EndSars in Portharcourt: Ọjọ́ méjì sẹ́yìn ni aya awakọ̀ Márúwá tí ọlọ́pàá pa bímọ tuntun

Iwọde n waye nilu Portharcourt

Oríṣun àwòrán, Allwell Ene

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi ijọba se n sanna bi a se jẹ ekuru ọran ko tan nidi ifẹhonuhan tawọn araalu n se tako awọn ọlọpaa, se ni awọn eeyan kan tun n gbọn ọwọ rẹ sinu awo.

Idi ni pe rogbodiyan nla miran tun ti bẹ silẹ nilu Portharcourt lowurọ ọjọbọ nitori bawọn araalu, paapaa awọn onikẹkẹ Maruwa se n sewọde.

Awọn eeyan naa ni wọn sọ pe, lai naani bawọn se n kigbe tako iwa ika latọdọ awọn ọlọpaa, se ni ọlọpa kan tun yinbọn mọ onikẹkẹ Maruwa kan, to si gbẹmi lẹnu rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin naa ni onikẹkẹ Maruwa naa lo fi aake kọri lati fun ọlọpa kan to wa loju popo ni ọgọrun naira, eyi to bi ọlọpaa naa ninu, to si da ibọn bo o.

Iwọde n waye nilu Portharcourt

Oríṣun àwòrán, Allwell Ene

Onikẹkẹ Maruwa naa ni wọn sọ pe iyawo rẹ bimọ ni ọjọ meji sẹyin, ti wọn si ti gbe oku ọkunrin naa lọ sagọ ọlọpaa to wa ni Rumuokoro.

Nigba to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers, Nnamdi Omoni salaye pe wọn ti mu osisẹ ọlọpaa ti aje iwa ika ọhun si mọ lori, ti iwadii si ti bẹrẹ nipa isẹlẹ naa.

O fikun pe wọn yoo gbe osisẹ ọlọpaa naa lọ sile ẹjọ laarin ọjọ meji si asiko yii.

Àkọlé fídíò, Omolola Arohunmolase Welder: Mo ti fí iṣẹ́ 'Welder' gbayì láwùjọ, tó mo fi tọ́ ọmọ yanjú

Wayi o, ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ni oun ti n sanna bi alaafia yoo se jọba pada ladugbo ti isẹlẹ naa ti waye, ti iwọde to n lọ lọwọ yoo si dawọ duro.

Ko tan sibẹ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers tun fikun pe, awọn yoo se abẹwo ibanikẹdun sile mọlẹbi oloogbe onikẹkẹ Maruwa naa.

Ọlọ́pàá, sójà yabo Lekki Toll Plaza láti dènà ìfẹ̀hónúhàn míràn

Ọlọ́pàá, sójà yabo Lekki Toll Plaza láti dènà ìfẹ̀hónúhàn míràn

Oríṣun àwòrán, Johnpaul/twitter

Ní ǹkan tó jọ́ bi ẹni pé ìjọba ń gbìyànjú láti dènà ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn #Endsars àwọn ọlọ́pàá àti sójà lọ sí Toll Gate Lekki nílùú Eko.

Ìròyìn sọ pé wọ́n ran awọn elétò ààbò lọ si ibẹ̀ ni ààrín òrú láti ma sọ ibẹ̀

Ọlọ́pàá, sójà yabo Lekki Toll Plaza láti dènà ìfẹ̀hónúhàn míràn

Sáájú àsìkò yìí ni àwọn tó n ṣe agbátẹrù ètò ìfẹ̀hónúhàn #Endsars ti kéde pé ìwọ́de míràn yóò bẹ̀rẹ̀ ni Eko Abuja àti Port Harcourt àti àwọn ìpińlẹ̀ míràn yóò wáyé.

Èyí sì ló mú kí àwọn ọlọ́pàá máa kìlọ̀ fún ará ilú láti ma gbìyànjú rẹ̀.

Sùgbọ́n ni ǹka tó fàrahàn pé ń ṣẹlẹ̀ ni ìgboro báyìí, àwọn ọdọ́ kan ti ń kéde lójú òpó twitter pé ìw'ọ́de míràn ti bẹ̀rl ní ìpínlẹ̀ Eko

Kílò ń ṣẹlẹ̀ lójú òpó twitter

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ọ̀kan nínú àwọn gbajúgbajà lójú òpó twitter #OurFavonlineDoc sọ pé, ìwọ́de ti bẹ̀rl ni ìlú Eko àti Ibadan, àti pé ọ̀pọ̀ àwọn ojú pópó ni wọ́n tipa

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Àkọlé fídíò, Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ
Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Lásìkò ti àwọn alákoso ìfẹ̀hónùhàn Endsars ṣe ìpolongo òmíràn tí yóò wáyé lónìí ni wọ́n ti kéde àwọn ǹkan tí wọ́n ń fẹ́ lọ́dọ̀ ìjọba.

Àwọn tó ń ṣagbátẹrù ọ̀rọ̀ náà sàlàyé pé, kí ìjọba dá àwọn tí wọ́n mú si àhámọ́ ọlọ́pàá nítori ipa ti wọ́n kó lásìkò ìwọ́de àkọ́kọ́

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Wọ́n fẹ́ kí bánkì apapọ̀ Nàìjíríà tú àkántì àwọn ti wọ́n tì pa nítori ìwọ́de àkọ́kọ́.