Ned Nwoko: Regina Daniels kàn wù mí ni, mo nàwọ́ sí i ó sì di tèmi

Oríṣun àwòrán, Regina daniels/instagram
Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin, Regina Daniels, Ned Nwoko sọ pe aarin ọsẹ mẹta pere ni oun fẹ iyawo oun Kẹfa, Regina.
Ninu ifọrọwanilẹnu kan to ṣe pẹlu BBC Igbo lo ti fi asiri ọrọ naa sita.
Ọgbẹni Nwoko ṣalaye pe oun ko faramọ ki ọkunrin ati obinrin fẹ ara wọn fun igba pipẹ, ki wọn o to ṣe igbeyawo.
"Mo ri, o wu mi, a si ṣe igbeyawo laarin ọsẹ mẹta."
- Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tí kìí ṣe ọmọ káàárọ̀ oòjíire
- Omo Ghetto: Funke Akindele ṣàlàyé bí àwọn agbébọn ṣe kọlù wọn làsíkò tí wọ́n ń ya fíìmù
- Àyà mi já nígbà tí Ganduje rọ Sanusi lóyè Emir Kano tó fi Bayero síi, ṣùgbọ́n...- Ooni Ile Ife
- Ìdí tí mi ò fi lè parí ìjà pẹ̀lú Ààrẹ Ọ̀nà kakanfò, Gani Adams - Obasanjo
- Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ kan ṣoṣo ni aṣòfin mẹ́rin ń pín lò! Àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun pariwo sí Gómìnà wọn
"Ilana kan naa ni mo fi fẹ gbogbo àwọn iyawo mi. Mi o gbagbọ ninu ki a ba obinrin rinrinajo ifẹ, ka to o gbe niyawo."
"Ma rinrinajo ifẹ pẹlu ẹni to fẹ ẹ fẹ, ẹ o ma nifẹ ara yin ninu igbeyawo.
Koda ninu àṣà ilu ti mo ti wa, àwọn eeyan kii rinrinajo ifẹ, lasiko ti wọn bi ni.
Ọdun 2019 ni Regina Daniels ati Ned Nwoko segbeyawo, wọn si ti bi ọmọkunrin kan.
Nwoko fikun ọrọ rẹ pe àṣà Igbo faaye gba ki ọkunrin fẹ iyawo pupọ. O ni awọn oyinbo lo mu àṣà iyawo kan, ọkọ kan wa pẹlu ẹṣin Kristẹni.
"Boya mo fẹ iyawo mii tabi mi o fẹ, Regina mọ pe o le ṣẹlẹ. Ile olorogun ni mo ti wa, mo si fẹran ọmọ pupọ.
" Gbogbo nkan yii ni Regina ati awọn iyawo mi yooku mọ. Nitori naa, ka wo nkan ti yoo sẹlẹ lọjọ iwaju. "

















