Seyi Makinde: Gbogbo ìgbà ni ìyá mi máa ń sọ fún mi pé díẹ̀ ló kù kí àwa méjèjì kú lọ́jọ́ tó bí mi

Aworan iya Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, amujuẹrọ Seyi Makinde ti sọrọ lori awọn ohun ti yoo saaro nipa iya rẹ lẹyin to jade laye tan.

Makinde sọ pe gbogbo igba ti iya oun ba fẹ gba ohun kohun lọwọ oun ni iya naa maa n ran oun leti pe diẹ lo ku ki awọn mejeji ku lọjọ to n rọbi.

Gomina ọhun lo fi ọrọ naa lede nibi ayẹyẹ ikẹyin to ṣe fun iya rẹ.

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn

Makinde sọ pe, bo tilẹ jẹ oun kii ṣe akọbi iya naa, awọn eeyan maa n pe ni mama Ṣeyi.

O ni nigba ti oun bere lọwọ iya naa idi ti wọn fi n pe ni mama Seyi ti oun si kii ṣe akọbi ni iya naa lọ ṣalaye fun oun pe, diẹ lo ku ki ọjọ ikunlẹ di ọjọ iku fun iya oun.

Nitori naa, o ni gbogbo igba ti iya naa ba bere ohukohunn lọwọ ohun ni oun maa fi fun.

Àkọlé fídíò, Kayeefi: 'Ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ní kí n lọ se mọ́í-mọ́í, tó ṣẹ̀ bá mi ṣeré tán ni mo gbọ́ pé "Mopol" yìnbọn pa á'

Makinde sọ pe igbeaye ti iya oun gbe kii ṣe fun ara rẹ nikan, ṣugbọn o gbe igbe aye rẹ fun oun to jẹ ọmọ rẹ atawọn eeyan miran pẹlu.

O wa sọ pe oun ko le gbagbe ipa ribiribi ti iya naa ko ninu aye oun atawọn ẹko ti oun kọ lara rẹ ko to fi aye silẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Seyi Makinde ṣe ètò ìdágbére ìkẹyìn fún ìyá rẹ̀, àwọn èèkàn sọ nípa ìyá náà

Gomina Seyi makinde n dagbere fun iya rẹ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti ṣe alaye ọrọ lorii bi o ṣe padanu anfani to yẹ ki o fi ba iya rẹ sọ ọrọ ikẹyin ki ọlọjọ to de.

Makinde fi ọrọ naa lede l'Ọjọbọ nibi isin idagbere to waye fun iya rẹ ni gbagede "Arcade" ile ijọba ipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bi o ṣe n fi kun ọrọ rẹ wi pe iku iya oun ṣi jẹ ọgbẹ ọkan nla.

Ọpọlọpọ awọn eeyan to sọrọ nibi isin naa lo mu igbesi aye oloogbe wa si iranti nibi akanṣe eto naa.

Lara wọn ni gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Oloye Rasheed Ladoja, Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo, aṣoju orilẹede yii tẹlẹri, Taofeek Arapaja, aarẹ ẹgbẹ awọn ọmọ lẹyin Kristi, Dr Olasupo Ayokunle, Alufa Femi Emmanuel, Biṣọọbu agba Segun Okubadejo ati awọn ẹẹkan mii.

Gomina Seyi Makinde ati Akeredolu ti Ondo

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Gomina Seyi Makinde atawọn Gomina ẹgbẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ninu ọrọ ti o sọ nibi ipejọpọ naa, Makinde ṣe alaye wipe oun ti ṣe ileri lati ri iya oun ni opin ọsẹ ti o tẹle eto idibo si ipo gomina ti o waye nipinlẹ Ondo, ṣugbọn oun ko ri aye lati gbe awọn ipe iya oun nitori ibẹru wi pe oun ko ni le ri iya oun saaju asiko ti wọn jọ da fun ara wọn.

O fi kun ọrọ rẹ pe ohun ijaya lo jẹ nigbati ipe pajiwiri kan dede wọle laarọ ọjọ keji wi pe iya oun ti re ibi agba n re, pẹlu afikun wi pe iya oun ki i fẹ ki ọmọ fi eto ẹkọ ṣere rara nigba aye rẹ.

Makinde ni, "O ṣi jẹ ohun ti o nira fun mi. Ibaṣepọ ti mo ni pẹlu iya mi ko lẹgbẹ. Mo baa sọrọ l'ọjọ Aje lọgan ti a pari eto idibo nipinlẹ Ondo, mo si sọ fun iya mi wi pe a o rira ni opin ọsẹ. Lẹyin eyii ni mo tun rin irinajo lọ si ilu Port Harcourt on lowurọ Ọjọru.

Aworan iya Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Gomina Seyi makinde n dagbere fun iya rẹ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

"Ni gbogbo Ọjọru ni iya mi fi pe aago mi, ṣugbọn mo ro pe ko ni itumọ ki n gbe ipe naa nitori mo wa ni irinajo ati wi pe l'opin ọsẹ ni ajọ ṣe ileri wi pe a o rira, ṣugbọn l'ọjọbọ ni iya mi jade laye".

Makinde fi kun ọrọ rẹ wi pe iya oun fi ọwọ rọri ku ni.

O ṣe apejuwe iya gẹgẹ bi akikanju obinrin ti ki i fi iṣẹ ṣere.

Gomina Seyi Makinde ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Gomina Seyi makinde n dagbere fun iya rẹ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde