Yellow Fever in Nigeria: Àrún ibà pónjú ti pa ènìyàn 172 ni Nàìjíríà - WHO

Kí oṣù kọkànlá ọdún tó parí ààrun náà ti tan ka ìpínlẹ̀ márún ni Nàìjíríà, Delta, Enugu, Benue, àti Ebonyi.

Oríṣun àwòrán, WHO

Ààrùn ibà pónjú tó bẹ́ sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà láìpẹ́ yìí tí mú ẹ̀mí ènìyàn méjìléláàdọ́jọ lọ báyìí.

Ààrùn yiì tún ti mú ìpèníjà míràn bá ètò ìlera orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó sì ń tiraka láti bọ́ lọ́wọ́ ààrùn Covid-19 to ti n da gbogbo àgbáyé láàmú láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2020.

Àjọ ìsọ̀kan àgbáyé fún ètò ìlera (WHO) sọ pé oníruurú ààrùn ló tí n yọjú láti ìbẹ̀rẹ̀ ajákàll ààrùn Covid-19 ni ìhà àríwá-ìlààoòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn

Agbẹnusọ àjọ ìsọkan agbáyé fún ètò ìlera (WHO) Tarik Jasarevic sọ pé láti ọdún 2017, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò tí jàjàbọ́ lọ́wọ́ ààrùn iba pójú (Yellow Fever). Èyí tó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ yìí fojú hàn nínú oṣù kọkanla ọdún yìí.

Kí oṣù kọkànlá ọdún tó parí, ààrun náà ti tan ka ìpínlẹ̀ márún ni Nàìjíríà, Delta, Enugu, Benue, àti Ebonyi.

Ènìyàn ọgbọ̀n lé ẹ̀ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta ló ti fojú hàn, tí àyẹ̀wò sì ti fìdí méjìdíláàdọ́ta múlẹ pé wọn ni ààrùn náà.

Àkọlé fídíò, Kayeefi: 'Ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ní kí n lọ se mọ́í-mọ́í, tó ṣẹ̀ bá mi ṣeré tán ni mo gbọ́ pé "Mopol" yìnbọn pa á'

Agbẹnusọ náà sàlàyé pé, ọ̀rọ̀ Covid-19 ni ìjọba Nàìjíríà gbájú mọ́, tí wọ́n ko si ṣe àyẹwò fún àwọn ènìyàn lórí ààrùn ibàpójú.

Ó fi kún pé ní báyìí ìpińlẹ̀ mẹ́rìndílógún nínú mẹ́rìndínlógójì ló ti pari ìpolongo abẹ́rẹ́ àjẹsára ààrún ibà pọ́jú.

Àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́fà míran yóò bẹ̀rl tiwọn ní sáà akọ́kọ́ nínú ọdún 2021.

Kó sí ìtọ́jú kan pàtó fún ààrún ibà pójú, ẹfọn sì ló máa n gbée láti ara ẹnikan si ara ẹlòmíràn.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Báwo ní gbogbo àgbáyé ṣe lè gba abẹ́rẹ́ ajẹ́sara àrún Coronavirus?