Ogun Stolen Mace: Bí wọ́n ṣe rí ọ̀pá àṣẹ ìpínlẹ̀ Ogun ní Eko rèé

Maze

Oríṣun àwòrán, Lagos PPRO

Iroyin ayọ lo de ba awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ lọjọ Ẹti pe wọn ti ri ọpa aṣẹ ti wọn jigbe pada.

Ninu ọrọ ti alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Muyiwa Adejobi fi sita, o ni wọn ri ọpa aṣẹ naa ni agbegbe Abule Ado, nipinlẹ Eko.

"Ọlọpaa ti wọn pin si agọ wọn to wa ni agbegbe Trade Fair l'Eko ri ọpa aṣẹ naa gba ni nkan bii ago mẹjọ abọ owurọ ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila ọdun 2020, ni agbegbe Abule Ado".

Iroyin jade nirọlẹ Ọjọbọ ọsẹ kan naa pe awọn janduku yabo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, ti wọn si ji ọpa aṣẹ eyi tii ṣe ami agbara rẹ gbe lọ.

Bakan naa ni wọn tun ba ọpọlọpọ nkan jẹ nile aṣofin ọhun.

Maze

Oríṣun àwòrán, Lagos PPRO

Adejọbi jẹ ko di mimọ pe "awọn ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ ni awọn ara adugbo ta lolobo pe wọn fura pe eeyan kan to n wa ọkọ ayọkẹlẹ Siena Space Wagon ju nkankan danu sinu igbo ti wọn si pada ri nkan naa lo ba di ọpa aṣẹ ile aṣofin ipinlẹ Ogun ti wọn n wa."

Nibayii wọn ti gbe ọpa aṣẹ naa fun kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu to ti paṣẹ fun igbakeji kọmisọna ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ, Yetunde Longe, lati da abo bo ọpa aṣẹ naa ko si kan si awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun lorii didaa pada.

Atẹjade ọhun tun sọ pe Odumosu ṣeleri lati ran ileeṣẹ ọlọpaa Ogun lọwọ ninu ṣiṣewadii iṣẹlẹ to fa sababii riri ọpa aṣẹ ọhun.

Maze

Oríṣun àwòrán, @justeventsonlin

Ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2020 ni iroyin gbode kan pe awọn janduku kan kọlu ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, ti wọn si ji ọpa aṣẹ rẹ gbe lọ.

Lẹyin iroyin naa ni ọpọ eeyan bẹrẹ si n beere pataki ọpa aṣẹ ninu ile igbimọ aṣofin, ati pe ki lo n tumọ si ti ko ba si ọpa aṣẹ ninu ile igbimọ aṣofin.

Idi ree ti BBC Yoruba ṣe kan si ọmọ ile igbimọ aṣofin tẹlẹri ati amofin, Boluwaji Kunlere, to ti figba kan ri ṣoju ẹkun Guusu ipinlẹ Ondo nile igbimọ aṣofin l'Abuja.

Kunlere sọ pe ọpa aṣẹ ni ami aṣẹ ninu ile igbimọ aṣofin.

O ni "Gẹgẹ bi aṣa ati ilana eto iṣofin, o jẹ ohun ti wọn gba gẹgẹ bii ami aṣẹ ninu ile naa, o si ni bi wọn ṣe n lo."

Maze

Oríṣun àwòrán, Unique Foundation Schools

Amofin naa ṣalaye pe ọpa aṣẹ naa ni yoo ṣaaju abẹnugan ile naa to be fẹ wọ inu ile igbimọ aṣofin naa lọ.

Kunlere tun ṣalaye pe ọpa aṣẹ ni ami agbara ninu ile igbimọ aṣọfin.

Àkọlé fídíò, Omolola Arohunmolase Welder: Mo ti fí iṣẹ́ 'Welder' gbayì láwùjọ, tó mo fi tọ́ ọmọ yanjú

Bẹẹ lo tun sọ siwaju si pe ọpa aṣẹ naa ni ami atọna ninu ile aṣofin nitori oun ni abẹnugan maa n tẹle wọ inu ile, ati pe lẹyin ti ọpa aṣẹ naa ba ti joko tan ni awọn aṣofin yoo to gba pe ile naa ti joko.

O ni ti wọn ba ti gbe ọpa aṣẹ naa sọkalẹ kuro lori aga rẹ, o n tumọ si pe igbimọ ti wa ni ijoko lati sọrọ lori abadofin.

Kunlere ni lẹyin ti wọn ba ti da ọpa aṣẹ naa pada si ijoko rẹ ti wọn ṣe fun, o n tumọ si pe abẹnugan ti ṣetan lati jabọ ipade igbimọ naa fun awọn ọmọ ile aṣofin lori abadofin ti wọn n daba le lori.

Àkọlé fídíò, Ojú mi ti rí lọ́pọ̀ lọpọ̀, àmọ́ mo dúpẹ́ pé mo ti pé ọdún márùn ún lórí oyé- Ooni

Nigba to n sọrọ lori ọpa aṣẹ ti wọn ji gbe ni ipinlẹ Ogun, Kunlere ni ọpa aṣẹ ti wọn ji gbe ko sọ pe iṣẹ ijọba yoo duro.

O ni "ihalẹmọ lasan ni ero pe ijọba yoo doju bolẹ ti wọn ba ti ji ọpa aṣẹ gbe lọ."

"Ko si ohun ti yoo ṣẹlẹ ti wọn ba gbe ọpa aṣẹ ile igbimọ aṣofin lọ nitori ko si ibi to wa ninu ofin pe ti wọn ko ba ti ri ọpa aṣẹ, pe ijoko ko ni wa ninu ile aṣofin."

O ni aṣa lasan ni ọpa aṣẹ naa, ko si da iṣẹ ijọba duro nitori ile igbimọ naa le lọ wa ọpa aṣẹ miran.

Amofin pari ọrọ rẹ pe, gẹgẹ bi aṣa adayeba, ile igbimọ ko pe lai si ọpa aṣẹ, ṣugbọn niwọn igba ti ile naa ba le wa pese ọpa aṣẹ miran, ko ṣe nnkan.

Àwọn jàndùkú ṣọṣẹ́ nílé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun, ọ̀pá aṣẹ dàwátì!

ogun

Oríṣun àwòrán, @Thegistday

Eemọ ti ṣẹlẹ ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun gẹgẹ bi awọn afurasi janduku ṣe ya bo ibẹ l'Ọjọbọ ọsẹ.

A gbọ pe awọn janduku naa ja wọ ọfiisi adari ile, Olakunle Oluomo ti wọn si ji ọpa aṣẹ gbe lọ.

Nigba ti awọn akọroyin de ibẹ lati ṣewadii ohun to ṣẹlẹ, awọn oṣiṣẹ alaabo ko jẹ ki wọn wọle, wọn ni latoke wa ni aṣẹ ọhun ti wa.

Ẹwẹ, gẹgẹ bi agbẹnusọ ile aṣofin naa ṣe sọ fun awọn oniroyin, wọn ti ri ami idanimọ Coat of Arm to wa lori ọpa aṣẹ naa, ṣugbọn ọpa aṣẹ gangan, wọn o tii ri i.

ogun

Oríṣun àwòrán, Channels Television

Alukoro Ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori bi awọn janduku yii ṣe ri ọna wọle ji ọpa aṣẹ naa gbe.

Oyeyemi ni awọn yoo fi ọrọ sita lẹkunrẹrẹ nigba ti wọn ba t ri ọpa aṣẹ naa pada lodindi.

Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ kan ṣoṣo ni aṣòfin mẹ́rin ń pín lò!

Iwaju ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun

Oríṣun àwòrán, Ogun State House of Assembly

Adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin ipinlẹ Ogun, Olakunle Oluomo ti sọ l'Ọjọbọ wipe aṣofin mẹrin lo wọdi mọ ile igbọnsẹ kan ṣoṣo nile igbimọ aṣofin.

Oluomo sọ eyi ni igba diẹ ṣaaju ki gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun to gbe aba eto isuna ọdun 2021 siwaju ile ni ile igbimọ aṣofin wọn to wa ni Oke-Mosan, Abeokuta.

Iroyin sọ pe Oluomo ti sọ ọ̀rọ̀ yii lati ọdun to kọja lasiko ti gomina n gbe aba eto isuna ti ọdun yii siwaju ile ẹjọ.

Àkọlé fídíò, 'Ọkọ mi wa ọkọ̀ tẹ "Poly Bag" lásán, àfi gbùùàà! Àdó okoró búrẹ́kẹ'

Iroyin tun sọ pe nigba to ka a lara wipe gomina o naani ọrọ ohun amayerọrun yii lẹyin ọdun kan, ṣe lo tun yi ohun rẹ soke to tẹnu mọ ọ pe bi nkan amayerọrun nile aṣofin ṣe n di akurẹtẹ nilo amojuto gidi.

Bakan naa ni adari ile tun safihan aworan iru ile igbimọ aṣofin tuntun ti awọn aṣofin ṣe fun gomina.

O ni "ẹ jẹ ki n fi ye bayii pe yatọ fun adari ati igbakeji adari, ko tun si ọmọ ile kankan to ni ibi igbalejo tiwọn ka ma wa sọ ọfiisi".

"O buru jai lati maa sọ pe ile igbọnsẹ kan ṣoṣo lawọn họnọrebu mẹrin n pin lo ninu ile igbimọ aṣofin wa".

Ile aṣofin Ogun

Oríṣun àwòrán, Ogun State House of Assembly

O fi kun un pe koda wọn koi tii san awọn owo ajẹmọnu kọọkan to yẹ ki wọn san fun awọn aṣofin.

Adari ile tun ṣalaye wipe awọn aṣofin o ribi dawọle awọn iṣẹ akanṣe to ṣe gboogi pẹlu bi ọdun yii ṣe n lọ sopin tori owo ti ko jade.

O sọ fun gomina Abiodun pe ko "fọwọ si pipese oriṣiriṣi owo ajẹmọnu ti wọn n jẹ awọn aṣofin ati awọn oṣiṣẹ wọn to fi mọ owo fun aga, owo asiko isinmi lẹnu iṣẹ ati owo aṣọ".

Nigba ti o fesi, Abiodun gba wipe lootọ ni adari ile sọ ọrọ yii lọdun to kọja o si ṣeleri pe ijọba oun yoo moju to ọrọ yii lọdun to m bọ.