Awolowo: Àwọn èèkàn ìlú péjú s'Ibadan níbi ìsìnkú màmá Omotola àkọ́bí obìnrin Awolowo tó wọ káà ilẹ̀ lọ

Tola Oyediran

Oríṣun àwòrán, Tribuneonline

Iku pa abiri, abiri lọ, iku pa abiri, abiri rọrun. Mama Omotola Oyediran tii ṣe akọbi lobinrin Oloye Obafemi Awolowo ti wọ kaa ilẹ lọ.

Awọn eekan lagbo oṣelu bii igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo, Asiwaju Bola Tinubu, Gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ ri, Bisi Akande lo peju pesẹ si ilu Ibadan lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun mama.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, Kayode Fayemi ti ipinlẹ Ekiti, Gomina Rotimi Akeredolu ipinlẹ Ondo, Aminu Tanbuwal atawọn ọtọkulu miiran lo wa nibi eto isinku ọhun ni Ibadan.

Ninu iwaasu rẹ, Alufaa Archbishop ijọ Methodist to ti fẹyin bayii, the Most Reverend Ayo Ladigbolu sọ pe mama Omotola fiwa jọ Oloye ati mama H.I.D. Awolowo nipa ṣiṣe aanu fawọn eeyan.

Alufaa Ladigbolu sọ pe Mama Omotola gbe igbe aye rẹ ni ibamu pẹlu ilana ti Oloye Awolowo la kalẹ ki o to papoda.

O fikun ọrọ rẹ pe olotitọ ati olododo eeyan to ṣe fi ọkan tan ni mama Omotola.

''Iwa to dara ti mama hu titi ti o fi jẹ Ọlọrun nipe, lọwọ awọn obi rẹ lo ti kọ gbogbo rẹ,'' alufaa Ladigbolu lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn

Alufaa naa ko ṣai sọ iṣepataki awọn obinrin lawujọ, o ni iru awọn obinrin bii mama Omotola lo le mu idagbasoke ba Naijiria.

O rọ awọn alaṣẹ ni Naijiria lati fun awọn obinrin lanfani lati di ipo olori mu ki wọn le lo ẹbun ti Eleduwa fun wọn fun anfaani gbogbo araalu.

''Ajijagbara ati ajafẹtọ ọmọniyan ni mama Omotola titi ọjọ aye rẹ ti o fi jade laye,'' alufaa Ladigbolu lo sọ bẹẹ.

Mama Omotola ṣe igbeyawo pẹlu ọjọgbọn A.B.O.O. Oyediran to jẹ ọga agba ile ẹkọ fasiti ilu Ibadan, U.I. nigba kan ri.

Àkọlé fídíò, Kayeefi: 'Ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ní kí n lọ se mọ́í-mọ́í, tó ṣẹ̀ bá mi ṣeré tán ni mo gbọ́ pé "Mopol" yìnbọn pa á'

Tola Oyediran ọmọ Obafemi Awolowo ti jáde láyé

Ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹwaa ọdun 2020 yii ni mama Oyediran fi aye silẹ.

Mama Omotola to jẹ ọkan ninu awọn ọmọ olootu ijọ iwọ oorun guusu Naijiria nigba kan ri, Oloye Obafemi Awolowo ko ba ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrin ọdun laye.

Oun ni omọ Awowlọwọ to dagba ju ki iku to mu un lọ.

Tola si ni alaga igbimọ alaṣẹ iwe iroyin Tribune titi ti o fi faye silẹ.