Yahoo Yahoo: Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọn ọdún kan àbọ̀ he lẹ́yìn tó lu obìrin ní jìbìtì ìfẹ́ lórí ayélujára

Law

Oríṣun àwòrán, Succo

Ile ẹjọ kan nipinlẹ Eko ti ran ọkunrin kan lẹwọn oṣu mejidinlogun lẹyin to jẹbi ẹsun lilu obinrin ni jibiti ifẹ lori ayelujara.

Ọkunrin naa, Chimah Daniel Iweregbu, wa lara awọn afurasi onijibi ori ayelujara ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI, n wa lati oṣu diẹ sẹyin.

Iweregbu di ẹni to n kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ lẹyin to ko sọwọ ajọ EFCC ni ipinlẹ Eko.

EFCC gbe afurasi naa lọ ile ẹjọ lọjọ kẹrin, oṣu kejila, ọdun 2020 lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ lọjọ kejila, oṣu Kẹjọ ọdun 2020 yii kan naa.

Lẹyin to bẹbẹ pe oun gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ni olupẹjọ, Franklyn Ofoma, rọ ile ẹjọ naa lati ṣe idajọ bo ṣe tọ labẹ ofin.

EFCC

Oríṣun àwòrán, Channels Television

Nigba to n ṣiṣọ loju awọn ẹri lati fidi ẹjọ naa mulẹ, Ofoma sọ pe ẹri to tẹ EFCC lọwọ lati ọdọ ajọ FBI fi han pe lootọ ni olujẹjọ naa lu jibiti ifẹ lori ayelujara.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "ọdaran naa maa n dibọn pe oun ni ọgagun Larry Pham, lati lu awọn ololufẹ rẹ ni jibiti lori ayelujara, paapaa awọn obinrin."

"Lẹyin to ko sọwọ ajọ EFCC, o jẹwọ pe lootọ ni oun lu awọn obinrin ni jibiti gẹgẹ bi ẹsun ti wọn fi ka oun."

Ofoma tẹsiwaju pe "iwadii ti a ṣe lori ẹrọ ibanisọrọ ati kọmputa rẹ fi han pe o lu awọn eeyan ni jibiti iye owo to to $15,000."

Lẹyin o rẹyin, adajọ Oluwatoyin Taiwo sọ pe ki ọdaran naa lọ fi ẹwọn jura fun oṣu mejidilogun lori ẹsun mẹta ti wọn fi kan an, yoo si maa ṣe ẹwọn naa papọ, tabi ko san owo itanran 100,000 naira fun ẹsun kọkan.

Bakan na ni adajọ ọhun tun ni ki ijọba gbẹsẹle ẹrọ ibanisọrọ iPhone rẹ pẹlu ẹrọ kọmputa alagbeka to fi n ṣiṣẹ ibi ọhun.

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn