Maryam Sanda: Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fòntẹ̀ lu ìdájọ́ ikú fún Sanda tó gún ọkọ rẹ̀ pa

Sanda

Oríṣun àwòrán, @thecableng

Ko si ṣiṣe, ko sí aiṣe, wọn gbọdọ yẹgi fún Maryam Sanda ni.

Eyi ni idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja lori ẹjọ ti Maryam Sanda ti ileẹjọ gíga ti dajọ iku fun tẹlẹ lori ẹsun pe o gun ọkọ rẹ pa.

Ileẹjọ naa sọ pe ko si ohun kan to f'ẹsẹ mulẹ ninu ẹjọ ti Maryam pe.

Nitori naa, oun naa gbọdọ ku nipa sisọ okun sí lọrun lẹyin to jẹbi ẹsun pe o gun ọkọ rẹ, Bilyamimu Bello ti ṣe ọmọ alaga gbogbo ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Haliru Bello pa.

Sanda

Oríṣun àwòrán, @SHOPEN_ONLINE

Amọ, agbajẹro Maryam, Joe Gadzama (SAN), tí ṣọ pe awọn yoo gbe ẹjọ naa lọ si ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria.

Bakan naa, agbẹjọro ileeṣẹ ọlọ́pàá, James Idachaba gboṣuba fún ileẹjọ lori idajo rẹ.

Àkọlé fídíò, Kayeefi: 'Ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ní kí n lọ se mọ́í-mọ́í, tó ṣẹ̀ bá mi ṣeré tán ni mo gbọ́ pé "Mopol" yìnbọn pa á'

Ọgbẹni Idachaba ni awọn naa ṣetan lati pade Maryam ati agbẹjọro rẹ nile ẹjọ to ga julọ.

Niiṣe ni Sanda bu s'ẹkun gbagada lẹyin ti adajọ ka idajọ rẹ tan.

Amọ, Sanda ni adajọ Yusuf Halilu ṣegbe lẹyin ẹnikan ninu idajọ rẹ, nitori naa oun ṣetan lati gbẹjọ oun lọ si ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria.