EndSARS: Olatunde Abolarinwa London Tailor ní òun á ṣe baba fún mi, kò tilẹ̀ dúró ṣe bàbá àwọn ọmọ tirẹ̀ tóríi ìwà Ọlọ́pàá Mopol

Àkọlé fídíò, Kayeefi: 'Ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ní kí n lọ se mọ́í-mọ́í, tó ṣẹ̀ bá mi ṣeré tán ni mo gbọ́ pé "Mopol" yìnbọn pa á'

Iṣẹlẹ Kayeefi wa ti oṣu yii jẹ kayeefi ṣugbọn ko si irọ kankan nibẹ. Ti ọtẹ yii si nii ṣe pẹlu ọrọ wahala iwọde EndSARS bo tilẹ jẹ pe o le ti maa sinmi bayii.

Amọ apa rẹ ati ọgbẹ rẹ ko lee laye laye kuro lọkan awọn eeyan kọọkan. Iwa aburu ti awọn ọlọpaa n hu si awọn ara ilu kan.

"London Tailor" ni orukọ inagijẹ ti wọn fun arakunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, Olatunde Abolarinwa ti ifẹ oun ati iyawo rẹ dabii ti ẹlẹyẹle ni ti iyawo ko si mọ wipe ọkọ rẹ ko ni dagba, di ogbo, ferigi pau jẹ obi gẹgẹ bi wọn ṣe lero sira wọn.

Gẹgẹ bi aya oloogbe, Odunayo Abolarinwa ṣe ṣalaye fun ikọ iroyin Kayeefi tio BBC Yoruba, odidi ọlọpaa Mopol meji lo yinbọn ba a ni ilu Oye Ekiti nigba to n lọ sile lati ṣọọbu rẹ to ti n ṣiṣẹ "Tailor".

"Haa, leeyan temi atirẹ ṣẹṣẹ jọ jẹun tan ni ṣọọbu to ni ki n lọ se mọi-mọi wa ni wọn waa n ṣalaye fun mi bi awọn lọpaa meji ṣe yin in nibọn".

Odunayo ni oun ko mọ pe arimọ awọn ni ere ranpẹ tawọn jọ ṣe ninu ṣọọbu lọ.

Odunayo kan sẹkun niwaju Kamẹra BBC, "mo fẹ ẹsan lorii iku London Tailor tori ọmọ mẹta to fi silẹ fun emi nikan".