣẹṣẹ wọle nigba ti Sade jẹ ojulumọ Ajani tẹlẹ.

Iwe O le ku

Oríṣun àwòrán, @Sunchine

Ikorita tani ki n fẹ́ lo da irinajo Ajani to jẹ́ oluda itan naa ru lẹ́yin to setan ni Fasiti.

Wọn ti ṣe e si fiimu agbelewo lọdun 1997, lati ọwọ ileeṣẹ MainFrame eyi ti Tunde Kelani dari rẹ to si ti di awogbadun sinima.

Akinwumi Isola tun kọ́ ọ́pọ́ iwe miran fun igbadun awọ́n ololufẹ́ ede Yoruba ki ọlọ́jọ́ to mu agba ajẹ̀ naa re ibi agba n re!

Sinima O le ku

Oríṣun àwòrán, @Mainframe

2) Ogboju Ọdẹ Ninu Igbo Irunmọle lati ọwọ oloogbe Daniel Olorunfẹmi Fagunwa

Oloogbe Daniel Olorunfrmi Fagunwa lati Oke Igbo ni ipinlẹ̀ Ondo lo kọ iwe yii

Lọ́dun 1938 ni Fagunwa kọ iwe itan aroso yii to jẹ́ akọ́kọ́ iru rẹ̀ nilẹ̀ Adulawọ ni eyi ti wọ́n gbe jade lọ́dun 1950 saaju ominira Naijiria.

Ogboju ọdẹ ninu igbo irunmole je itan awon akoni meje ti wọn lo sinu igbo ibẹru, igbo to kun fun awọn ẹbọra lorisiirisii ni eyi ti wọn lọ́ wa nkan iyebiye fun Oba ilu wọn ki alaafia le jọba ni ilu wọn, iyẹ́n Eso Ironu.

Ogboju Ọdẹ ninu Igbo Irunmọlẹ da lori itan igbesi aye Akara Oogun, akani ọ́dẹ́ to n pa erin, pa ẹfọ̀n to jẹ olu ẹda itan iwe naa.

O so bi iya rẹ to jẹ ogbologbo ajẹ ati baba rẹ, Olowolayemmo se ku ki oun to di akọni eda.

Igbo Olodumare to safihan itan Olowo aye to jẹ́ baba Akara Oogun ni wie ti Fagunwa geb jade tẹ́le Ogboju ọdẹ nibi o se tà lori igba tó

Ogboju #ode

Oríṣun àwòrán, @Amazon books

Iya ré lo pa ọma mẹjọ mii ti baba rẹ bi pẹlu iyawo mẹta ti wọn jẹ orogun iya rẹ.

Eso Ironu ni awọn meje naa lọ ba awọn ara ilu wọ́n wa ninu igbo irunmole to kun fun iwin, ẹbọra, Olori Igbo, Abami ẹda, ati ọrọ igi.

Awọn meje ti wọn lọ naa ni: Akara oogun, Kako Oni kumọ ẹkun, Olohun Iyọ, Elegbeje Ado, Aramanda Olotutu, Imadoye ati Efo Iyẹ.

Akara Oogun ati awọn diẹ lo pada wa sile lẹyin ti wọn ri eso naa gba wa sile.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ onkowe miran lo ti sise lori iwe yii ni awọn Fasiti Naijiria gbogbo.

Koda, wọ́n ti tumọ̀ rl si ede oyinbo ti wọ́n si pe akọ́le rẹ̀ ni: The Forest of Thousand Demon

Orukọ awọn akọni meje naa niwọnyii:

-Akara Oogun

- Kako Oni kumọ ẹkun

- Olohun Iyọ

- Elegbeje Ado

- Aramọnda Olotutu

- Imọdoye

-Efo Iye

Àkọlé fídíò, Àmì ohùn ṣe pàtàkí nínú èdè Yoruba púpọ̀

3) Ọmọ Olokun Ẹṣin lati ọwọ oloogbe Adebayọ Faleti

Iwe itan arosọ yii ni Adebayo Faleti kọ lọdun 1958 ṣaaju ominira Naijiria to pada wa si imuṣẹ ni ọjọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 1960.

Ọdun 1970 ni Faleti gbe iwe naa jade fun igba akọkọ.

Iwe naa ni Adebayo Faleti fi yaworan ohun ti awọn eeyan la kọja ṣaaju ominira lọwọ amunisin oyinbo ati ti eeyan dudu to wa ni ipo adari.

Oyo Òkò atijọ ni ibudo itan iwe naa, O safihan iṣoro ijẹgaba ati imunilẹru ti awọn ọdọ koju nigba naa ni ilẹ Yoruba.

Adebayo Faleti

Oríṣun àwòrán, @Ps/io/sta

Àkọlé àwòrán, Adebayo Faleti

Ajayi ni olu ẹda itan to jẹ ọmọ Oloye Olokun Esin. ajayi kọ ifiyajẹni ni eyi to sọọ si oko ẹru.

Lẹyin ti oju rẹ ati awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ jijangbara ri to loko ẹru, o jijangbara, o jajabọ o si yọ awọn eniyan rẹ (Òkò) kuro ninu iṣoro yii ti wọn si gba ominira nigbẹyin kuro lọwọ Olumoko.

Ominira yii lo ṣi oju awọn ọdọ agbegbe miran si ọna abayọ iṣoro to n koju koowa ni abule wọn to sọ wọn di ẹru labẹ awọn adari amunisin gbogbo.

Iwe yii fọrọ yaworan itan iran Yoruba ninu iṣẹlu, awọn ohun to ṣẹlẹ ṣaju ominira ati awọn ọna ijijangbara oriṣii ti awọn eeyan n lo lati fi bọ ninu ajaga ijẹgaba ninu itan Adulawọ.

Adebayo Faleti tun kọ awọn iwe miran bii Basorun Gaa to je iwe ere onitan ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewi to dun bii Onibode Lalupọn, Alagbara ile ati Alagbara Oko, Adebimpe Ojedokun, Erelu omo ati bẹ́ẹ̀ bẹẹ̀ lọ

Iwe Omo Olokun Ẹṣin, yii n ran onkawe leti pataki ominira, pẹlu ẹkọ loriṣiiriṣi nipa igbe aye alaafia ati ọna ijijangbara kuro loko ẹru.

Pamela Olubunmi Smith ti tumọ iwe akagbadun yii si ede Oyinbo ni eyi to pe ni: The Freedom Fight lọdun 2010

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

4) Eegun alare lati ọwọ oloogbe Lawuyi Ogunniran

Iwe Eegun Alare lati ọwọ Lawuyi Ogunniran jẹ iwe akagbadun fun gbogbo ọmọ Yoruba sugbọn o tun jẹ iwe to n mu ori ẹni to ba fẹran Ẹsa tabi Iwi Egungun pupọ wu soke.

Ojelade ni olu ẹda itan naa ti Iyaduuni, iyawo Ọjẹlarinaka bi nigba ti ko si nile to ti sawo egungun ló.

Ojelarinaka jẹ agba eegun to maa n sere to tun n pidan lagbo lati ileto kan si ikeji.

Eegun Alare

Oríṣun àwòrán, @CSS

Iyawo re wa ninu oyun nigba to sere eegun lọ to si fa a le Dasofunjo ọrẹ rẹ ti wọn jọ jẹ Ojẹ eegun lọwọ nigba to n lọ.

Ni kete ti Iyadunni bi Ojelade ni akọsẹjaye rẹ ti fihan pe o maa ni laari nidi isẹ eegun ju Ojelarinaka, baba rẹ lọ ni eyi ti mọlẹbi fi fa a le Dasofunjo lọwọ lati kọ ọ ni ise ọ̀jẹ̀.

Nigba ti Ojelade dagba oun naa tun se ere eegun lọ silu miran nibi to ti ko si wahala nitori pe ko juba awọn agba Ọjẹ ko to bẹrẹ idan pipa.

Lẹyin o rẹyin baba kan ba so Ojelade ni agadagodo lẹyin to di ọọni tan eyi ti ko si le yipada di eeyan mọ.

Ojelade ba pe ẹsa eegun titi to si ki ara rẹ dele baba rẹ Ojelarinaka ni baba naa ba tu u silẹ nigba to rii pe ọmọ oun ni.

Àkọlé fídíò, Wo imọran Fọlọrunṣọ Alakija fun awọn ọdọ adulawọ

.

Nigba ti Ojelarinaka ati Ojelade fi maa pada si ilu wọn pẹlu ayọ pe wọn foju ri ara wọn ni Iyadunni , to jẹ́ iya Ojelade ba ti ku.

Ko pe lẹyin naa ni Ojelarinaka naa di ero ọrun.

Ojelade wa di agba ọjẹ laarin awọn eleegun to si lokiki pupọ de ibi pe Alaafin Oyo nigba naa pada fi jẹ oye Baalẹ Arẹkujaye lẹyin to dije pẹlu Duduyẹmi, agba eleegun miran.

O bori idije dupo oye Baale Arekujaye naa nipa pipe ohun ẹsa ati nipa idan pipa nilu Oyo.

Ojelade gba ade Arẹkujaye ni gbogbo ilẹ Oyo nigba naa to si di olokiki to lowo, to lọrọ pẹlu iranlọwọ iyawo rẹ ti oun naa wa lati ile eleegun pẹlu.

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi

5) Aja lo l'ẹru lati ọwọ oloogbe Oladẹjọ Okediji.

Oladejo Okediji jẹ agba ọjẹ onkọwe itan arosọ ni nigba aye rẹ ki ọlọjọ to de sii lẹni ọdun mọkandinlaadọrun.

Awọn iwe rẹ pupọ lo da lori iwa ibajẹ ati ọna idajọ to ye kooro fun awọn oniṣẹ ibi ninu eyi to ti maa n ṣafihan awọn iwa ibi to wọpọ lasiko naa.

Lọdun 1969 ni Oladejọ Okediji gbe iwe aja lo lẹru jade lati ile iṣẹ Longmans of Nigeria ni Ibadan ni ipinlẹ Oyo ni eyi ti wọn tun tẹ ni ọdun, 1981, 1996, ati ni 2000 lati ile iṣe Longman ni Ikeja.

Aja lo lẹru

Oríṣun àwòrán, @Atelewo

Aja lo léru je iwe itan arosọ akagbadun lede Yoruba to safihan iwa ibaje awọn agbofinro.

Awọn ọlọpaa kọọkan ni wọn n se agbodegba fun awọn ole ati awọn onisẹ ibi ninu iwe naa.

Oga Audu Kareem ni ọga agba ọlọpaa ti ọwọ rẹ̀ ko mọ rara, to si n huwa ibi nitori riba to n gab lọ́wa awọn ole ati ajinigbe.

Tafa jẹ amugbalegbe ẹda itan ti onkọwe sapejuwe drẹ ninu iwe itan arosọ naa.

Tafa jẹ́ ọdaran pọnbele to mọ ọgbọn ayinike ati ayinipada awọn onisẹ ibi lorisiirisi ki o to di pe o salabapade Lapade ti o si yipada si olootọ ni awujọ.

Àkọlé fídíò, Tinubu: Nítorí Tinubu, àwọn ọmọge Sanwo-Olu da ìlù bolẹ̀

Lapade ni Olu ẹeda itan to jẹ akọni to n gbogun ti iwa ibajẹ ni awujọ lasiko naa.

Leyin ti Tafa yipada tan si ẹni rere, lo bẹrẹ si ni ran Lapade lọ́wọ lati mu awọn to n se ika ni awujọ sugbọn awọn jẹgudujẹra ọlọpaa bii Oga Audu ko jẹ ki isẹ wọn yọ rara.

Eyi ko seyin pe wọn maa n tun n da awọn eeyan gbajue bii Taiwo, Gbekuta ati awọn ọmọ ita miran silẹ ni lẹyin ti Tafa ati Lapade ba ti mu wọn tan.

Okediji

Oríṣun àwòrán, @Okediji f/bk

Ni igbeyin iwe yii, onkọwe Oladejo Okediji fi ọrọ yaworan gbogbo iwa ibi to n sẹlẹ nigba naa, eyi to si ba igba mu di asiko yii.

Oloogbe Oladejo Okediji tun ko iwe Agbalagba Akan gẹgẹ bii abala keji iwe Aja lo lẹru ti a n gbeyẹwo yii.

Tafa ati Lapade ni awọn ẹda itan to ṣe gboogi nibẹ pẹlu iwa ifarada, iforiti ati fifọ awujọ́ mọ́..

Okediji naa maa n lo awọn ẹwa ede ati litireṣo alohun ninu agbekalẹ itan rẹ bii ti awọn agba onkọwe mẹrin to ku ti a n sọ nipa wọn yii ni.

Awọn iwe miran ti Oladejọ Okediji tun kọ ni Rẹrẹ Run, Agbalagba Akan, Atoto Arere ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Kini o ya awọn agba ọjẹ yii sọtọ ninu litireso itan arosọ Yoruba?

Ẹwa ede to kọja afẹnusọ ni awọn agba onkọwe maraarun yii lo nipa kikọ awọn iwe itan arosọ maraarun ti a gbe yẹwo wọnyii

Awọn agba onkọwe yii fi ọrọ dara pupọ, wọn fi ọrọ yaworan to fi dabi pe ẹni pe eeyan n woran sinima ni ti eeyan ba n ka awon iwe ko see ma ni ti kosi see ma ka naa.

Itan ninu itan, Afiwe ẹlẹlọọ ati Afiwe taara ni awọn Onkọwe yii tun fi safihan iwa ọmọluwabi bii itẹlọrun, Ifẹ ati Ootọ inu fun awọn Onkawe gẹgẹ bii ẹkọ to yẹ ni kikọ.

Litireso alohun jẹyọ pupọ̀ ninu awn iwe yii bii ẹ̀sà eeegun, oriki, ọ̀rọ̀ asọregee ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Eko ipari:

Ọpọ onkọwe miran lo ti dide lasiko yii sugbọn ko si bi a maa se pa itan iwe akagbadun iwe litireso Yoruba ti a ko ni fi ida Daniel Olorunfemi Fagunwa, Adebayo Faleti, Akinwumi Orojide Isola, Lawuyi Ogunniran, ati Oladejo Okediji lale gaaraga.

Eyi ko sẹyin pe awọn agba ọjẹ yii wa lara awọn to kọkọ si oju awọn onkawe si iwe litiresọ akagbadun ni ede Yoruba.

Awọn Onkọwe maraarun ti a gbe iṣẹ wọn yẹwo yii ni wọn ti filẹ bora bi aṣọ ṣugbọn awọn iṣẹ wọn ṣi n jẹ akagbadun lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti tẹ wọn jade laye.

Àkọlé fídíò, Obinrin Akansẹ: Ẹsẹ kiku bi ojo kọ mi lati di alagbara

Wọn ti tumọ ninu awọn iwe wọnyii si ede oyinbo ki awọn ti ko gbọ ede Yoruba naa le maa ka wọn ni akagbadun.

Lara rẹ ni Ọmọ Olokun Eṣin, Ogboju Ọdẹ ninu Igbo Irunmọle nigba ti awọn miran bii O le ku ti di sinima agbelewo bayii.

BBC Yoruba n gba ẹyin ọdọ asiko yii naa nimọran lati fi irun dudu ṣiṣẹ si idagbasoke ede ati aṣa Yoruba ko ma baa parun lasiko ti yin, ki awọn eeyan le ri ipa rere ti yin naa sọ nigba ti agba tabi ọlọ́jọ́ ba de.

Sebi ariṣe ni arika, bẹẹ, arika si ni baba iregun, ohun ti awa naa ba ṣe loni fun itẹsiwaju ede ati aṣa ati iwa ọmọluwabi ti a mọ iran Yoruba mọ naa ni a o sọ nipa wa lẹyin ọla.