Adolf Hitler: Kíni ẹ̀yin rántí tàbí mọ̀ nípa Adolf Hitler yìí?

Oríṣun àwòrán, @EagleFMNam
Bi ẹ ba gbọ orukọ yi kini iru ero to maa n wa si ọkan yin?
Bi oloselu kan ba wa dije sipo torukọ rẹ si n jẹ Adolf Hitler njẹ ẹyin yoo dibo fún ùn?
Awọn ibeere yi lo ṣuyọ lori iroyin kan ti iwe iroyin orileede Germany kan torukọ rẹ n jẹ Bild gbe jade pe arakunrin kan torukọ rẹ n jẹ Adolf Hitler wọle sipo kánsílọ̀ ninu idibo to waye ni Namibia.
- Ṣé Amotekun ti di "HisbahTekun" ní ìpínlẹ̀ Osun ní?
- Irọ́ ni, abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 kò lè ṣàyípadà DNA rẹ
- Àwọn agbègbè tí àtùndi ìbò yóò kàn lọ́jọ́ Àbámẹ́ta nípìnlẹ̀ Eko rèé
- Wo ọ̀nà tóo lé tọ̀ láti gba físà tóo bá fẹ́ ṣiṣẹ́ ní UK lábẹ́ ìlànà tuntun
- Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fòntẹ̀ lu ìdájọ́ ikú fún Maryam Sanda tó gún ọkọ rẹ̀ pa
Adolf Hitler Uunona jawe olubori labẹ asia ẹgbẹ Swapo to jẹ ẹgbẹ to wa lori oye níbẹ.
Oloselu naa to fi orukọ Adolf Uunona dije ko ida marundinlaadorin ninu ida ọgọrun ibo to waye loṣu to kọja ni Ompundja ilu kekere kan to wa ni Ariwa orileede naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ninu iwe orukọ oludije lẹta 'H' ni wọn fi kọ Hitler to wa ninu orukọ rẹ ṣugbọn ninu iwe ẹri abajade ibo,wọn kọ ẹkunrẹrẹ orukọ rẹ sibẹ gbagada ni.

Oríṣun àwòrán, ECN
Lọwọ orileede Germany ni Namibia ti gba ominira.
Iru awọn orukọ bayi si jẹ iranti fawọn eeyan pe wọn ni nkan ṣe pẹlu Germany.
Ati pe awọn eeyan ile naa kan wa ti wọn n sọ ede Germany.
Arakunrin Uunona so fun ileesẹ iroyin Bild pe
"Baba mi kan sọ mi lorukọ Hitler ni.Mi o ro pe o mọ itumọ rẹ."
- Díẹ̀ ló kù kí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ di ọjọ́ ikú fún ìyá mi lọ́jọ́ tó bí mi - Seyi Makinde
- Àwọn àgbàgbà òkè ọya ń fẹ́ kí Ààrẹ Buhari kọ̀wé fipò sílẹ̀
- Àwọn afurasí ṣá ìgbákejì kọmísọ́nà ọ̀gá ọlọ́pàá láàké dójú ikú
- Wo ọ̀rọ̀ tí Asiwaju Bola Tinubu fi síta lórí ìṣòro ètò àbò Nàìjíríà
- Sójà obìnrin lù mí lálù bami nílùú Ibadan
- Nkechi Blessing vs Toyin Abraham: Nkechi tí tọrọ ìdáríjí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ akẹgbẹ́ rẹ̀, Toyin Abraham
"Nigba ti mo wa ni kekere orukọ naa ko jẹ ajoji si mi.Bi mo se n dagba ni mo bẹrẹ si ni mọ pe amunisin ni ẹni to n jẹ orukọ yi nigba aye rẹ"
Germany ko Namibia l'ẹru lẹyin ti ogun agbaye kini pari ṣaaju igba ti Hitler bọ sori aleefa.
N'ise ninu awọn eeyan maa n bajẹ ni Namibia bi wọn ba ṣe iranti igba amunisin yi
Laarin ọdun 1904 si 1908 awọn ọmọ-ogun Germany pa to ọpọ eeyan ẹya Nama ati Herero bi ẹni pa ẹran ninu iṣẹlẹ t'awọn onkọtan a máa pe ni "Forgotten Genocide"















